Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi ló tú àṣírí agbára tí mo fi ológbò ṣe fáwọn DSS -Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyemo (Igboho), ṣe n tẹsiwaju ninu abẹwo rẹ si ọdọ awọn ọba ilẹ Yoruba, ọkunrin to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba yii ti tu aṣiri miran.
Nigba to ṣabẹwo si Aafin Olowo ti ilu Owo, Oba Ajibade Gbadegesin (Ogunoye Kẹta), Igboho sọrọ nipa agbara rẹ tó fi ológbò ṣe, ti awọn ẹṣọ DSS pa loru ọjọ ti wọn ya bo ile rẹ niluu Ibadan loṣu Keje ọdun 2021.
Aafin Olowo ni Igboho ti sọ pe oun ni ologbo kan lootọ, eyi ti oun sọ aṣiri nipa rẹ fun ọrẹ oun kan to sunmọ oun pẹkipẹki.
Aṣiri naa lo ni ọrẹ òun náà tu fun awọn agbofinro DSS, ti wọn si ṣe bẹẹ pa ologbo naa nigba ti wọn fi ipa wọle, ti wọn wa we e laṣọ bi oku eeyan lẹyin ti wọn pa a tan.
"Awọn kan n sọ kiri pe ifun mi ti jade sita, ẹsẹ mi ti kan, lóòótọ́ wọn yinbọn si mi pupọ, ṣugbọn adua ẹyin baba mi gba lori mi"
Gẹgẹ bi Sunday Igboho ṣe wi:
"Nigba ti wọn fipa wọ ile mi, wọn fẹ pa mi ni, ṣugbọn wọn ko ri mi pa.
"Nigba ti mo ṣilẹkun yara mi fun wọn, wọn ri oloogbo mi lori ibusun.
"Ọkan lara awọn ọrẹ mi ti mo sọ aṣiri fun nipa ologbo náà, lo ti sọ fun wọn tẹlẹ pe wọn ko gbọdọ jẹ ki ologbo yẹn lọ."
"Nitori ẹ, ni wọn ṣe pa ologbo naa ti wọn si we e laṣọ bi oku.
Wọn ba gbogbo ile jẹ, wọn pa ọkan lara awọn aburo mi ati ẹnikan, wọn si ba ti wọn lọ."
"Awọn kan ti n gbe e kiri pe ifun mi ti jade sita, awọn kan ni ẹsẹ mi ni wọn kan, ṣugbọn ko sohun to jọ bẹẹ.
"Loootọ, wọn yinbọn si mi pupọ, ṣugbọn adua ẹyin baba mi gba lori mi."
Bẹẹ ni Sunday Igboho ṣalaye nipa ikọlu ọdun kẹrin sẹyin naa.
O fi kun un pe atimọle loun wa lorilẹede Benin, ti mama oun fi ku nile.
Igboho sọ pe mama naa ro pe ijọba Tinubu yoo lo agbara lati tu oun silẹ kia ni, ṣugbọn nigba ti aarẹ gba jọba, toun ko si ri itusilẹ, mama oun dagbere faye.
Ọjọ keji lẹyin iku iya naa lo ni oun gba ominira.
"Ọkan lara awọn minisita ilẹ Germany, lo fun mi ni iwe irinna idaabobo, eyi to jẹ ki n le rin irinajo wale"
Igboho ṣalaye nipa iṣoro to n koju lati rin irinajo, pẹlu bi ijọba Naijiria ṣe kọ lati fun un ni iwe irinna rẹ, ti ko si jẹ ko le wale taara lati orilẹede Germany.
O ni ọkan lara awọn minisita ilẹ Germany, lo pada fun oun iwe irinna idaabobo, eyi to fun oun ni anfaani lati rin irinajo.
Igboho sọ pe ṣugbọn ki i ṣe iwe irinna kikun ti eeyan le fi ọwọ sọya le lori.
"O ni oun yoo fun mi ni iwe irinna to jẹ ti Germany, pe ibikibi ti mo ba lọ, bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, wọn o ni i ṣe nnkan kan fun mi, kaka bẹẹ, wọn a mu mi pada.
"O si fọwọ sọya fun mi pe oun yoo maa ran mi lọwọ lọ.
Iwe irinna naa ni mo n lo lati rin irinajo bayii"
Bẹẹ ni Igboho ṣàlàyé.
"Bi ko ba jẹ aini ominira mi ni, gbogbo idojukọ ipaniyan to n ti inu igbẹ wa nilẹ Yoruba yii, maa ti wọgbo lọ koju wọn"
Ajijagbara naa ni eto naa ko ṣe e fi gbogbo ara gbọkan lè torí ifẹ inu oun ni lati pada si Naijiria bii ọmọ oniluu tootọ.
Igboho wa rọ Olowo, Oba Ajibade Gbadegesin, lati lo ipo rẹ fi ba Aarẹ Tinubu sọrọ, ko yọnda oun ni kikun, koun le ni ominira gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere.
O ni o ti n pe ọdun marun-un lọ bayii ti wọn ti le oun nilẹ yii, o si to ki ọba alaye naa dide iranlọwọ, boun ṣe n tọ wọn lọ nikọọkan.
Igboho ni bi ko ba jẹ aini ominira oun ni, gbogbo idojukọ ipaniyan to n ti inu igbẹ wa nilẹ Yoruba yii, oun yoo ti wọgbo lọọ koju wọn.
Nigba to n fesi, Kabiyesi Olowo sọ pe ireti ọjọ ọla to daju ni Igboho jẹ fun iran rẹ ati irandiran ọjọ iwaju.
O ni ko ma ko aarẹ ọkan pẹlu ogun to n koju, ki oun ati awọn ikọ rẹ si ri i pe wọn n tẹle ofin ilẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Koiki
Kí ló dé tí Sunday Igboho ń ṣe àbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ọba yíká ilẹ̀ Yorùbá?
Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si 'Sunday Igboho' ti pada si orilẹede Naijiria lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye to rọ mọ awọn igbesẹ to gbe lati ja fun ẹtọ ilẹ Yoruba.
Bi ẹ kò ba tíì gbagbe, Sunday Igboho lo n lewaju àwọn ajijagbara miran yíká ilẹ̀ kaarọ Oojire to ń pe fún òmìnira ilẹ̀ Yorùbá.
Igbesẹ yii ni kò dùn mọ ijọba Muhammad Buhari to wa lori aleefa nígbà náà, tí wọn si kọjú oro si àwọn ìgbésẹ̀ rẹ náà.
Lásìkò náà, o koju ọpọlọpọ awọn ipenija nílẹ̀ Naijiria ati ni orílẹ̀èdè Olominira Benin, ki o to lọ fi ori pamọ si orílẹ̀èdè Germany, lasiko iṣejọba aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Oloogbe Mohammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Koiki
Lati igba ti Igboho si ti de padà laipẹ yii si orilẹede Naijiria, lo si ti n ṣe abẹwo si awọn ọkanojọkan ọba alade nilẹ Yoruba.
Lára àwọn ọba tí Sunday Igboho tí ṣe ago láàfin sí ní Olugbon, Soun, Alaafin, Eleruwa, Ọlọwọ àti àwọn miran.
Ìbéèrè tó sì n gbe ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nínú ni pe ki lo n gbe ajafẹtọ ẹni káàkiri ọdọ àwọn oriade nílẹ̀ Yorùbá.
Ìdí rèé tí BBC News Yorùbá fi ṣe àkójọpọ̀ irinajo Sunday Igboho sáwọn ọba alaye yìí àti ohun tó wáyé ní ọhun.
Aafin akọkọ tí Sunday Igboho ṣe abẹwo si ni aafin Olugbọn Orile Igbọn, Oba (Dr.) Francis Olushola Alao.
Nibẹ lo ti ṣe alaye wi pe oun ko tii jẹ anfani ẹkunrẹrẹ ominira ti ofin fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
O ni ijọba orilẹede yii ṣi n fitina oun nipasẹ bi wọn ṣe gbẹsẹ le apo asunwọn owo òun làwọn banki ati bi orukọ rẹ ṣe n bẹ lara orukọ awọn afurasi ti jọba apapọ n wa.
Nibi abẹwo ti Igboho ṣe si aafin Olugbọn naa lo ti n ke si ijọba apapọ orilẹede Naijiria lati yọ orukọ oun kuro ninu awọn ẹni ti wọn n wa.
Igboho ni ibi ti o ti fẹ lọ gba iwe igbelu Naijiria lorilẹede Germany ni wọn ti sọ fun oun pe ijọba apapọ ti kọ orukọ oun si ara awọn eeyan ti ko le gba iwe naa.
Eyi si lo mu kí Olugbon ke si ìjọba àpapọ̀ láti forí jin Sunday Igboho nítorí kii ṣe ọ̀daràn tí wọn ń wa kiri.

Oríṣun àwòrán, Koiki
Lẹyin abẹwo ti Oloye Igboho ṣe si aafin Olugbọn, bakan naa ni o tun ti ṣe abẹwo si awọn aafin mii nilẹ Yoruba.
Lara wọn ni ọdọ Alaafin Ọyọ, Ọba Abimbọla Akeem Ọwọade 1.
O tun de ilu Igangan nibi ti o ti le awọn afurasi darandaran lọjọ kini ana.
Bákan náà, o ṣe abẹwo si ilu Eruwa lọdọ Eleruwa, Ọba Oba Samuel Adegbola.
O tun de ilu Ijero ati Ikerẹ Ekiti, ki o to di pe o tun fi ara han ni aafin Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ajibade Gbadegesin Ogunoye III laipẹ yii.
Ẹ̀bẹ̀ tí gbogbo àwọn oriade naa si n bẹ ijọba àpapọ̀ ni pe ko jẹ eburẹ, ko si fi ọwọ́ wọnú nípa Sunday Igboho, ko le ni anfaani sì àwọn àsùnwọ̀n owó rẹ ni banki.
Ireti wa wi pe o ṣeeṣe ki Oloye Sunday Igboho tun ṣe abẹwo si aafin Ooniriṣa, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ọjájá kejì laipẹ laijinna.

Oríṣun àwòrán, Koiki
Kí ló ń gbé Sunday Igboho kiri lọ sáwọn ààfin ọba nílẹ̀ Yorùbá
BBC News Yorùbá kan si Oloye Igboho saaju asiko yii lati gbọ esi ibeere yii, ṣugbọn pabo ni igbiyanju wa ja si nitori eekan ọmọ ilẹ Oodua naa ko tii fẹ ba awọn Akọroyin sọrọ lásìkò yìí.
Ṣugbọn ariwisi ti awọn eeyan n ṣe lori itakun ayelujara ni pe abẹwo naa yoo mu ki awọn lọbalọba ilẹ Yoruba fi agbajọwọ ṣe atilẹyin fun un, paapaa julọ lori awọn ẹsun tí ijọba apapọ orilẹede Naijiria fi kan an.
Bakan naa, ni awọn eeyan kan tun sọ wi pe ifarahan Igboho ni awọn ilu yii yoo jẹ ikilọ fun gbogbo oniṣẹ laabi ati afurasi darandaran to ń hùwà ọ̀daràn yíká ilẹ̀ Yorùbá wi pe ko si ibi ti wọn le sa si nitori pe Igboho ti pada si Naijiria.

Ki lo tí sẹlẹ ṣáájú nípa Sunday Igboho, tí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbé ẹsẹ le owó rẹ?
Oloye Sunday Adeyemo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho jẹ ọmọ bíbí ìlú Igboho nipinlẹ Oyo.
Ọjọ Kẹwàá oṣù Kẹwàá ọdún 1972, eyiun ọdún mẹtalelaadọta sẹ́yìn.
O kopa bíi akíkanjú lásìkò ogun ilu Ile Ife ati Modakeke àmọ́ ọdún 2021 lo di ilumọkaa yíká Naijiria ati lókè òkun.
Èyí kò si sẹ́yìn bo se lọ koju àwọn Fulani darandaran tí wọn ló ń da ẹmi àwọn ènìyàn legbodo lagbegbe Ibarapa, pàápàá ìlú Igangan.
Lẹyin naa lo n pe fun ijijagbara àti òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń tẹle lẹ́yìn.
Ní ọjọ́ kinni oṣù keje ọdún ọdún 2022 ni àwọn òṣìṣẹ́ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria ya bo ilé Sunday Igboho ni Ibadan, ẹmi èèyàn méjì bọ, wọn si ba ọ̀pọ̀ dúkìá rẹ jẹ.
Àmọ́ orí kò òun fúnra rẹ yọ, to si sá lọ si orílẹ̀èdè Olominira Benin ṣugbọn ìjọba àpapọ̀ kéde rẹ bíi adaluru, tí wọn sì gbe ẹsẹ le àwọn àpò àsùnwọ̀n owó rẹ̀ ni banki
O gbinyanju láti wọ bàálù lọ silẹ Germany níbi molebi rẹ wa àmọ́ wọn da lọwọ kọ láti arìnrìnàjò náà, tí ìjọba Benin sì sọ sì àhámọ́.
Lẹyin ọ̀pọ̀ awuyewuye, ilé ẹjọ́ gba idande Sunday Igboho, to si rìnrìn àjò lọ si orílẹ̀ èdè Germany, níbi tó ń gbé pẹlu aya àtàwọn ọmọ rẹ, ko tó padà wá sí Naijiria.















