Aráàlú lu obìnrin tó ń rìn gbéregbère kiri pa, wọn ló jọ ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọrọ lori iṣẹlẹ iṣekupani kan to waye si obinrin kan ti awọn araalu dawọ lu pa niluu Ilorin.
Iṣẹlẹ ọhun waye ni agbegbe Ipata ni deede ago mẹsan an owurọ ni Ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2025.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi fi lede fun awọn akọroyin, lo sísọ lójú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Atẹjade ọhun ṣalaye pe awọn ara agbegbe Ipata ni wọn naka aburu si obinrin oloogbe yìí, pe o jọ ajinigbe, ti wọn si yabo.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police
"Ko pẹ ti a gbe obinrin naa de ile iwosan lo jade laye lẹyin to farapa yanayana nitori ikọlu aráàlú"
Adeyemi ni kete tí ileeṣẹ ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa, ni awọn oṣiṣẹ ọlọpaa gbera, ti wọn si gba obinrin naa silẹ lọwọ awọn eeyan, ti wọn gbe digbadigba lọ si ile iwosan General niluu Ilorin.
"Ko pẹ ti a gbe obinrin naa de ile iwosan, ni dokita jade sọ fun wa pe obinrin naa ti jade laye lẹyin to farapa yanayana nitori ikọlu araalu.
"A ti gbe oku rẹ si ile igbokusi ni ile iwosan, ti iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa."
Ninu atẹjade naa, ileeṣẹ ọlọpaa ni ofin orilẹede Naijiria koroju si pe eeyan fi idajọ si ọwọ ara rẹ, eyi ti wọn ni o sekupa ọpọ eeyan ti ko mọ ọwọ mọ ẹsẹ lori ẹsun ti wọn ba fi kan wọn.
Kọmisan fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, CP Adekimi Ojo psc rọ araalu pe ki wọn maa se suuru, tẹle ofin, ki wọn si maa fi gbogbo ohun to ba n sẹlẹ to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa ni tosi wọn leti.
Ọ tun rọ araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ati ijọba ipinlẹ Kwara, lati gbe ofin duro ni gbogbo agbegbe.
Bawo ni iṣẹlẹ naa se waye?
Iṣẹlẹ yii waye ni Ọja Ipata niluu Ilorin nigba ti awọn eeyan furasi obinrin kan o jẹ ajinigbe.
Oṣojumikoro kan ni wọn fẹsun kan obinrin naa pe o fẹ ji ọmọ gbe saaju ki wọn to yabo, ti wọn si lu ni ilukulu.
Lara nnkan wọn ti ri pẹlu obinrin oloogbe yii ni kaadi ATM ati awọn iwe kan.
Iṣẹlẹ yii n waye laarin oṣu mẹta ti ori ko ọkunrin kan yọ lẹyin ti wọn fẹsun kan oun naa pe, o fẹ ji ọmọ gbe.
Ileeṣẹ ọlọpaa náà lo gbe ọkunrin naa lọ lasiko ìṣẹ̀lẹ̀ naa.















