Seyi Makinde ní òun kò le è bá Ẹlẹ́dẹ̀ yí nínú ẹrọ̀fọ̀ bí igun Wike ṣe kẹ̀yìn sí ìpàdé PDP lẹ́kùn gúúsù

Oríṣun àwòrán, Nyesom Wike/ FB/ Seyi Makinde/FB
Igun ẹgbẹ oṣelu PDP to faramọ Minisita fun olu ilu ilẹ wa l'Abuja, Nyesom Wike, ti kẹyin si abajade ipade ẹlẹkunjẹkun ẹgbẹ naa to waye niluu Eko l'Ọjọbọ.
Awọn eekan lapa Guusu ilẹ wá, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP, lo peju sibi ipade Eko náà.
Ipade náà lo da lori bi iṣọkan yoo ṣe wa, ti PDP yoo si gbaradi silẹ de ibo 2027, àmọ́ Wike pẹlu awọn ikọ rẹ sọ pe awọn ko lọwọ si i.
Iroyin sọ pe igun to tako ipade naa yoo ṣe ipade tiwọn nipinlẹ Zamfara lọjọ Abamẹta ọla.
Nyesom Wike lo tí kéde ṣáájú pé òun kò mọ ohunkóhun nípa ipade apapọ PDP ti yoo waye ni oṣu Kọkanla ọdún yìí nilu Ibadan èyí tó fihan pe ede aiyede n waye laaarin awọn olori ni apa Guusu-Guusu ati Guusu -Ila-Oorun ninu ẹgbẹ naa.
Bakan naa ni igun yii ṣalaye pe ko si ifitonileti rara ki ipade naa too waye.
Wọn ni awọn alaga ati alẹnulọrọ to yẹ ki wọn fi ipade naa to leti ko gbọ nnkan kan nípa rẹ.
Ninu rogbodiyan ti igun Wike gbagbọ pe o wa nilẹ naa ni bi Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ati awọn gomina ti ọrọ wọn papọ ninu ẹgbẹ náà, ti pade l'Ekoo lati ri i pe ipade apapọ ti wọn n gbero rẹ waye ni ilana ofin ẹgbẹ PDP.
Lara awọn eekan PDP to wa nipade naa ni gomina ipinlẹ Osun; Ọmọọba Ademola Adeleke, Gomina ipinlẹ Akwa Ibom tẹlẹ; Emmanuel Udom, Oloye Olagunsoye Oyinlola,(gomina Osun tẹlẹ),oludije dupo aarẹ tẹlẹ ri; Ben Obi, Oloye Olabode George ati awọn ọmọ igbimọ olufọkantan ninu PDP.
Gomina ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri, lo lewaju igbimọ naa, nigba ti awọn ọmọ igbimọ jẹ mẹrinlelogoji (44).
Ẹhonu tí igun Wike ni sáwọn ọmọ ẹgbẹ PDP yoku
Ninu atẹjade ti awọn alaga ẹgbẹ PDP lati Imo, Abia, Cross River, Akwa Ibom ati Rivers jọ buwọlu pẹlu awọn olori ile igbimọ aṣofin ati awọn alẹnulọrọ mi-in l'Ọjọbọ, wọn kede pe:
"Ohun yoowu ki wọn fẹnuko si tabi to jẹ abajade ipade kankan ko fi ẹsẹ mulẹ, ko si si ni ibamu pẹlu ohun ti PDP Guusu Naijiria n fẹ."
" O dun wa pe wọn pe iru ipade bẹẹ lai fi to ọpọ alaga ibilẹ leti, titi kan Akówe apapọ ẹgbẹ ati lọya ẹgbẹ nla wa.
"Ipade Eko naa wa fun adanikanjẹ awọn eeyan perete, a rọ igbimọ amuṣẹṣe apapọ (National Working Committee) ati awọn ti ọrọ kan lati kọyin si abajade ipade yii, eyi ti ko ba ofin mu to si tun le fa ipinya.''
Bẹẹ ni atẹjade igun Nyesom Wike naa wi.
Bí èèyàn bà ń ṣe bíi ọmọ ilẹ̀ẹ́lẹ̀, èmi ki n ba iru wọn ṣe - Gomina Seyi Makinde
Ni ohun to jọ bi idahun si Wike ati igun rẹ lori ipade naa, Gomina Seyi Makinde ṣalaye pe ipade Eko naa ki i ṣe fun imọtaraẹni nikan.
Makinde sọ pe ipade ọhun ki i ṣe fun ipinya ninu PDP, ko si ni nnkan kan lati ṣe pẹlu okunkun rara.
O fi kun un pe ipade ti awọn eekan ẹgbẹ peju si, ti o kere tan, mejila ninu awọn ọmọ igbimọ mẹtadinlogun to n wa fun akoso ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni ẹlẹkunjekun tun wa nibẹ, ki i ṣe ohun ti awọn yọ ṣe.
" Ẹyọkan lati ipinlẹ kan ni. Ipinlẹ mejila pẹlu aṣoju wọn , a ni awọn sẹnẹtọ lati ẹkun Guusu, ẹkun mẹtẹẹta".
" Emi gẹgẹ bi ẹnikan, bi eeyan ba n ṣe bii ọmọ ilẹẹlẹ, emi ki I ba wọn ṣe. Èmi kò sì le ba Ẹlẹ́dẹ̀ tó ń yí nínú ẹrọ̀fọ̀ ṣeré.
"Ki lohun ti a n gbiyanju lati ṣe?
A n gbiyanju lati ko gbogbo awọn alẹnulọrọ papọ ni PDP, ka le baa ni ọna abayọ mi-in ni Naijiria lọjọ iwájú.
"Oṣelu ni wa, apa Guusu si ti lọ jinaa ninu ipinnu wọn, a ṣi maa ṣepade nla, o si da wa loju pe awon to n sọ pe PDP ti ku ti mọ pe ko ri bẹẹ mọ bayii.
"Ẹ maa bẹrẹ si i ri awọn nnkan ta a sọ ninu ipade yii laipẹ"
Makinde lo sọ bẹẹ.
"A kò tí ì fẹnukò lórí ẹkùn tí yóò fa ààrẹ kalẹ̀ ní 2027''

Oríṣun àwòrán, @PDP
Gẹgẹ bi Gomina Seyi Makinde ṣe wi, ipade ti wọn ṣe naa ko fẹnuko lori apa ibi ti wọn yoo ti fa oludije dupo aarẹ kalẹ ninu ẹgbẹ PDP ni 2027.
O ni o yẹ ki ẹgbẹ kọkọ duro re nílẹ̀ na, ki awọn too maa sọrọ nipa oludije.
Makinde sọ pe bi ẹgbẹ ko ba si, ko si ohunkohun ti awọn le ṣe.
O ni gbogbo ipa lawọn n sa bayii lati ni PDP ti yoo fẹsẹ mulẹ, ti yoo si kari, eyi ti yoo jẹ iwuri fun awọn ọmo Naijriia, ti wọn yoo si gbagbọ ninu rẹ.














