"Ẹni ọdún 56 ni mí, mo wá ọmọ fọ́dún 24, mo lóyún ìbẹta, dókítà ní kí ń fọ́ wọ́n dànù àmọ́ Ọlọ́run padà ṣe ìbejì"
Bi o ba se wu Oluwa, lo n se ọla, Kabiyesi si ni, ko si ẹni to le bii lere pe bawo lo se pin in.
Amọ ohunkohun ti Oluwa ba ti pinnu lọkan rẹ, ẹda kankan ko le di lọwọ.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu obinrin kan, Olusọaguntan Funmilola Abraham, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ri, ẹni to ti n wa ọmọ lati ọdun mẹrinlelogun sẹyin.
Amọ lẹyin ọpọ ọdun yii, Oluwa gbọ ẹkun obinrin naa, to si di Ọlọmọ laye, koda, iya ibeji ni tori ọmọ meji ni Ọlọrun fun ni ẹẹkan soso.
Bawo wa ni irinajo rẹ se ri nidi wiwa ọmọ ati bi ọba oke se da lohun?
Pasitọ Funmilola Abraham ba BBC News Yoruba sọrọ nipa oore nla ti Ọlọrun se fun lẹyin ọpọ ọdun naa.
Bakan naa, o tun salaye irinajo rẹ lati di ọlọmọ laye eyi to kun fun ireti, ijakulẹ, ẹgan ati ayọ nigbẹyin.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Pasitọ Funmilola Abraham ni iyalẹnu ni pe isẹ iransẹ ti Ọlọrun pe oun si ni lati maa gbadura fun awọn eeyan to n woju Ọlọrun fun ọmọ bibi.
"Ko tiẹ wa ye mi bi Ọlọrun se gbe isẹ iransẹ awọn eeyan to n woju Ọlọrun le mi lọwọ.
Ọpọlọpọ eeyan ni Ọlọrun ti lo mi fun lati bimọ laye.
Awọn miran ti bi ibẹrin, ibẹta, ibeji ti ko se ka ati ẹyọ kang an wa lara wọn.
Mo wa n beere pe ki lo wa sẹlẹ si emi, ti temi fi ri bayii?
Nigba mii, oogun ti wọn ba fun mi nile iwosan, maa ko diẹ fun awọn ẹlomiran tabi ki n kọ orukọ oogun naa fun wọn pe ki wọn lọ ra.
Wọn maa ra oogun naa, wọn yoo si loyun, wọn a bimọ.
Mo maa n sọ fun Ọlọrun pe ko tiẹ wa wo emi, ko da mi lohun nidi ọmọ bibi."
Pasitọ Funmilola Abraham tẹsiwaju pe oun se ilana igbalode lati loyun ti a mọ si IVF fun igba akọkọ, ti oun si loyun.
"Mo wa se IVF akọkọ, bi a si ti se tan bayii, Jesu Oluwa gbakoso, mo loyun ibẹta.
Inu wa dun gan ni, ẹ wa wo ayọ amọ bi mo se gbe de osu marun, mow a lọ se ayẹwo Scan.
Wọn sọ fun mi pe awọn ibẹta naa ko mi daadaa, ọna abayọ si ni pe ki n lọ fọ awọn ọmọ mẹtẹẹta naa danu.
Isẹlẹ yii jẹ oun to ba mi ninu jẹ kan, ti mo ke gidi, mo wa tun pada lọ."
Amọ Funilola Abraham pinnu ninu ọkan rẹ pe niwọn igba to jẹ pe kii se ọmọ lo maa mu oun de ijọba ọrun, oun yoo kuku maa woran nipa ọmọ bibi.
Funmilola tẹsiwaju pe "Mo ni ki n ma wulẹ kuku se wahala kankan nipa ti ọmọ.
Amọ ti n ba ro ti ọkọ mi, nigba ti mo ri pe n ko se nnkan osu mọ, mo sọkun kikoro gan bi nkan mii.
Mo wa sọ fun wipe abi ka dọgbọn si ni, ko ma di pe emi ni mo n da duro.
Mo ni ko lọ fẹ ẹnikan amọ se lo gbe ẹnu mi sọhun, pe ki ni mo n gbiyanju lati sọ.
Amọ lẹyin o rẹyin, ọ̀rọ ẹbi yii di ayọ."
"Mo gba obinrin kan nimọran, ko dun mọ ninu, o si fi aibimọ bu mi, mo sọkun gidi"
Pasitọ Funmilola Abraham tun salaye awọn akoko manigbagbe lasiko to n woju Ọlọrun fun ọmọ.
O ni oun ko le gbagbe ọjọ kan ti oun n pari ija ninu idile kan amọ ti obinrin kan fi airi ọmọ bi bu oun eyi to ba oun ninu jẹ pupọ.
"Mo gba eeyan kan nimọran ni, bi mo se da ẹjọ yẹn, a se ko dun mọ obinrin yẹn ninu.
Bi obinrin naa se bẹrẹ ti mi niyẹn, o ni wn kii ri ọmọ lẹyin ejo, o ni ẹni ti ko bimọ, to n tun ile onile se.
Odidi ọsẹ kan ni mo fi sun ẹkun nipa ọrọ naa.
Ninu ọdun ti a wayii ni Ọlọrun alaaye da mi lohun, gbogbo igboya ni mo fi sọ pe Jesu lo se iyanu naa fun mi, kii se nipa ẹnikankan."
Fun igba akọkọ, awọn eeyan ti ko mọ orukọ mi, mọ ọ lonii - Emmanuel Abraham
Emmanuel Abraham, tii se ọkọ Pasitọ Funmilola, naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa bi inu rẹ se dun si lori bi Ọlrun se fi ibeji ta wọn lọrẹ lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn fi duro.
O salaye pe ọpọ eeyan to ti gbagbe oun tẹlẹ, lo bẹrẹ si ni pe oun lori aago lati ki oun ni kete ti wọn bi awọn ibeji naa.
"Fun igba akọkọ, awọn eeyan ti ko mọ orukọ mi, mọ ọ lonii.
Awọn ọrẹ to ti gbagbe mi, n pada pe nọmba mi loniii."






