Nǹkan yan! Ìyá arúgbó ẹní ọdún 70 bí ìbejì, bàbá ọmọ f'ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ

Oríṣun àwòrán, WHIFCug
Iya agabalagba ẹni aadọrin ọdun kan ti bi ibeji lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ ilana fifi atọ ọkunrin si ara ẹyin obinrin ni ilana isegun igbalode, taa mọ si IVF fun un.
Ni akọsilẹ, oun ni obinrin to dagba julọ nilẹ Africa gẹgẹ bi ile iwosan to bimọ si ti ṣe sọ.
Ile iwosan Women's Hospital International and Fertility Centre to wa ni Kampala,Uganda sọ pe Safina Namukwaya bi ọkunrin kan ati obinrin kan layọ ati lalaafia.
''Iroyin yi ko kan da lori aṣẹyọri ilera bi kii ṣe pe o ni ṣe pẹlu iduroṣinṣin ọkan ẹdamọniyan''
Bayii ni ile iwosan naa ṣe ṣapejuwe iṣẹlẹ yi soju opo wọn ni Facebook lẹyin ti arabinrin Namukwaya moribọ nibi iṣẹ abẹ ti wọn fi gbẹbi awọn ọmọ naa lỌjọru.
Igba keji ti yoo bimọ ree laarin ọdun meji

Oríṣun àwòrán, Women's Hospital International and Fertility Centre
Bi eeyan baa n ṣe kayeefi lori bi iya yi ṣe bimọ lẹni ọdun aadọrin, ko ni fẹ panu de to ba gbọ nkan taa tun ri gbọ nipa ibimọ rẹ.
Arabinrin Namukwaya sọ fun ileeṣẹ iroyin aladani NTV pe igba keji ree ti oun bimọ laarin ọdun mẹta sẹyin.
Eyi tunmọ si pe o finu ṣoyun to si bi wẹrẹ lọdun 2020.
Nigba naa lọhun gẹgẹ bo ṣe wi, ọmọ obinrin lo bi.
Ṣaaju asiko yi ko tii bimọ ri rara to si ti sọkan nuu pe oun yoo bimọ laye.
Arabinrin Namukwaya ṣalaye pe orisi idẹyẹsi loun koju nitori aibimọ ko to di pe ọrẹ rẹ kan juwe ile iwosan ti wọn ti ṣe ayẹwo fun.
Wọn sọ fun nile iwosan naa pe oju ọna ti ẹyin n gba de ile ọmọ rẹ taa mọ si 'fallopian tube' lo di ti wọn si baa ṣeto bi yoo se lọ geere.
Igba akọkọ ti wọn da aatọ ati ẹyin rẹ papọ si lo loyun lai si idiwọ.
Nigba keji yi to pada wa bi ibeji,Arabinrin Namukwaya loun koju ọpọ inira
to fi mọ pe baba awọn ọmọ naa paa ti lalae tọju rẹ.
''Awọn ọkunrin kii fẹ gbọ pe oyun ọmọ to ju ẹyọ kan lọ lo wa ninu iyawo wọn. Lati igba ti wọn ti gbe mi sile iwosan yi ni ko ti yọju mọ.''
O ku bi maa ṣe tọju ọmọ mẹta fun araami
Ti a ba fi ibeji yi kun ọmọ obinrin kan to wa nilẹ tẹlẹ, o di ọmọ mẹta bayii ti Eledua fi ta arabinrin Namukwaya lọrẹ.
O ṣalaye pe oun ko mọ boun yoo ṣe da nikan tọju awọn ọmọ wọnyi.
Amọ o ni inu oun dun pe lẹyin ọpọ ọdun toun ko ri ọmọ bi tawọn eeyan si n bu oun lori rẹ,idunnu lo jẹ pe oun ni ọmọ mẹta.
O ni''nigba kan ọmọ ọkunrin kekere kan n tẹle mi kiri to si sọ fun mi pe iya mi lo ṣepe fun mi pe mi o ni bimọ titi ti maa fi jade laye.''
Ọpọ awọn obinrin lode oni lo ti ni anfaani lati bimọ nipa iṣẹ abẹ ilana fifi atọ ọkunrin si ara ẹyin obinrin ni ilana isegun igbalode, taa mọ si IVF.
Ipenija kan to kan wa pẹlu rẹ ni pe owo rẹ gọbọi ti ipa ọpọ ko si kaa lati jẹ anfaani rẹ fi di ọlọmọ laye.












