IVF: Ìyá ìbejì se IVF mẹ́ta lókè òkun, ìkẹrin tó se ní Nàíjíríà, ló fi bímọ
Ọdun meje ni Okiki Marinho fi n wa ọmọ, to si gbiyanju ilana fifi atọ ọkunrin si ara ẹyin obinrin ni ilana isegun igbalode, taa mọ si IVF.
O se IVF ni ẹẹmẹta ọtọọtọ ni oke okun, amọ igba kẹrin to pinnu lati se IVF ni ilu Eko, lorilẹ-ede Naijiria, lo di iya Ibeji.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Okiki ni owo ilana IVF wọn, ko si rọrun rara, bẹẹ ni eeyan nilo adura, ati iranwọ awọn ẹbi rẹ, ko to se aseyọri lori rẹ.
Bakan naa, lodi si ero awọn eeyan kan pe, ọmọ ti wọn ba bi ni ilana IVF kii dape lara, Okiki ni imọ sayẹnsi ti lọ siwaju kọja ero yii. tori bibi ọmọ ni ilana IVF lawọn oyinbo tẹwọgba bayii ju nini oyun nilana abalaye lọ.