Ayọrinde: Èpè rẹ kò le mú olóṣèlú tó o bá gbowó lọ́wọ́ rẹ̀
Oludije fun ipo Gomina labẹ ẹgbẹ oselu ANRP, Ọlalekan Ayọrinde, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, Olusọaguntan ile ijọsin oun ni Amẹrika lo ta oun ni idi kan lati pada sile.
Ayọrinde ni ojisẹ Ọlọrun naa lo bi oun pe ki lo de ti awọn ọmọ Naijiria se maa n jafafa nilu oyinbo, lai lee tun ilu wọn se.
O wa foju abuku wo iwa awọn araalu to maa n gba owo lọwọ awọn oloselu ki wọn to dibo fun wọn, eyi to ni o n mu ki wọn wọ majẹmu pẹlu awọn oloselu yii, epe ti wọn ba sẹ ko si lee mu oloselu.
Ayọrinde wa rọ awọn araalu lati maa beere eto rere ti oludije ni fun wọn, ki wọn to dibo fun, dipo ki wọn maa gba owo lati se ọbẹ lọwọ rẹ, tori ohun to n tan ni owo ọbẹ.