Mi ò ní sinmi, àyàfi kí n fojú àwọn tó pá Taiwo Oyekanmi hàn fáyé rí - Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, OGUN GOVERNMENT
Gómìnà ipinle Ogun, omoba Dapo Abiodun ti ṣe ileri láti ri dájú pé gbogbo agbara ni òun yóò sá láti rí pé ọwọ tẹ àwọn amokunseka tí wọ́n gbà ẹ̀mí olusiro owó ni ẹ̀ka ofisi rẹ, Ogbeni Taiwo Oyekanmi.
Gomina ṣe ileri yìí, lásìkò tí ó ń gbé aba isuna 2024 kalẹ nílé ìgbìmò asofin ipinlẹ Ogun lọjọbọ.
Abiodun ni inu ibanuje àti iporuru ọkan ni òun àti àwọn ọmọ igbimo ìṣàkóso ipinle Ogun wa láti ìgbà tí ìròyìn ikú Ogbeni Taiwo oyekanmi tí to òun létí.
Ogbeni Taiwo oyekanmi ni wọ́n pá sínú agbára ẹ̀jẹ̀ laana ni ori afara tí ó lọ láti Kuto sí Oke Mosan lọsan-an ọjọ́ru lásìkò tí ó ń bọ̀ láti ilé ifowopamo tí ó ti lọ gba owó tí ẹnikẹ́ni kò mọ iye rẹ lórúkọ ijoba.
Awọn agbebon tí a ko tii mọ ohunkohun nipa wọn titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni wọn lọ dawọn lọna ti wọn si pa oluṣiro owo ọhun. pá tí wọn sì gbé owó náà lọ.

Oríṣun àwòrán, OGUN GOVT.
Akọroyin BBC News Yoruba ti o wa ni ile igbimo asofin ipinlẹ Ogun jabọ pé pẹ̀lú aidunu ọkàn ni Gomina fi ń ka aba eto isuna ọdún 2024 tí ó ń gbé sì iwájú àwọn ọmọ ilé.
Gómìnà ni kí àwọn ènìyàn dakẹ iṣẹju kan fún oloogbe náà láti fi bù ọlá àti ẹyẹ ìkẹyìn fún un.
Bakan naa lo kẹ́dùn pẹ̀lú ọmọ, aya, ara, ẹbi àti ìyá tí oloogbe Taiwo Oyekanmi fi sílẹ̀ sáyé.
Bẹẹ náà lo tun kẹ́dùn pẹlu ijoba ibilẹ Ipokia tí oloogbe náà tí wá àti àwọn òṣìṣẹ́ ipinle Ogun lapapọ lórí ikú ọkàn lára wọn tí ó di olóògbé.
Gómìnà Abiodun ni ọdún 2019 ni òun pàdé Ologbe Taiwo Oyekanmi nígbà tí òun de ofisi gẹ́gẹ́ bí gomina ipinle ogun.
Ó ṣàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́, ẹni tí ó fi ara jin fún iṣẹ tí ó sì máa ń ṣe akitiyan láti rí pé nǹkan lọ létòletò.
Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa bí àwọn adigunjálè ṣe já owó ọ́fíìsì gómìnà Ogun gbà l‘Abeokuta

Oríṣun àwòrán, others
Ni ọjọru, awọn adigunjale kọlu ọkọ agboworin kan to n gbe owo ijọba ipinlẹ Ogun ti wọn si gba owo naa lọlẹyin ti wọn yinbọn pa adari ẹka iṣuna lọfisi gomina ipinlẹ naa.
Ohun ti agbọ ni wi pe lati ile ifowopamọsi kan lagbegbe kan nilu Abẹokuta ti wọn si nkọri si ọfissi ijọba ipinlẹ naa nigba ti awọn adigunjale naa ti wọn jẹ marun un niye dabu wọn lọna.
Awọn adigunjale naa dabu ọkọ agboworin atọwọda naa lasiko to fi n sọkalẹ lori afara Kutọ, ti wọn si ṣina ibọn fun akọwe owo naa, lẹyin eyi ni wọn si ja ibi ti wọn ko owo naa si ti wọn si koo lọ.
Nigba ti wọn gbe e de ile iwosan ijọba to wa lagbegbe Ijaye, akọwe owo naa ti dakẹ.
‘awọn adigunjale naa fi iboju bo oju wọn lasiko ti wọn fi ṣe ọṣẹ naa’
Ohun ti a gbọ ni pe banki Fidelity ati Sterling Bank to wa nilu Abẹokuta ni Ọgbẹni Taiwo Oyekanmi to jẹ Oludari ẹka iṣuna ni ọfiisi gomina ipinlẹ Ogun ti lọ gba awọn owo naa ti ẹnikẹni ko le e sọ ni pato iye to jẹ.
Awọn kan tun sọ pe awọn adigunjale naa fi iboju bo oju wọn lasiko ti wọn fi ṣe ọṣẹ naa.
Nọmba idanimọ ọkọ agboworin naa gẹgẹ bi a ṣe gbọn ni X pilot 13.
Awọn adigunjale naa, ti wọn ko ibọn atamatase AK-47 gbe ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla olomi fadaka
Wọn ni awọn adigunjale naa kọkọ beere boya wọn ni ibọn kankan ninu ọkọ ti wọn si tun beere oludari eto iṣuna naa ki wọn to fi ibinu yinbọn si ilẹkun iwaju ọkọ naa nibi ti Oloogbe Oyekanmi joko si.

Oríṣun àwòrán, others
Ibọn ti wọn yin naa la gbọ pe o ba a ni itan ati ibi nnkan ọmọkunrin rẹ ki o to di pe o dagbere faye nigba ti wọn gbe e de ile iwosan
A tun gbọ pe, ọlọpaa to yẹ ko jẹ ẹṣọ fun wọn ti gba aye lati lọ moju to awọn nnkankan.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, nigba ti awọn adigunjale naa yinbọn fun oludari ẹka iṣuna naa tan ni wọn gbe oolu nla ti wọn si jan an mọ ẹnu ọna ibi ti wọn gbe owo naa si ni inu ọkọ agboworin ọhun ti wọn si ja ilẹkun rẹ lati gbe owo to wa nibẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, others
Awọn afurasi adigunjale ti ṣekọlu si ọkọ ìjọba to n gbe owo bọ lati banki nipinlẹ Ogun, ti wọn si gbe ọpọlọpọ owo lọ.
Bakan naa ni wọn ṣekupa olusiro owo to jẹ osisẹ ijọba ni ẹka eto isuna ni ọfisi Gomina, Taiwo Oyekanmi, ẹni to kọwọrin pẹlu ọkọ naa.
Kọmisọna Ọlọpaa Ogun, Abiodun Alamutu fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni oun ti paa lasẹ pe ki awọn agbofinro gbegi dina gbogbo ẹnubode ipinlẹ Ogun.
O ni ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun tí kesi awọn Ọlọpaa ni awọn ipinlẹ to sun mọ wọn lati ran wọn lọwọ mu awọn adigunjale naa.
Oyekanmi, ẹni to jẹ adari ni ẹka eto isuna ni ọfisi Gomina gba owo lati ẹka banki Fidelity niluu Abeokuta, to si n pada lọ sì ọfisi lasiko ti Ikọlu naa waye.
Osojumikoro to ba Ileeṣẹ Channels TV sọrọ ni awọn marun un lawọn adigunjale to ṣe ikọlu naa ni agbegbe ori afara Kuto, ti wọn si salọ pẹlu owo ìjọba.
Osisẹ ìjọba to ba awọn akọroyin sọrọ ni Oyekanmi ati awọn yooku kọkọ dero ile iwosan General tí Ijaye ni bi ti Oyekanmi ti pada jade laye.
Ẹwẹ, akọwe ìjọba ìpinlẹ Ogun, Tokunbo Talabi ti ṣabẹwo sì awọn mọlẹbi oloogbe ni ile wọn.















