A ò lọ́wọ́ nínú làásìgbò tó ń wáyé láàárín ìjọba Osun àti adájọ́ àgbà -Ẹbí Adedoyin

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Bí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Osun, àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ètò ìdájọ́ àti ìjọba ìpínlẹ̀ náà, àwọn ẹbí Rahman Adedoyin ní àwọn kò mọ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ṣáájú àwọn kan ti ń gbé ìròyìn kiri lórí ayélujára pé làásìgbò tó ń wáyé láàárín gómìnà ìpínlẹ̀ náà àti adájọ́ àgbà ọ̀hún, Adepele Ojo.
Agbẹnusọ ìdílé Adedoyin, Kunle Awojoodu ní kí ẹnikẹ́ni yé lo ìgbẹ́jọ́ Rahman Adedoyin láti fi bo ìwà àjẹbánu èyí tí wọ́n fi kan adájọ́ àgbà náà.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ náà fi léde ní onírúurú ìròyìn ni àwọn ti ń ka lórí ayélujára níbi tí àwọn kan ti ń lọ awuyewuye tó ń wáyé láàárín ẹ̀ka ìdájọ́ àti ìjọba Osun mọ́ ẹjọ́ Rahman Adedoyin lọ́rùn.
Wọ́n ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé àwọn kan, fún ìwà ìmọ́taraẹni nìkan, ń fẹ̀sùn kàn pé nítorí ìgbẹ́jọ́ Adedoyin ni gómìnà ṣe fẹ́ yọ adájọ́ àgbà náà nígbà tó jẹ́ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú gbogbo ẹ̀sùn tí ilé aṣòfin kà sí adájọ́ náà lọ́rùn.
Ó sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé Rahman Adedoyin kò fi ìgbà kankan ṣe òṣèlú rí tàbí ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú àwọn olóṣèlú, pé àwọn kò mọ ìdí tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹyọ nínú ìròyìn náà.
Ó fi kun pé ìdílé Adedoyin ní ìgbàgbọ́ nínú ìbọ̀wọ̀ fún òfin àti títẹ̀lé ìlànà òfin bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ àti pé àwọn kò lọ bẹ̀bẹ̀ tàbí wá ojú àánú ẹnìkankan, ìbáà jẹ́ olóṣèlú tàbí lọ́balọ́ba lórí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ nítorí àwọn ní ìgbàgbọ́ pé ilé ẹjọ́ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.
“Ilé ẹjọ́ jáwa kulẹ̀ nígbà tí wọ́n dája ikú fún Rahman Adedoyin láìsí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ikú ẹni tí wọ́n sọ wí pé ó pa.
“Gẹ́gẹ́ bí ebí tó máa ń tẹ̀lé òfin, a gbà ìdájọ́ náà tí a sì ti pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn láti fi ẹ̀hónú wa hàn sí ìgbẹ́jọ́ náà.
“Fún ìdí èyí, kò bá òfin mú, tí kò sì tọ̀nà kí ẹnikẹ́ni máa so ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé láàárín gómìnà àti ẹ̀ka ìdájọ́ àti adájọ́ àgbà Osun, Adepele Ojo mọ́ ẹjọ́ tó ṣì wà nílé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nítorí òṣèlú.”
Awojoodu fi kun ọ̀rọ̀ pé Rahman Adedoyin kò mọ Gómìnà Ademola Adeleke rí àti pé wọn ò fi ìgbà kankan pàdé rí.
Bákan náà ló ní ẹbí Adedoyin fẹ́ jk kó yé gbogbo ayé pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé kí àwọn ènìyàn dènà, kí wọ́n yẹ̀bàá nínú síso ọ̀rọ̀ tí kò kan àwọn mọ́wọ lọ́wọ́.















