Ìdájọ́ ikú nípa yíyẹgí fún Oloye Adedoyin ni Adajọ́ kéde ǹsìyí

Ile ẹjọ naa gbẹsẹ le iwe iwadii ohun to ṣokunfa iku oloogbe Timothy Adegoke ti awọn akọṣẹmọṣẹ ayẹwo nipa oku meji lati fasiti OAU nilu Ile Ifẹ fọwọ si lori pe awọn to lọwọ ninu igbẹjọ to wa nilẹ naa jẹ ẹni mimọ wọn.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Adepele Ojo fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni Timothy Adegoke wọ sinu ile itura Hilton Hotel, o si sanwo sinu aṣuwọn ifowopamọsi olujẹjọ keje.

“Mo rii pe olujẹjọ akọkọ, (Ramon Adedoyin) jẹbi ẹsun igbimọ lati paniyan ati ẹsun ipaniyan.”

Ile ẹjọ naa tun fi kun un pe ẹri to wa niwaju ilẹ ẹjọ ọhun fihan pe Oyetunde Kazeem wa lara awọn to ṣe iṣẹ ibi naa, nitori eyi oun pẹlu jẹbi ẹsun wọnyii.

Adedoyin

Ile ẹjọ giga tipinlẹ Ọṣun eyi to fi ikalẹ si ilu Osogbo ti dajọ ẹbi ẹsun ipaniyan ati gbigbimọpọ lati pa eeyan lonii.

Adajọ da ẹjọ naa fun oludasilẹ ile itura Hilton Hotel nilu Ile Ifẹ, Ọmọwe Ramon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile itura naa mẹta miran lori iku akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU ti ilu Ile ifẹ, Timothy Adegoke.

Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Adepele Ojo wa dajọ ki wọn lọ yẹgi fun Oloye Adedoyin.

Oloye Adedoyin di ero ile ẹjọ pẹlu awọn mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ lori ẹsun mejidinlogun to nii ṣe pẹlu ipaniyan, igbimọpọ lati ṣekupani pẹlu imulẹ atawọn ẹsun miran.

Adedoyin

Oríṣun àwòrán, @Adedoyin

Adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Onidajọ Adepele Ojo, ninu idajọ to gbe kalẹ lori ẹjọ naa lọjọ Iṣẹgun, tu mẹta ninu awọn olujẹjọ silẹ labẹ ẹsun ipaniyan, igbimọ pọ lati ṣeku pani.

Awọn ti wọn tu silẹ naa ni Magdalene Chiefuna, Lawrence Oluwole ati Adedeji Adesola.

Amọṣa, Onidajọ Adepele Ojo ni wn jẹbi awọn ẹsun yoku.

Amọṣa Adajọ naa ni Oloye Adegoke Adedoyin jẹbi ẹsun ikini, ikeji, ikẹta, ikeje, ikẹsanan, ikarundinlogun ati ikẹrindinlogun.

Awọn oṣiṣẹ ile itura naa mẹta ti ile ẹjọ da lẹbi pẹlu Oloye Adedoyin ni Adeniyi Aderogba, Oyetunde Kazeem ati Adebayo Kunle.

Adájọ́ Ojo ti kéde pé Adedoyin jẹ̀bí gbogbo ẹ̀sùn tó wà níwájú òun

Adajo Àgbà ile ejo giga ni ilu Osogbo ipinle Osun, Onidajo Adepele Òjó, ti so pe pelu gbogbo ẹ̀sùn tí wọn fi kan ẹniti o ni ile ìtura Hilton àti ẹri to wa niwaju oun, fi han gbangba pe Dokita Adedoyin lowo ninu iku Timothy Adegoke.

Adajọ Adepele Ojo ti dájọ́ pé Falana láṣẹ́ lábẹ́ òfin láti ṣojú ìpínlẹ̀ Osun àti ìdílé Timothy

Adajo Adepele Ojo

Oríṣun àwòrán, @Adepele Ojo

Adajọ Adepele Ojo ti dájọ́ pé Falana láṣẹ́ lábẹ́ òfin láti ṣojú ìpínlẹ̀ Osun àti ìdílé Timothy

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adajo ti bẹrẹ idajọ ni ẹyọ kọọkan bayii.

Ejọ akọkọ ni eyi ti Agbjọrọ awọn olujẹjọ Adedoyin pe ti wọn sọ pe Falana ko lẹtọọ lati ṣoju ipinlẹ Osun ati ididle Adegoke Timothy lasiko to bẹrẹ si ni ṣoju wọn.

Wọn sọ pe awọn iwe Mo-gba- ki agbẹjọrọ tuntun tẹsiwaju lori ẹjọ mi to ye ki ileeṣẹ ijọba lori ọrọ ofin ti ipinle Osun fi ranṣẹ sile ẹjọ ko tete de laisko.

Pe fun idi eyi Falana ko lẹtọ lati ṣoju wọn rara nitori igbẹjọ ti bẹrẹ tipẹ ki Amofin Femi Falana to pada da síi.

Sugbọn Adajo Ojo ti da ẹjọ naa nu.

Kini Idajo akọkọ lonii?

Adajọ ti dajọ́ pé Falana ni àṣẹ láti ṣojú ìjọba Osun àti ìdílẹ̀ Timothy Adegoke.

Adajo Àgbà ipinle Osun ká àwọn ẹsun orisirisi tí àwọn agbejoro olujejo tí gbé sì iwájú ilé ẹjọ́ ṣáájú .

Lori ẹsun pe bóyá agbejoro àgbà Femi Falana ni ẹtọ láti dúró fún Ìjọba ipinle Osun àti ẹbí olóògbé olupejo ni Adajo Àgbà Adepele Òjó ti faagi lé pé ẹnikẹ́ni kọ́ ni ẹtọ lábé òfin láti tako igbèsè Ogbeni Femi Falana àti àwọn alabasisepo rẹ.

Adajọ Agba náà sì fi idi rẹ múlẹ̀ pé Agbejoro àgbà Femi Falana ni àṣẹ lábẹ́ òfin lati ṣoju ipinlẹ̀ Osun

Awon Olujejo

Idajọ kejì ni Adajọ Adepele Ojo fẹ́ bẹrẹ bayii lori ẹsùn keji ti Agbejọrọ awọn Olujẹjọ Adedoyin pe...

Adajọ Ojo ṣàlaye fun awọn to wa nile ẹjọ pe lọkọọkan ni won yoo seto idajọ naa loni ki ẹjọ naa le pari bi o ti yẹ labẹ ofin.

Adajọ Agba Adepele Ojo ti wọlé sí yàrá ìdájọ́ báyìí, Ó sì ti jókòó lórí àga ìdájọ́

Wọn ti kò àwọn olujejo de ile ẹjọ́, tí wọn sì ń retí adajo àgbà fún. Ìdájọ́

Àwọn agbejoro olujejo tí fi ara wọn hàn bẹẹ ni àwọn agbejoro olupejo náà tí ṣe bá kan náà

Idajọ Timothy Adegoke
Idajọ Timothy Adegoke
Idajọ Timothy Adegoke
Idajọ Timothy Adegoke

Lára àwọn ìdájọ́ tí yio wáyé looní ni ilé ẹjọ́ ni bóyá agbejoro àgbà Femi Falana ni àṣẹ láti sójú fún ìjọba àti fún olupejo rárá.

Elekeji ni ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pá Timothy Adegoke sílè Ìtura Hilton Dr Ramon Adedoyin n'ilu Ilé-Ifè, tí wọn sì fẹ́ kí adajo àgbà Adepele ṣe idajọ náà fún olúkúlùkù àwọn a fẹ̀sùn kàn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ló nínú òfin orile-ede Naijiria

Idajọ Timothy Adegoke
Adedoyin

Oríṣun àwòrán, @Others

Òní ni ìdájọ́ lórí ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke yóò wáyé

Lonii, ọgbọn ọjọ, oṣu Karun un, ọdun 2023 ni idajọ lori iku Timothy Adegoke to ku sile itura Hilton yoo waye.

Ṣaaju ni adajọ agba ipinlẹ Osun, to tun jẹ adajọ to n gbọ ẹjọ naa niluu Osogbo, Adepele Ojo, sun idajọ naa si oni yii.

Oludasilẹ ile itura naa, Oloye Adedoyin n jẹjọ ẹsun ipaniyan lẹyin iku oloogbe naa nile itura rẹ.

Awọn oṣiṣe ile itura naa to tun n jẹjọ ni Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderogba, Oluwole Lawrence, Oyetunde Kazeem, Adebayo Kunle ati Adedeji Adesola.

Asiko igbẹjọ naa ninu oṣu Kẹrin ni adajọ gba awijare ikẹyin lọwọ ikọ agbẹjọro olupẹjọ atawọn olujẹjọ.

Ṣaaju ni ikọ agbẹjọro awọn olujẹjọ, Yusuf Ali, Rowland Otaru, ati Murtala Abdulrasheed, ti kọkọ bẹ ile ẹjọ naa lati maṣe faye gba agbẹjọro agba, Femi Falana, lati ṣoju fun ẹbi Timothy Adegoke.

Wọn ni ki ile ẹjọ gbe igbesẹ naa latari pe Femi Falana ati Fatima Adesina kuna lati fi ẹri han wọn gba aṣẹ lọwọ agbẹjọro agba ipinlẹ Osun lati ṣoju ẹbi Adegoke.

Amọ Falana ni oun ti gba aṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ naa ki oun to gba ẹjọ ọhun ro.

O ni adajọ agba ipinlẹ naa ti ran agbẹjọro mẹta sile ẹjọ lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, lati fa igbẹjọ ọhun le oun lọwọ.