Murphy Afolabi : Alfaa tó kédé orúkọ Adunni Ade ní gbangba gẹ́gẹ́ bí ajigbèsè Murphy Afolabi ṣe ohun tó kù díẹ̀ káà tó – Sheikh Akeugbagold

Àkọlé fídíò, Akeu gbagold sọrọ lori sisan gbese oku

Gbajumọ aṣiwaju ẹsin Islam kan, Sheik Azeez ti ọpọ mọ si Akeugbagold ti sọ pe ninu ẹsin Islam dandan lo yẹ ki wọn san owo gbogbo ti eeyan to ba ku jẹ ki wọn to gbe e wọ kaa ilẹ lọ. O ni bi a ba wa ri ẹni to ku ṣugbọn ti owo to ni ko to san awọn gbese to jẹ, awọn mọlẹbi rẹ ati gbogbo awọn ti ogun rẹ tọ si gbọdọ da owo jọ lati san igbese naa.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba nilu Ibadan ni Alfa Akeugbagold ti yannana ọr yii.

Ibeere naa jẹyọ pẹlu bi oniruuru ọrọ ṣe ja ranyiranyin lọjọ diẹ sẹyin nigba ti alfaa kan pe orukọ gbajugbaja oṣere, Adunni Ade nibi eto fidau ti wọn ṣe fun ọku gbajumọ oṣere tiata, Murphy Afọlabi to jade laye laipẹ yii, gẹgẹ bi ara awọn to jẹ eekan oṣere tiata naa lowo ko to ku to si gbdọ wa san.

Bi o tilẹ jẹ wi pe Adunni Ade ti jade pẹlu awọn ẹrin isanwo pe oun ti san owo ọhun fun Murphy ko to ku, nitori naa oun ko jẹ ẹ ni igbese kankan, ọpọ awọn eeyan lo ti n bu ẹni atẹ lu Alfa naa ati awọn ọmọ igbimọ isinku Murphy Afọlabi pe o ku diẹ kaato fun wọn lati maa da orukọ oṣere naa ni gbangba laikiiṣe wi pe wọn ko ni ọna miran lati kan sii.

idi ti haya to gun ju ninu Al-Quran da lori ọrọ igbese

Ninu ọrọ rẹ, Alfaa Akeugbagold salaye pe Ọlọrun ko fi oju kekere wo ọrọ igbese, ko si fẹ ki eeyan jẹ igbese biotiwukomọ.

O sọ ninu ifọrọwerọ naa pe ohun ti ẹsin Islam fi lelẹ ni pe ki wọn to wẹ fun oku rara, wọn kọkọ gbọdọ yanju gbogbo igbese to ba jẹ, kii tiẹ n ṣe lẹyin ti wọn ba sin oku bẹẹ.

Bi ẹni ti oku ba jẹ lowo ba wa yaafi igbese bẹẹ, a jẹ wi pe iyẹn ti lọ.

Awọn to beere awọn to jẹ Murphy Afọlabi lowo ṣe daadaa ṣugbọn ohun to ku diẹ kaato ninu rẹ ni bi wọn ṣe polongo rẹ sita fun araye.

"Bi igba pe wọn fẹ fi onitọhun ṣẹsin leyi ri."

O ni iwa to ku diẹ kaato ni didarukọ ti wọn darukọ awọn to jẹ oku ni gbese, ati pe awọn to ba tun darukọ awọn ti oku pẹlu jẹ lowo n fi oku ṣe ẹsin ni.

O wa bu ẹnu atẹ lu awọn alfa to pariwo pe awọn ko le kirun si Murphy lara.

"|se awọn ni Ọlọrun to fẹ gbọ adura ni? A saa ti gbọ pe o kirun ko to ku. O ṣeeṣe gan ko jẹ ẹni mimọ niwaju Ọlọrun ju Alfa naa lọ."