Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá "Part 2 Ti Oluwa Nile" dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande

Àkọlé fídíò, Baba Wande: Ọlọ́run ti kẹ́ mi, mi ò ní ìmọ̀lára pé tunde Kelani ò san owó "Part 2" fíìmù "
Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá "Part 2 Ti Oluwa Nile" dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande

"Ootọ ọrọ ni, emi o mọ irọ pa, titi di isinsiyii, Tunde Kelani nikan lo n ta apa keji "Ti Oluwa Ni Ilẹ" oun nikan si lo n da a na, ko fun mi ni nkankan nibẹ amọ mo dupẹ pe Ọlọhun kẹ mi".

Agbaọjẹ oṣere ni Alhaji Kareem Adepoju ti ọpọlọpọ mọ si Baba Wande, gbogbo ololufẹ fiimu aṣa ati iṣe Yoruba ko le ṣai ma wari fun un.

ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba, Baba Wande ṣalaye bi ohun ati agbaọjẹ ayasinima, Tunde Kelani ṣe bẹrẹ, adehun ti wọn ṣe lati jọ maa ṣiṣẹ pọ amọ ti ko wọ ati bi wọn ṣe pada joko pọ lati ṣe apa keji sinimi "Ti Oluwa Nile" eyi ti awọn eeyan ti n beere fun tipẹ tipẹ.

Baba Wande

Bawo ni ọrọ ṣe di ija laarin Tunde Kelani ati Baba Wande?

Aworan Baba Wande ati Tunde Kelani

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Nigba taa bẹrẹ, yara Tunde Kelani ni mo maa n sun taa ba lọ ṣe fiimu, nigba to ya, a ṣe adehun lati jọ maa ṣe ere pọ to si ni oun yoo maa fun mi ni 30%".

Baba Wande ni nigba ti awọn bẹrẹ si ni ṣe fiimu gẹgẹ bi adehun, Tunke Kelani kọ lati fun oun ni ida gbọn ti awọn jọ fẹnu ko le lori to si dun oun.

Bi ẹ ba ranti, ẹyin ololufẹ fiimu "Ti oluwa Nile" naa lẹ n beere fun apa keji.

Ki wọn to lee jọ joko pọ sọrọ lati ṣe apa keji yii, ọjọ lọ lori rẹ gan tori pe wọn ti pinya fun igba diẹ nigba naa.

Amọ Baba Wande jẹ ko di mimọ pe lẹyin apa keji fiimu naa ti awọn ṣe sita, oun ko beere owo kankan lọwọ Tunde Kelani mọ bẹẹ si ni Kelani gan o sọ pe ki oun wa gba owo.

O ni awọn eniyan tilẹ ni ki oun ti ọwọ ofin bọ ọrọ naa amọ o sọ fun wọn pe "ọrọ ẹnu la fi ṣe adehun nigba naa, aa si le wa fi ofin pari rẹ".

Ẹwẹ, Baba Wande ni nibayii, ọrẹ ni oun ati Tunde Kelani, ati pe Ọlọrun ti kẹ ohun de bi pe oun ko ni imọlara pe Tunde ko san owo fiimu "Ti oluwa Nile" ti awọn jọ ṣe fun oun mọ.