Bàbá Wande ní gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù lòun ì bá jẹ́ ká ní òun kò ṣeré tíátà

Oríṣun àwòrán, Baba wande
Gbajumọ àgbà ọjẹ osere tíátà, Alhaji Kareem Adepoju, tí gbogbo ènìyàn mọ sí bàbá Wande, tí ṣàlàyé nípa iru èèyàn tó jẹ́ àti bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ère tíátà.
Bàbá Wande, lásìkò to ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ni, ọmọ bibi ìlú Osogbo ni òun, tí òun sì lọ sile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ Ansardeen àti ilé ẹ̀kọ́ mọda.
O ni odun mẹẹdọgbọn ni òun fi kọ iṣẹ́ tíátà lọdọ oga òun, Oyin Adejobi, àmọ́ ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ni òun ti ní ìfẹ́ sì ère tíátà nígbà tí olóògbé Adejobi máa ń wà ṣe ère nílé ẹ̀kọ́ òun.
- Àwọn èèyàn kò fi bẹ́ ẹ̀ ní ìbálòpọ̀ lásìkò ìgbélé yìí - Iléèṣẹ́ kọ́ńdọ́ọ́mù Durex
- Ayẹwò kò dáwọ́ dúro botílẹ̀ jẹ́ pé èròjà ayẹwò (Reagents) kò si mọ́
- Èmi àti Sanyeri ti tọrọ oúnjẹ jẹ rí nílé oninawo torí ebi, ká tó di gbajumọ oṣere
- Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣ'ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Bíṣọ́ọ́bù Oyedepo pé kò sí ìdí tí iléèjọ́sìn láti wà ní títì pa
Adepoju ni òun bẹ̀rẹ̀ ère tíátà, tí òun sì ni ìlọsíwájú nínú eré itage, Atọ́ka, fídíò àgbéléwò àti sinima, kò tó di pé òun dá dúró, láti máa ṣe iṣẹ́ ti ara òun.
Nígbà tó ń ṣàlàyé lórí imisi to ni nípa kíkọ ère Ti Olúwa Nile, bàbà Wande ni ilu Eko ni imisi náà tí wá, nígbà tí wọ́n ń ṣe ipilẹ ile ni oru, tí wọn sì ń kọ ilé náà ni oru, ó wá gbosuba fún Tunde Kelani tó fi owó tí sinima náà nìdí, tó fi di fíìmù àgbéléwò.

Oríṣun àwòrán, Baba wande
Bákan náà lo ṣàlàyé nipa ìròyìn kan tó já nilẹ pé òun fẹ́ gbé Tunde Kelani lọ sílè ẹjọ́, gbajumọ osere náà ni ìròyìn eke ni ìròyìn náà, òun kò sọ bẹẹ, òun kò sì leè gbé Kelani lọ sílè ẹjọ́ láéláé.
Bàbá Wande fikùn pé "Mo fẹ́ sọ ere 'Tí Olúwa Ni Ilẹ̀' di sinima, máa si parọ àwọn oṣere tó kopa ninu rẹ, tí yóò fi bá ìlànà tode òní mú."
O tun sísọ lójú rẹ pé, inu sinima 'Ilé Tí A Fi Itọ́ mọ' ní òun ti ń jẹ orúkọ Baba Wande, èyí tó wà di Gbajumọ títí di òní, kii sì ṣe wípé òun bí ọmọ kankan tó ń jẹ Wande.
Bàbá Wande ni, ti òun kò bá ṣe ère tíátà, bóyá agbabọọlu ni oun kò bá jẹ, èyí tí yóò sì fún oun ní òkìkí gidi bíi ère tíátà.


Bàbá Wande, ẹni tó koro ojú sì àṣà aṣọ iwọkuwọ àti fífi ara sílẹ̀ nínú eré, ní àṣà tí kò dára ní, àwọn sí ti ń ṣe idanilẹkọọ fún awọn obìnrin oṣere tó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, láti pinwọ ṣíṣe àṣà burúkú náà .
Gbajumọ osere náà, tó ni òun kò leè sọ iye sinima tí òun ti kopa ninu rẹ, wá fi to àwọn olólùfẹ́ rẹ létí pé, òun sì ń kopa gidi nínú eré lásìkò yìí, àmọ́ ni àwọn ojú òpó ayélujára ni kí wọn tí máa pàdé òun.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa akẹẹgbẹ rẹ, Ògún Majek, tí ìròyìn gbalẹ pé ó ṣe alaisi laipẹ yii, Bàbá Wande ni irọ ni, Ogun Majek sì wá láàyè, tí àlàáfíà sí ti ń to lọwọ.
Tunde Kelani: Èmi ò jẹ́ Baba Wande lówó lórí fíìmù Ti Olúwa nilẹ̀
Gbajugbaja olosere Tunde Kelani ti sọ wi pe irọ ni ọrọ ti Baba Wande sọ, wi pe o yan oun jẹ, lori owo to san fun un lorii fiimu ‘Ti Olúwa nilẹ̀’.
Fun igba diẹ bayii ni ariyanjiyan ti wa lori ẹni to ni fiimu ‘Ti Olúwa nilẹ̀’ ti ‘Mainframe’ gbe jade lọdun 1993, pẹlu Kareem Adepoju ti gbogbo eniyan mo si ‘Baba Wande’, ti Tunde Kelani si se olootu rẹ.
Tunde Kelani nigba to n ba BBC sọrọ sọ wi pe oun ko yan Baba Wande jẹ, ati wi pe ẹtọ rẹ lohun fun un lẹyin ti won gbe fiimu naa jade, lẹyin to sọ wi pe awọn to n se ayederu filmu naa ko jẹ ki ere ko wa lori rẹ.
Lopin ọsẹ ni Iwe Iroyin kan sọ pé Baba Wande fẹsun kan Tunde Kelani wi pe owo to tọ si oun, kọ ni wọn fun oun lori fillmu naa ti o si jẹ wipe oun lo kọ itan naa.
Amọ, Baba Wande nigba to n ba BBC sọrọ wi pe oun ko ni ija pẹlu Tunde Kelani, sugbọn otitọ ni wi pe Kelani yan oun jẹ lori filmu naa.
















