Tithing: Daddy Freeze àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míì ta gbá òjíṣẹ́ Ọlọ́run torí ègún ìdá mẹ́wàá

Oyedepo

Oríṣun àwòrán, @DavidOyedepoMin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ṣe ni ori ayelujara tun n gbona tori ọrọ ida mẹwaa ti olori ìjọ Living Faith, Bisọọbu David Oyedepo sọ ni ọjọ Ẹti.

Bisọọbu Oyedepo, lo sọ loju opo Twitter rẹ pe egun ọda owo yoo ja ẹnikẹni ti ko ba da ida mẹwaa fun ijọ Ọlọrun.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Oyedepo ni "Ida mẹwaa jẹ majẹmu pẹlu Ọlọrun ti ko ṣe e yẹ, laisi ida mẹwaa, ko see ṣe lati ṣe rere tabi ni ọrọ, aisan ida mẹwaa si lo n fi ẹ sinu egun ọda owo.

Bakan naa lo fikun pe" ọna to n gba ṣe akoso ẹnawo rẹ ni yoo sọ bo ṣe lowo si nitori ọpọ isoro ti ẹda n koju la le e tọ ipasẹ rẹ de idi ibasepọ rẹ pẹlu owo. "

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria to ka ọrọ yii lo faraya, ti wọn si ni irufẹ ọrọ bayii ko dara rara.

Nigba to n fesi lori ọrọ Oyedepo naa, Ifedayo Olarinde, ti ọpọ eeyan mọ si Daddy Freeze ni ọrọ radarada ni ojisẹ Ọlọrun naa kọ, ti ko si bojumu.

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Other

"Ṣe o ni ida kan owo ti awọn olowo agbaye bii Jeff Bezos, Bill Gates ati Warren Buffet, ti kii san ida mẹwaa ni bi? Mo ri ọrọ yii bii eyi ti ko ba Bibeli mu, to si jẹ iwa ika si ọmọniyan?

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Daddy Freeze ni Jesu tabi awọn ọmọ ẹyin rẹ ko gba ida mẹwaa nigba aye rẹ, ofin atijọ ni sisan ida mẹwaa jẹ, idi si ree ti Kristẹni fi n pe ofin majẹmu laelae ni ofin ẹsẹ ati iku.

Ẹ yé tako ìjọba lórí iléèjọ́sìn títì pa, ẹ jọ̀wọ́ ṣọ́ọ̀ṣì yín fún ìtọ́jú àwọn tó lárùn coronavirus- Tunde Bakare

Oludasilẹ ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti rọ awọn alufa ijọ bi tiẹ lati jọwọ gbọngan ile ijọsin silẹ fun ijọba lati loo fun ibudo itọju awọn alaisan coronavirus.

Pasitọ Bakare sọrọ yii ninu fidio kan to wa lori ayelujara eleyi tawọn eeyan ti n sọrọ nipa rẹ.

Alufaa Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Twitter/Pastor Tunde Bakare

Pasitọ Bakare ni ijọ Latter Rain gan an ti jọwọ gọngan meji to jẹ ti ṣọọṣi naa fun ijọba ipinlẹ Eko lati lo fun ibudo iyasọtọ awọn to ti lugbadi coronavirus.

Bakan naa lo sọ pe ijọ naa tun ti jọwọ ile kan niluu Abẹokuta fun ijọba ipinlẹ Ogun lati lo fun itọju awọn to laarun covid-19.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

O bu ẹnu atẹ lu awọn ojiṣẹ Ọlọrun kan ti wọn sọ pe ko yẹ ki ọja wa ni ṣiṣi nigba ile ijọsin wa ni titipa.

Alufaa Bakare nisẹ lo yẹ kawọn ojiṣẹ Ọlọrun ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati gbogun ti ajakalẹ aarun coronavirus to n ba gbogbo aye finra lọwọ yii.

O ni o yẹ kawọn ile ijọsin nla jọwọ lo ohun ini wọn lati ran ijọba lọwọ, dipọ kawọn olori wọn maa tako igbesẹ ijọba lori ofin konle-o-gbele.

Alufaa Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Twitter/Pastor Tunde Bakare

Pasitọ Bakare ni ṣọọṣi nikan kọ ni ijọba fofin de, o ni o kan mọṣalaaṣi naa.

O ṣalaye pe ijọba ko gbe ọja tipa nitori ki ebi maa ba pa ọgọrọ araalu to jọ pe iṣẹ oojọ ni wọn n ṣe ki wọn to le jẹun.

Alufaa Bakare lu awọn oṣiṣẹ eleto ilera lọgọ ẹnu lori iṣẹ takun takun ti wọn n ṣe lasiko ajakalẹ coronavirus yii, o gbadura fun aabo Ọlọrun lori wọn.

Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣ'ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Bíṣọ́ọ́bù Oyedepo pé kò sí ìdí tí iléèjọ́sìn láti wà ní títì pa

Bisọọbu David Oyedepo, nínú ìsìn irọlẹ Ọjọru faraya lórí bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ti ilẹkun mọ àwọn sọọsi àmọ́ tó ń sì àwọn ọjà oúnjẹ gbogbo fún wákàtí mẹ́fà gbáko, nibiti àwọn aráàlú kò ti bọ̀wọ̀ fún òfin títa kété síra ẹni.Ọ̀rọ̀ ojisẹ Ọlọ́run náà sì lo tí ń fa awuyewuye làwọn ojú òpó ikansiraẹni lórí itakun àgbáyé , bí àwọn èèyàn kan sì ṣe tako èrò rẹ, ni àwọn míràn fara mọ.Kódà, ọ̀rọ̀ náà kò tíì tán lójú òpó BBC Yoruba, nibiti àwọn èèyàn ti ń gbáà ọrọ náà mọ ara wọn lọ́wọ́, bíi ẹni gba igba ọtí.

Lérò tí Ajayi Solomon, oúnjẹ leè gbé ẹmi ró gẹ́gẹ́ bíi ẹlẹ́ran ara àmọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ni oúnjẹ ẹ̀mí tí yóò jẹ ká dàgbà nínú ìwà rere, tí yóò sì jẹ ká ye, ó ní ọjà àti sọọsi lo yẹ kí ìjọba sí papọ.

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tako èrò rẹ yìí, ní èrò tí Nurudeen Mufc Bamidele, kò sì ibi tí èèyàn kò ti leè gbọ ọrọ Ọlọ́run, tí Dára Dariz Ogunsola náà sì kin lẹ́yìn pé oúnjẹ kii wọnú, kí ọrọ miran wọ ọ, bí àwọn èèyàn kò bá jẹun, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò leè wọ wọn létí.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì dá sí ìjíròrò náà lo fara mọ pe oúnjẹ ní kókó, kódà, Oluwaseun Abiodun ni, niwọn ìgbà tí àwọn ilé ìjọsìn kò ní fún àwọn ni oúnjẹ jẹ, ọjà tí àwọn yoo ti rí oúnjẹ rà ni pàtàkì. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn míràn yí ọ̀rọ̀ náà si ibòmíràn, tí wọ́n sì ni torí owó tí àwọn ìjọ Ọlọ́run kò rí pa wọlé mọ, ní ojisẹ Ọlọ́run náà ṣe ń pariwo lórí bí ìjọba ṣe tí ilé ìjọsìn pá.

Awọn ero ninu ijọ kan

Oríṣun àwòrán, davidoyedepomin

Afolabi Idris Wayforward ń tiẹ̀ ń béèrè pé kí ló dé tí Oyedepo fi fẹ́ kí jọba si sọọsi pẹ̀lú tipátipá, ṣe nítorí owó tí kò wọlé fún àwọn ojisẹ Ọlọ́run mọ ni?

Ìmọ̀ràn tí àwọn èèyàn mìíràn bíi Ojo Omoniyi wá ń gba aráàlú ni pé, bí wọn ṣe gba wọn láàyè láti lọ sí ọjà, ṣe ni kí wọn tẹle òfin títa kété síra ẹni, kí a máa bàa wá jẹbi lẹ́yìn ó rẹyìn.

Oyedepo: Ẹ ṣílẹ̀kùn ọjà àmọ́ ẹ ti ilẹkun ilé Ọlọ́run, ejò lọ́wọ́ nínú - Oyedepo pariwo

Oyedepo

Oríṣun àwòrán, @DavidOyedepoMin

Oyedepo, ẹni tó pariwo bẹẹ lásìkò ìsìn wákàtí àdúrà tó wáyé ní Ọjọru ni, òun fura pé ejò lọ́wọ́ nínú lórí bí ìjọba kò ṣe tíì pàṣẹ láti ṣílẹ̀kùn ilé Ọlọ́run padà.

"Ẹ ní kí wọn máa ṣílẹ̀kùn ọjà gbogbo fún wákàtí mẹ́fà, kí wá lo dé tí ẹ kò fi silẹkun sọọsi fún wákàtí méjì, mo ní ìgbàgbọ́ pé iditẹ mọ ìdàgbàsókè àwọn sọọsi ni Nàìjíríà ni èyí".

"Mo ń fura pupọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ọlọ́run bá mi sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa ni àná, àbí ọ̀nà wo ni wọn tún fẹ́ gbà láti dá sọọsi lọwọkọ kò má baa gbòòrò, oyè èyí kò ye àwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ yìí kan."

Oyedepo ni ohùn òkùnkùn lo fẹ́ ń darí àwọn èèyàn ní gbogbo ẹ̀ka yìí, tó sì dojú kọ ìjọ Ọlọ́run nítorí bí àwọn sọọsi ṣe ń gbòòrò lo ń fọ èṣù lórí, àmọ́ ẹnu ọ̀nà ọrùn àpáàdì kò ní borí,

Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ yóò jìyà rẹ.

Oyedepo tún wà ń béèrè pé" irú ilé ìwòsàn wo ló ń ṣe àṣeyọrí ìwòsàn bíi èyí táwọn ìjọ Ọlọ́run ńṣe?

Ó ní ilé ìwòsàn tí àwọn èèyàn ń kú sí wa ni ṣíṣí silẹ àmọ́ wọn ti ilẹ̀kùn ilé Ọlọ́run nítorí ìwà ìjẹgàba Èṣù, èyí tí kò ní ìwòsàn.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn nǹkan mẹ́rin tó yẹ kó wà nínú báàgì rẹ lásìkò Covid-19 yìí

Bishop Oyedepo: Ìlẹ̀ Amẹrika ní ìròyìn òfegè ní pé àwọn fi físà dun Bísọ̀bù Oyedepo

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Twitter/US Mission Nigeria

Irọ lasan ni, iroyin ofege lawọn eeyan kan n gbe kaakiri.

Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ti fesi si si iroyin to lu oju ayelujara pa laarọ ọjọ Ẹti pe wọn o fun oludasilẹ ijọ Living Faith Church ti ọpọ mọ si Winners, Bisọọbu David Oyedepo.

Iwe iroyin Thisday lo kọkọ gbe iroyin naa pe olu ile iṣẹ ilẹ Amẹrika ni Naijiria kọ lati fun Bisọbu ni fisa.

Amọ olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika ṣalaye loju opo Twitter wọn pe irọ funfun balau ni iroyin naa.

Wọn rọ awọn eeyan ti wọn ti ri iroyin naa lori ayelujara wi pe ki wọ kọ eti kun sii nitotri kosi otitọ kankan nibẹ.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Olu ileeṣẹ ilẹ Amẹrika sọ loju opo Twitter wọn pe iṣinilọna gbaa ni iroyin naa to jade.

David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bishop David Oyedepo

Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori ayelujara lati aarọ ọjọ Ẹti lati igba ti iroyin naa ti jade.

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

Skip X post, 7

End of X post, 7

Skip X post, 8

End of X post, 8

Skip X post, 9

End of X post, 9

Skip X post, 10

End of X post, 10

Skip X post, 11

End of X post, 11