Akpabio list: James Manager, Peter Nwaboachi, Samuel Anyanwu fèsì sí ẹ̀sùn ti Godswill Akpabio NDDC fi kàn wọ́n

Godswill Akpabio NDDC

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé àwòrán, Sen. Godswill Akpabio, Hon. Olubunmi Tunji-Ojo, Sen. James Manager, Kemebradikumo Pondei
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 12

Àwọn èèkàn nínú òṣèlú Nàìjíríà ti mínísítà fún ọ̀rọ̀ Niger Delta Godswill Akpabio nànka sí pé àwọn ni wọ́n ń gba kọngilá iṣẹ́ NDDC ti fèsì pé àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni ọ̀rọ̀ Akpabio, ati pe ko ni ẹ̀ri kankan.

Peter Nwaboachi, tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ tẹ̀ẹ́kótó ilé lórí ọ̀rọ̀ Niger Delta lónìí ọjọ́ ajé, sọ pé ko si 'òòtọ́' kan nínú ọ́rọ́ ti mínísítà sọ.

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà ni ti Akpabio ba tó bẹ́ẹ̀, ti ǹkan to n sọ sì dáa'lójú kó kọ gbogbo àwọn iṣẹ́ kọngila ti àwọn gbà síta, kí àwọn àjọ tó n'mójú to ìwà àjẹbánu láwùjọ sì ṣe ìwádiìí tọ yẹ lórí rẹ̀.

Akpabio ni Nwaboachi ti gba iṣẹ́ kọngilá tọ tó mẹ́tàléláàdọ́ta lọ́wọ́ àjọ náà.

Gẹ́gẹ́ bi àtẹjáde ti Nwaboachi fi síta ṣe sọ, ó ní kí mínísítà kọ́kọ́ sàlàyé àwọn owó bílíọ̀nù to ná nínàkúnà náà lásìkò ti àwọ ìgbìmọ̀ IMC san fún ara wọ́n pẹlu ibuwọ́lù Godswill Akpabio.

Godswill Akpabio NDDC Probe: Olubunmi Tunji-Ojo

Oríṣun àwòrán, Ile igbimo

Àkọlé àwòrán, ọmọ ilé igbimọ Asofin Olubunmi tunji-ojo ní lati yọ ara rẹ̀ kuro ni ibujoko awon to n se iwadii.

Ọkan nínú àwọn ti ọ̀rọ̀ yìí kan bákan náà Samuel Anyanwu, sọ fun BBC pe ẹkun ibi ti òun ṣoju fun ni òun ni ki wọ́n dari ṣẹ́ o tọ́ si wọ́n lọ, ati pé oun ko gba iṣẹ́ kankan.

"Gbogbo ẹ̀sùn ti Akpabio fi n kan tabi o sọ ko ní ìtumọ̀. Mo sọ̀na bi iṣẹ́ yóò ṣe de ìhàn ìlàoorùn Imo nípinlẹ Imo, nítori pe o wa lára àwọn ibi ti NDDC ń mójú tó, nítori náà gẹ́gẹ́ bi asojú ẹkùn náà ni mó ṣe gbé iṣk lọ si bẹ̀. Mí ò gba kọngila gẹ́gẹ́ bi ọlọ́dani"

Anyanwu fi kun pé nítori pé òun jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ PDP ní oùn ni Akpabio ṣe n so irú nkan bẹ́ẹ̀ láti fi ba orúkọ oun jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bi àwọn oníròyìn abẹ́lé ṣe sọ Akpabio ni Anyanwu gba kọngila mọ́kandílógún.

James Manager náà wà lára àwọn ti Akpabio naawọ́ sí pé ó gba kọngilá mẹ́fà, sùgbọ́n Manager náà ni òun ko gba kọgila kankan.

"NDDC kò gbé iṣẹ́ kankan jáde si ìta debi ti mo fẹ́ ri kọngila gba. Mi o mọ ilé iṣẹ́ ti mo ni ti mo fẹ́ fi gba iṣẹ́ kọngila ìjọba níbì kankan ni aye yìí. O le ya àwọn eǹìyàn lẹ́nu, sùgbọ́n òòtọ́ọ́ ọ̀rọ̀ ni" ọ̀rọ̀ ti Manager so fun BBC rèé nínú àtẹ̀jáde to fi sọ̀wọ.

Gbogbo èyí wáye lẹ́yin ti abẹnugan ilé Femi gbajabiamila sọ pé òun yóò fi ọwọ́ òfin mu Akpabio ti ko bá dárúkọ àwọn ọmọ ilé to n gba iṣl kọngila NDDC

NDDC Probe

Oríṣun àwòrán, NDDC

Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọ́n Kemebradikumo Pondei

Sáájú ni adarí àjọ NDDC Kemebradikumo Pondei, ti sọ fun ile ìgbìmọ̀ asòfin pé àwọn náà bíliọnù kan àbọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ nítori ààrùn Covid-19''.

Pondei padà dáku, lásíkò ti an fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wo lórí amohunmaworan lori gbogbo ìwà mágòmágó to ṣẹ̀lẹ̀ ni àjọ náà

Godswill Akpabio NDDC vs Gbajabiamila: Ilé Aṣòfin yóò pe Godswill Akpabio l'ẹ́jọ́ fún ìbanilórúkọ jẹ́

Ile Asofin Naijiria

Oríṣun àwòrán, @National Assembly

Ile aṣofin Naijiria kekere sọ pe oun yoo pe Minisita fun idagbasoke ẹkun Niger Delta, Godswill Akpabio, l'ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Eyi n waye lẹyin ti Akpabio kọ lati darukọ awọn aṣofin ti ajọ NDDC gbe iṣẹ fun, gẹgẹ boṣe sọ lasiko ti ile n wadii ẹsun inakuna ti wọn fi kan ajọ naa l'abẹ iṣakoso rẹ.

Ọjọ Iṣẹgun ni olori ile aṣofin naa, Femi Gbajabiamila, kede pe oun fun Akpabio ni wakati mejidinlaadọta lati fi orukọ awọn aṣofin naa sita.

Gbajabiamila sọ ninu ikede kan to fi sita loju opo Twitter rẹ ni ọsan Ọjọbọ, pe oun ti paṣẹ fun akọwe ile aṣofin naa lati lai gba awọn agbẹjọro ti yoo bẹrẹ ẹjọ lori ẹsun iwa ọdaran lori Akpabio.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa lo ni ile aṣofin yoo paṣẹ fun awọn agbẹjọro naa lati pe ẹjọ tako o fun ibanilorukọ jẹ.

Gbajabiamila sọ oun ko ni i fi ọwọ l'ẹran, ko si ma a wo ki ẹnikan ba ile aṣofin naa l'orukọ jẹ, nitori pe o fẹ ẹ ki oju kuro lara ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan-an.

Gbajabiamila ati Akpabio

Ṣé Akpabio ṣetán láti dárúkọ àwọn Aṣòfin tó gba iṣẹ́ àkànṣe lọ́wọ́ NDDC?

Lẹyin ti Ọjọgbọn Pondei daku lasiko ti wọn n fi ọrọ waa lẹnu wo lori nina owo ilu mọkukọku ninu ajọ to yẹ ko mojuto awọn eeyan ẹkun ti Naijiria ti n wa epo rọbi ni ọrọ tun gbẹyin yọ.

Minista Akpabio to n risi ẹkun yii lo sọ lasiko to n jabọ bi wọn ṣe na owo pe awọn Aṣojuṣofin lo n gba iṣẹ akanṣe ida ọgọta ninu ọgọrun un ninu iṣẹ ti awọn ba gbe sita.

O ṣalaye pe eyi jẹ ọkan lara koko ohun ti oun le sọ nipatọ.

Lẹyin naa ni Femi Gbajabiamiala to jẹ Abẹnugan ile aṣofin kekere fun Godswill Akpabio ni gbendeke ọjọ meji lati darukọ awọn Aṣofin ti NDDC gbe iṣẹ akanṣe fun.

Kini ofin sọ lori iṣẹlẹ yii?

Owo to to biliọnu mejilelọgọrin o dín diẹ ni awọn igbimọ oluwadii ile igbimọ Aṣofin n ṣe iwadii rẹ.

Bayii gbogbo ọmọ Naijiria lo n reti ohun to maa ṣẹlẹ lonii ti gbendeke ti Gbajabiamila fun Akpabio pe yii

Amofin Bulama Bukarti to jẹ agbẹjọrọ ni ilu Oba ṣalaye fun BBC pe ti Akpabio ba kọ lati kede orukọ naa, awọn ile igbimọ Aṣofin le sọ fun Aarẹ Buhari lati gab ipo minista naa lọwọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

O ni aba ni eyi, wọn ko le paṣẹ fun un rara.

amofin naa ni ṣugbọn ti ade iwa ibajẹ yii ba jẹ ootọ, ofin ni agbara lati yọ awọn Aṣofin ti Akpabio ba darukọ wọn kuro nipo.

O ni eyi tọna nitori pe o lodi si ofin ile igbimọ Aṣofin ni abala 24 ti 'Code of Conduct Act' fun awọn aṣofin lati maa gba iru iṣẹ akanṣe bẹẹ.

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Adarí àjọ NDDC, Pondei ṣetán láti sọ ohun tó mọ̀ nípa ìwàdíì tó bá ti gbádùn- NDDC

Wọ́n ní Pondei ń ṣàìsàn ló ṣe dákú níwájú ìgbìmọ̀ olùwádíì

Adari Ajọ Niger Delta Commission, Ọjọgbọn Kemebradikumo Pondei n ṣe aisan ni o ṣe daku lasiko ti ile igbimọ aṣofin n fi ọrọ wa lẹnu wo lori iwa ajẹbanu to n waye ninu ajọ naa.

Ajọ NDDC lo fi lede pe o ti to ọsẹ meji ti Pondei ti n ṣe aisan ti dokita si kilọ fun un pe ko ma lọ fun ifọrọwanilẹnuwo to waye ni Ile Igbimọ Aṣofin naa.

Agbẹnusọ fun Ajọ NDDC, Charles Obi Odili ni aisan to n ṣe adari naa peleke si ni aarọ Ọjọ Aje to n lọ si Ile Igbimọ Aṣofin, amọ o pinnu lati lọ ki awọn eniyan ma ro wi pe ko ni otitọ ni ko ṣe yọju.

Wọn fikun un wi pe, Adari ajọ NDDC naa ti wa ni ile iwosan kan bayii ni Abuja.

Pondei

Oríṣun àwòrán, others

Ninu atejade naa ni wọn ti wa salaye awọn ohun to ṣokunkun si awọn eniyan;

Ọjọgbọn Pondei di Adele Adari Ajọ NDDC ni Ogunjọ, Oṣu Keji, ọdun 2020, amọ Ọjọ Karun un, Oṣu Karun un ni Ile Igbimọ Aṣofin paṣẹ ki wọn ṣe iwadii adari naa.

Eyi si ṣẹlẹ ni asiko ofin konile-o-gbele nitori arun Coronavirus.

  • Ootọ ni adele adari ajọ NDDC naa ni aṣẹ labẹ ofin lati dahun gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni ẹka naa, amọ adele naa ko lee dahun ibeere awọn aṣofin naa nitori pe ko si ni bẹ ni ọdun 2008 si 2012 ti iwa jẹgudujẹra waye ni bẹ.
Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....
  • Nigba ti iwadii naa bẹrẹ, ohun ti Ile Igbimọ Aṣofin fẹ mọ ni bi ogoji miliọnu Naira ṣe di awati ni ajọ naa.
  • Ajọ naa si fi lede gbogbo bi wọn ṣe na owo labẹ isakoso Ọjọgbọn Pondei.
  • Amọ, wọn ti sọ iwadii naa di ohun ibanilorukọjẹ fun adele ajọ naa, ti ko si mọ nkankan nipa ẹ.
Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù
  • Bakan naa ni wọn fikun un pe Alaga ajọ NDDC ni Ile Igbimọ Aṣofin naa yọ ara rẹ kuro lasiko ifọrọwanilẹnuwo naa, amọ ki gbogbo eniyan mọ wi pe, gbogbo wọn ni yoo jiyin iṣe naa, paapaa ipa ti ẹni kọọkan ko lati lu owo ajọ naa ni ponpo.
  • Bi Aarẹ Buhari ṣe bẹrẹ iwadii lori bi awọn eniyan ṣe na owo ijọba ni ajọ NDDC lati ọdun 2001 titi di asiko yii yoo ja si aṣeyori ni abẹ isakoso Ọjọgbọn Pondei.
  • Bakan naa ni ajọ NDDC ni awọn gbagbọ wi pe iwadii ti wọn n ṣe naa yoo mu igba ọtun de ba ọjọ iwaju ajọ NDDC.
Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Gbajabiamila fún Godswill Akpabio lọ́jọ́ méjì láti forúkọ àwọn aṣòfin tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ NDDC léde

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ti fun Minisita fun ọrọ Niger Delta, Godswill Akpabio ni ọjọ meji pere lati darukọ awọn aṣofin ti ajọ NDDC n gbeṣẹ fun.

Gbajabiamila/Akpabio

Oríṣun àwòrán, others

Gbajabiamila ni Minisita naa yoo foju wina ofin to ba kọ lati fi orukọ awọn aṣofin ọhun lede ní kiakia.

Igbeṣe yii lo n waye lẹyin ti Akpabio sọ niwaju igbimọ to n ṣewadii bi ajọ NDDC ṣe nawo laarin oṣu Kinni si oṣu Kẹfa, ọdun 2020, pe ọwọ awọn aṣojuṣofin ni pupọ ninu agbaṣẹ iṣẹ NDDC n bọ si.

Idan orita ṣẹlẹ niwaju igbimọ naa nigba ti Akpabio sọ pe awọn ọmọ ile aṣojo-ṣofin "lo n jẹ mudun-mudun iṣẹ agbaṣẹ to n jade lati NDDC."

O tẹsiwaju pe oun ni ẹri ati akọsilẹ to fi han pe lootọ ni awọn awọn aṣoju-ṣofin n gba iṣẹ lọwọ ajọ NDDC.

Ọrọ naa ko dun mọ awọn to n tukọ igbimọ ninu, koda wọn gbiyanju lati pa ọrọ ọhun mọ ọ lẹnu.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Ààrẹ Buhari, ẹ̀yin gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ rántí wa ní Oman, àwọn ọmọ

Gbajabiamila fẹsun kan Akpabio pe ọgbọn olumọkọrọyi lo n lo lati moribọ ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an, bi bẹẹ kọ, ko fi orukọ awọn to n naka si lede.

Ṣaaju ni alakoso fidihẹ NDDC, Daniel Pondei ti kọkọ daku rangbọndan niwaju igbimọ oluwadii naa, nigba ti wọn n da ibere bo bi ẹni to n waṣẹ.

Àwọn ìgba mẹ́rin t'áwọn èèkàn tí dùbúlẹ̀ àìsàn lásìkò tí wọ́n ń jẹ́jọ́ ìwà ìjẹkújẹ

Ni ọjọ Aje, sinima awodamiẹnu kan ṣẹlẹ nibi ijoko iwadii itagbangba lori iṣuna ajọ idagbasoke agbegbe Niger Delta.

Adele oludari agba ileeṣẹ naa, Kemebradikumo Pondei ni awọn aṣojuṣofin n fi ọrọ wa lẹnuwo lori bi wọn ṣe n na ẹgbẹlẹgbẹ owo ajọ naa, amọṣa ṣadede ni Ọjọgbọn Pondei ba ṣubululẹ to si daku.

Oniruuru ariwo ati ọrọ lawọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n sọ lori iṣẹlẹ yii.

Melaye lori stretcher

Oríṣun àwòrán, @sumner_sambo

Amọṣa, ṣe igba akọkọ irufẹ iṣẹlẹ bayii niyi lorilẹ-ede Naijiria? Idahun rẹ ni rara!

Eyi ni awọn igba mẹrin kan tawọn eekan ilu ti wọnu ipo idubulẹ aisan lasiko ti wọn n koju igbẹjọ tabi iwadii lori ọkan o jọkan iwa aṣẹmaṣẹ to niiṣe pẹlu iwa jẹgudujẹra.

Sẹnetọ Dino Melaye

Ni oṣu karun un, ọdun 2018, ileeṣẹ ọlọpaa gbe Dino Melaye to jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin agba nigba naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun to niiṣe pẹlu idibo ni ẹkun aringbungbun ariwa ipinlẹ Kogi.

Nigba ti Dino Melaye yoo fi gunlẹ sile ẹjọ, kayefi lo ṣe ọpọ nigba ti wọn rii lori kẹkẹ alaarẹ ti oloyinbo n pe ni 'Stretcher'

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Olisah Metuh

Ni ọdun 2018 kan naa ni wọn gbe Olisah Metuh to jẹ alukoro tẹlẹ fun gbẹ oṣelu PDP.

Ajọ EFCC gbe Olisah Metuh lọ sile ẹjọ giga kan nilu Abuja fun gbigba irinwo miliọnu naira lọwọ ọfiisi alamojuto abo lorilẹede Naijiria lọdun 2014.

Nigba ti yoo fi wa si igbẹjọ nileẹjọ, gbalaja bayii ni Metuh sun sori bẹẹdi alaarẹ, Stretcher wa si ile ẹjọ

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Maina lori wheelchair

Oríṣun àwòrán, other

Abdulrasheed Maina

Ni ọdun 2019, Alaga nigbakan ri fun ajọ to n ṣamojuto owo ifẹyinti lorilẹede Naijiria, Abdulrasheed Maina naa foju ba ile ẹjọ lori owo to to biliọnu meji naira.

Ile ẹjọ ni ki wọn gbee lọ si ahamọ. Nigba ti Maina yoo fi farahan nile ẹjs nigba miran, ori kẹkẹ ailera Wheelchair lo wa.

Akpabio

Oríṣun àwòrán, facebook/Godswill Obot Akpabio

Gbogbo ohun tí Godswill Akpabio sọ níbi ẹ̀sùn ìnákùnàá tí wọ́n fi kàn án rèé

Lasiko ti igbẹjọ wọn n lọ lọwọ eyi ti igbimọ to n gbẹjọ nipa ajọ NDDC n ṣe, Sẹnetọ Akpabio ni oun ko ja ilana itọpinpin isuna ajọ naa gba bẹẹ si ni oun ko da ẹnikẹni duro lẹnu iṣẹ.

Awọn nkan mii ti Sẹnetọ Godswill Akpabio tun mẹnu ba lonii ree pẹlu bi ọrọ ṣe di fa ki n fa a pẹlu igbimọ to n gbẹjọ gẹgẹ bi wọn ṣe da ọpọlọpọ ibeere bo o.

Sẹnetọ Akpabio ni iṣẹ minisita to n ri si ọrọ ẹkun Niger Delta ni lati maa ṣe abojuto kii ṣe lati dari gbogbo nkan.

Awọn nnkan miran ti Akpabio sọ ree:

  • Akpabio ni oun ko ni erongba kankan lati dije du ipo aarẹ.
  • O ni oun ko ni ki oṣiṣẹ kankan ko biliọnu mẹwaa naira wa. Ko si naira kan ti ẹnikẹni san fun un gẹgẹ bii minisita oun ko si gba kọngilaa iṣẹ akanṣe kankan fun ajọ NDDC.
  • O tẹnu mọ ọ pe ko ṣeeṣe ki ogoji biliọnu naira sọ nu lapoo NDDC toripe asuwọn owo kan ṣoṣo ni wọn n lo. "Ko si ẹni to da na biliọnu mẹjọ naira. Gbogbo owo ti a na ni biliọnu mẹtalelogun naira koda ki Covid-19 to de, ida ọgọta aba eto isuna ajọ NDDC lo ba eto ilera lọ.
Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù
  • Akpabio ni lati igba ti oun ti de ori alefa, iṣẹ kọngila mẹta pere ni wọn gba.
  • O ni ibi ti ajọ NDDC de lonii, tori aisi abojuto to peye ni.
  • O ni ko si iwe faili kankan to sọnu tori awọn ṣe eto gbigbe ibi ti iṣẹ de duro le awọn tọrọ kan lọwọ daadaa.
  • O ni gbogbo rẹ lawọn ko silẹ fun ayẹwo iwe isuna ajọ naa.
  • Akpabio ni ida ọgọta iṣẹ akanṣe ajọ NDDC ni o jẹ pe awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ni wọn gbe e fun.
  • Eleyii gan lo wa di ọrọ rangbọndọn laarin oun atawọn aṣofin bayii.

Ẹwẹ, o ni oun yoo nilo ifọwọsowọpọ ile aṣofin lati fopin si pinpin iṣẹ akanṣe NDDC mọra wọn lọwọ nile igbimọ aṣofin ati ṣiṣe atunto ajọ naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

NDDC Acting MD, Pondei dákú lásìkò tí lásìkò tí ìwádìí n lọ lórí ẹ̀sùn ìnákúnàá

Ọjọgbọn Pondei nibi to ti daku sori aga to joko si i

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Adele Ọga Agba ajọ to n mojuto idagbasoke agbegbe Niger Delta, Ọjọgbọn Kemebradikumo Pondei, daku rangbọndan lasiko ti iwadii ẹsun n waye.

Pondei daku aasiko to n ṣalaye iye owo ti ajọ NDDC na labẹ iṣakoso rẹ.

Ọjọgbọn Pondei nibi to ti daku sori aga to joko si i

Oríṣun àwòrán, Sreenshot

Niṣe ni gbogbo awọn to wa nibi ijoko naa n sare kijokijo lasiko ti Ọjọgbọn Pondei daku lori aga to joko si.

Eyi si mu ki gbogbo awọn to tẹle e wa sibẹ o ma a fẹ ẹ l'oju, fẹ ẹ nimu, rọ omi si i l'ori.

Fidio ibi to ti daku re e:

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Lẹyin naa ni wọn gbe e digba-digba jade kuro ninu yaara ti wọn ti n fi ọrọ wa a l'ẹnu wo.

Ṣaaju ni alaga igbimọ ti ile aṣofin Naijiria gbekalẹ lati wadii awọn ẹsun iwa ibajẹ ninu ajọ to n mojuto idagbasoke agbegbe Niger Delta, NDDC, Olubunmi Tunji-Ojo ti kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Olubunmi Tunji-Ojo

Oríṣun àwòrán, Tunji Ojo

Àkọlé àwòrán, Alága ìgbìmọ̀ tó n wádìí ẹ̀sùn ìnákúnàá nínú àjọ NDDC l'óun kò ṣe mọ́

Ọsẹ to lọ ni awọn alaṣẹ ajọ NDDC, ti Pondei jẹ ọkan lara wọn, binu kuro niwaju igbimọ oluwadii, lẹyin ti wọn fi ẹsun kan Tunji-Ojo pe, ọwọ ti ẹ naa ko mọ́ lori ọrọ naa.

Lati bi ọsẹ melo kan ni awọn adari ajọ naa, to fi mọ minisita to wa fun Niger Delta, Godswill Akpabio, ti n koju iwadii lori bi ajọ naa ṣe na owo ti ijọba fun wọn.

Ẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan bẹrẹ si n jẹ orukọ Joy Nunieh lẹnu lori ayelujara.

Eyi waye lẹyin awuyewuye to waye ninu ajọ NDDC, ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun un ti oun naa si fẹsun jẹgudujẹra kan minisita to n ri si ọrọ Niger Delta, Godswill Akpabio.

Laipẹ yii ni ọrọ kan tun waye ni ile rẹ ti a gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko awọn eeyan wọn lọ si ile arabinrin yii ti wọn si n gbiyanju ati ja ilẹkun wọle lati lọ gbe e lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Iroyin ni ọpọlọpọ gomina Nyesome Wike to n tukọ ipinlẹ Rivers lo wa gbaa silẹ lọ sile ijọba ni Pọta.

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Wọnyi ni awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa arabinrin Joy Nunieh naa:

Joy Nunieh ni ẹni akọkọ ti yoo di agbẹjọro ni gbogbo ilẹ Ogoni lagbegbe Niger Delta, ni iha ila-oorun Naijiria.

Ọmọ ipinlẹ River ni obinrin naa, eyi ko si ṣẹyin bi gomina ipinlẹ rẹ, Nyesom Wike ṣe gba a silẹ ninu ahamọ ti wọn fi si ninu ile to wa lẹyin awuyewuye to waye lẹyinn to kuro ni NDDC.

Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù

Joi Yimebe Nunieh gangan ni apeja orukọ rẹ, ṣugbọn ọpọ eeyan lo mọ ọ si Joy Nunieh.

Oun ni alakoso agba fun ileeṣẹ Hydrocarbon Pollution Remediation Project, (HYPREP) lọdun 2012 ko to darapọ ajọ NDDC.

Nunieh ni ọmọ kẹrin sẹnatọ ati agbẹjọro akọkọ nilẹ Ogoni, Cyrus Nunieh to wa lati ijọba ibilẹ Beeri Khana, ṣugbọn baba rẹ ọhun ti wọ kaa ilẹ sun.

Obinrin naa ti ṣegbeyawo ri, bo tilẹ jẹ pe Akpabio sọ lori ẹrọ tẹlifiṣọn kan pe ọkọ mẹrin lo ti ni sẹyin, ṣugbọn a ko lee fi idi ọrọ naa mulẹ.

Ọgbọn ọjọ, oṣu Kinni, ọdun 2020 ni ẹgbẹ kan ti kii ṣe ti ijọba, Anti-Corruption and Accountability Coalition Against Corruption, fẹsun kan an,

Wọn si kọwe mọọ lọdọ aare Muhammadu Buhari pe ayederu iwe ẹri lo fi n ṣiṣẹ.

Gẹgẹ bi ohun to fi sojo opo LinkedIn rẹ, Joy Nunieh jẹ agbaṣẹṣe to da wa laye ara rẹ fun ileeṣẹ to n pan epo rọbi, Shel, fun ọdun mọkanla gbako.

Bakan naa lo tun gbaṣẹse fun ileeṣẹ Chevron Oil Nigeria Limited fun ọgbọn ọdun, lati ọdun 1989 si 2019.

Oṣu mẹrin pere ni Joy Nunieh lo gẹgẹ bi alakoso fidihẹ fun ajọ NDDC ki wọn to yọ ọ bi jiga loṣu Keji ọdun 2020.