Yoruba Stars in Hollywood / Europe: Sade Adu, Chamillionaire, Sikiru Adepoju wà lára ọmọ Oodua tó jẹ́ àmúlùúdùn níbẹ̀

Yoruba ni ti ọmọ ẹni ba dara, o yẹ ka wi, kii ṣe pe a fi ṣe aya.
Bẹẹ ni ti awọn ọmọ Oodua mẹwaa kan ṣe jẹ, ti wọn n dabira nilẹ Amẹrika ati Yuroopu, paapaa ni ẹka amuludun wọn.
Ọpọ igba ni awọn eeyan maa n sọ pe awọn ọmọ Oodua kan nilẹ okeere maa n ba oju iran Yoruba jẹ.
BBC Yoruba gbe awọn oju oge oju to n gbe ogo Oodua ga nilẹ America ati Europe yii ki awọn ọdọ ọmọ Yoruba to pinnu lati lọ silẹ okeere le ri awokọṣe rere lati ṣoju iran Yoruba daadaa nibi kibi ti wọn ba wa iṣẹ aje lọ.
- Èèyàn 38,344 ló ti ní COVID-19 ní Nàìjíríà lẹ́yìn tí 543 kún un lọ́jọ̀rú
- Kí ló pa Bobrisky àti Olorì Aláàfin Oyo pọ̀?
- Kí ló dé tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde fífagilé Sáà ètò ẹ̀kọ́ kẹta fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́?
- Wo bí ètò ìsìnkú Isa Funtua ṣe wáyé ní ìlú Abuja
- A yìnbọn lu Precious láti dáa dúró ni, akò mọ̀ pé o máa kú- Ọlọ́pàá
Awọn ọmọ Yoruba ti a n sọrọ wọn yii ti laami-laaka to bẹẹ ti wọn fi jẹ aridunnu fun iran Yoruba, o si yẹ ki a maa gbe wọn larugẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn akinkanju ọmọ Oodua to n ṣe bẹbẹ loke okun pọ lọ jantirẹrẹ, amọ ninu akọsilẹ wa, mẹwaa pere ni BBC Yoruba ṣe akojọpọ iroyin nipa wọn ni ẹka amuludun.
Ọmọ Oodua mẹwaa to n ṣe bẹbẹ ni ẹka amuludun loke okun:
1) Sade Adu:
Ilu Ibadan ni wọn bi Helen Folasade Adu si ni ọjọ kẹrindilogun, oṣu kinni, ọdun 1959, tii ṣe ọdun mọkanlelọgọta ṣẹyin.
Baba rẹ, Adebisi Adu jẹ Olukọ ati ọmọ bibi ilẹ Ekiti, ti iya rẹ, Anne Hayes si jẹ oyinbo alawọ funfun, to n ṣíṣẹ Nọọsi.
Nigba ti wọn gbe Sade pada silu Ọba, o yan isẹ orin kíkọ takansufe laayo, to si di gbajumọ akọrin yika agbaye.
Sade Adu gba ọpọ ami ẹyẹ, to si tun jẹ olowo rẹpẹtẹ nilu London, aridunnu ọmọ bibi ilẹ Oodua nii ṣe.

Oríṣun àwòrán, others
2) Sikiru Adepoju:
Ilu Eruwa lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo ni wọn bi Sikiru Adepoju si ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 1950, iyẹn ọdun mọkandinlaadọrin sẹyin.
Agboole Ayan, tii ṣe onilu ni Sikiru ti wa, kekere si ni baba rẹ, Oloye Ayanleke Adepoju ti kọ ni ilu lilu.
Ki gbajumọ afilusọrọ yii to rekọja silẹ Amẹrika lọdun 1985, o ti lu ilu lẹyin gbajugbaja akọrin Juju nni, Ebenezer Obey ri.
Ọdun 1991 lo gba kọkọ ami ẹyẹ Grammy, to si tun gba ami ẹyẹ naa ni ẹẹkeji lọdun 2009.
Ọmọ Oodua to n mu ori ẹni wu lorilẹ-ede Amẹrika ni Sikiru Adepoju, isẹ ilu lilu si lo mu ko laami-laaka.
3) Hakeem Seriki (Chamillionaire):
Ojulowo ọmọ Yoruba ni baba ilumọọka olorin takansufe kan, Hakeem Seriki, ti ọpọ eeyan mọ si Chamillionaire, ti iya rẹ si jẹ Akata nilẹ Amẹrika.
Ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 1979, to jẹ ọdun mọkanlelogoji sẹyin ni wọn bi Chamillionaire silu Texas, lorilẹ-ede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, @Hakeem
Ọdun 2002 lo gbe awo orin akọkọ jade, to si gba ami ẹyẹ Grammy lọdun 2007.
Yatọ si orin kíkọ, Chamillionaire tun jẹ onileeṣẹ adani ati gbajumọ oloko-owo to dantọ, to si jẹ amuyangan fun iran Kaarọ Oojiire.
- Ènìyàn 653 míràn tún kún iye àwọn tó ní COVID-19 ní Nàìjíríà
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
- Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn tí a jọ díje nínú ìdìbó abẹ́lé sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
4) Henry Olusegun Adeola Samuel (Seal):
Ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun 1963 ni wọn bi Henry Olusegun Adeola Samuel, ti ọpọ eeyan mọ si Seal nilu London.
Ogidi ọmọ Kaarọ Oojiire ni Adebisi Ogundeji, tii ṣe iya Seal, nigba ti baba rẹ, Francis Samuel, jẹ alawọ dudu ọmọ orilẹ-ede Brazil.
Seal jẹ onkọwe orin, ọdun 1991 si lo gbe awo orin akọkọ, 'Crazy' sita, eyi to mi agbaye titi, amọ awo orin rẹ ti aye tẹwọgba julọ, 'Kiss from a Rose' lo gbe jade lọdun 1994.
Seal ti ta awo rẹkọọdu to le ni ogun miliọnu sita jakejado agbaye, to si ti gba ami ẹyẹ Grammy nigba mẹrin ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, Others
5) Lekan Babalola:
Ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun un, ọdun 1960 ni Olalekan Babalola de ile aye nilu Eko, kekere si lo ti n lu ilu Konga ni ìjọ Kerubu ati Serafu tawọn obi rẹ n lọ.
Olalekan kawe alakọbẹrẹ nile ẹkọ ti Bishop Oluwole ni Agege, to si tun lọ sile ẹkọ girama nilu Iwo.

Oríṣun àwòrán, @Lekan
O jẹ ẹbun ẹkọ ọfẹ lọdun 1980 lati kawe nipa imọ ẹrọ fun ọkọ ayọkẹlẹ ni fasiti kan nilẹ UK, eyi to mu u kuro ni Naijiria.
Ṣugbọn isẹ orin lo yan laayo ni kete to de ilu Ọba, lẹyin naa lo lọ kawe nipa sinima ṣíṣe, to si gba oye imọ ijinlẹ keji ninu rẹ.
Lọwọ lọwọ bayii, Lekan Babalola ti gba ami ẹyẹ Grammy ni ẹẹmeji, akọkọ lọdun 2006, ẹẹkeji lọdun 2009.
6) Kelvin Olusola:
Ọjọ Karun-un, oṣu Kẹwaa, ọdun 1988, ọdun mejilelọgbọn ṣẹyin ni Kelvin Oluwole Olusola dele aye, ọmọ Oodua pọnbele si ni baba rẹ, iya rẹ si jẹ Akata.
Iṣẹ orin kíkọ si loun naa yan laayo ni Kentucky lorilẹ-ede Amẹrika, to si ti gba ami ẹyẹ Grammy ni ẹẹmẹta ọtọọtọ.
Koda, Kevin ti ta awo orin to le ni miliọnu meji, ti eeyan to le ni biliọnu meji si ti gbọ awo orin rẹ lori YouTube.

Oríṣun àwòrán, Others
7) Oloogbe Babatunde Olatunji:
Michael Babatunde Olatunji jẹ onilu ọmọ bibi ilẹ Yoruba nigba aye rẹ, ati ọmọwe, Ajafetọ awujọ pẹlu agbe awo orin jade.
Ọjọ Keje, oṣu Kẹrin, ọdun 1927 ni wọn bi Olatunji si abule Ajido lẹba ilu Badagry, to si jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Others
Kekere lo ti mọ ilu lu, amọ, ẹkọ ọfẹ ti ẹgbẹ Alaanu Rotary gbe kalẹ lo fun ni anfaani lati lọ silẹ Amẹrika lọdun 1950, níbi to ti kawe.
Olatunji di ilumọọka onilu ni Amẹrika, to jẹ amuyangan fun iran Yoruba, to si gba ami ẹyẹ Grammy nidi orin kíkọ lọdun 1991.
Ọjọ Kẹfa oṣu Kẹrin ọdun 2003 ni Olatunji jade laye nilu California lorilẹ-ede Amẹrika, ti ifẹ rẹ fun ilu lilu si jẹ manigbagbe.
8) Olubowale Victor Akintimeyin:
Ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1984 ni tọkọtaya kan to jẹ ọmọ ilẹ Kaarọ Oojiire, bi gbajumọ akọrin takansufe kan, Olubowale Victor Akintimeyin.
Ilu Washington lorilẹ-ede Amẹrika ni wọn bi akikanju ọmọ Yoruba naa si, to si gbe awo orin akọkọ rẹ jade lọdun 2009.
Olubowale ti gba ọpọ ami ẹyẹ, to si gbe ogo iran Yoruba larugẹ.

Oríṣun àwòrán, others
9) Oluwatosin Ayoyinka Abass:
Oluwatosin Ayoyinka Abasi jẹ akọrin lorilẹ-ede Amẹrika amọ to jẹ ojulowo ọmọ Oodua.
Ọjọ Keje, oṣu Kinni, ọdun 1983 ni Tosin dele aye, to si ti gbe awo orin mẹrin jade, eyi ti aye tẹwọgba.
Ata gita to pegede ni Tosin, to si wa lara awọn ọgọrun atagita lagbaye to jẹ ilumọọka.

Oríṣun àwòrán, others
10) Hakeem Kae-Kazim:
Ilu Eko ni wọn bi Hakeem Kae Kazim si lọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1962 nibi to ti bẹrẹ igbe aye rẹ.
Awọn obi rẹ, ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta, wa isẹ aje lọ silu London, níbi ti oun naa ti bẹrẹ iṣẹ tiata lati ile ẹkọ.
Hakeem ni ohun didun, to si tun jẹ ẹlẹyinju aanu, ẹni to n kopa ribiribi si eto idagbasoke ilẹ Afirika.

Oríṣun àwòrán, @Hakeem













