Police Brutality: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara lé ọlọ́pàá mẹ́rin kúrò lẹ́nu iṣẹ́ fún ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́

Police Brutality: Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara lé ọlọ́pàá mẹ́rin kúrò lẹ́nu iṣẹ́ fún ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti ni kí àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin kan lọ rọ́kún nilẹ̀, nígbà ti àwọn mẹ́jọ mírà wà lábẹ́ ìbáwí fún onírúurú ẹ̀sùn ìwàbàjẹ́.

Gẹ́gẹ́ bi kọmísọnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara Kayode Egbetokun ṣe sọ àwọn ọlọ́pàá náà ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí o buru jáì tó fi mọ ìwá àìbíkítà fún àwọn adari ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá.

Nínú àtẹjáde ti àgbẹnúsọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ajayi Okasanmi fọ́wọ́sí sàlàyé pé kọmísọnà ọlọ́pàá ló paá láṣẹ pé ki wan lọ rọkún nile wọ́n.

Ó ní lẹ́yìn gbogbo ìwádìí, ó fi han pé àwọn ọlọ́pàá náà jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn yi wọ́n fi kan wọ́n, o sì di dandan ki i'sk bọ́ lọ́wọ́ wọ́n.

Àwọn wọ́n ti ìjìyà ki iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn tọ́ si ni ex-Sgt Sola Akano àti ex- Cpl Babatunde Glorious.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan wọ́n pé wọ́n mu ọ̀daran jáde pé awọ́n fẹ́ lọ ṣe ìwádìí, sùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n mú ọdaran náà lọ si ilé ìfówópamọ́ Zenith lopópónà Unity nílùú ilorin lati lọ gba owó to lé ni mílíọ́nù kan Náírà.

Kò tán sibẹ̀, wọ́n tún bèrè fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà náírà lọ́wọ́ ẹbí ọ̀daràn náà gẹ́gẹ́ bi owó béèlì kí wọ́n tó fi sílẹ̀.

Wọ́n gba fóònù afurasí náà, títí di ìgbà ti ọwọ́ òfín ba wọ́n, fóònù méjèèjì ti wọ́n gbà ni wọ́n ti sọ di ti àra wọ́n ti wọ́n ń lò.

Lẹ́yìn ti afuransi náà bọ lọ́wọ́ ọlọ́pàá ló mú ẹjọ́ náà padà wọ́ sí àgọ́ ọlọ́pàá ti ilé iṣk ọlọ́pàá si bẹ̀rl si ni ṣe ìwádìí àwọn ènìyàn náà.

Ẹgbetokun ni ǹkan to buru jù ni pé, lẹ́yìn ti àwọn fi àwọn ọlọ́pàá náà si abẹ́ ìbáwí tán ni wọ́n bẹ̀rl si ni kọ ìwé ẹdun si ọga ọlọ́pàá pátápáta pé,

ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara n fi ìyà jẹ àwọn nítori pé àwọn jẹ́ olóòtọ́ ni.

Police Brutality: A yìnbọn lu Precious láti dáa dúró ni, akò mọ̀ pé o máa kú- Ọlọ́pàá

Olọpaa

Oríṣun àwòrán, others

Ileeṣẹ Ọlọpaa ti ni lootọ ni awọn yinbọn fun ọmọ Naijiria ti orukọ rẹ n jẹ Precious ni agbegbe Gomoa Buduburam ni orilẹ-ede Ghana.

Adari ileeṣẹ ọlọpaa naa, Superintendent Samuel Odame ni awọn yinbọn fun Precious nitori o n dunkooko mọ awọn eniyan ni agbegbe naa ni.

O ni bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni pe awọn eniyan pe ọlọpaa wi pe arakunrin Precious to gbe ada dani naa, ti n ṣa ẹnikẹni ti o ba sun mọ ọ ni ada.

Agbofiro Odame ṣalaye pe nitori naa ni awọn ṣe ran ikọ ọlọpaa lọ si agbegbe naa, ti awọn ọlọpaa si tiraka lati ba a sọrọ, amọ niṣe lo bẹrẹ si ni fi ada le wọn, ti awọn ọlọpaa si salọ fun un.

'A yin ibọn naa lati da duro pẹlu ada ọwọ rẹ, amọ o ṣeni laanu pe o gba ibẹ ku.

A o da aba lati pa arakunrin naa, a kan fẹ ko dawọ duro, A ko fẹ ko maa fi ada le awọn eeyan kiri ni, a ko mọ pe iku lo maa ja si fun Precious.'

Ghana agbofinro

Oríṣun àwòrán, others

Amọ, Odame ko sọ ibi ti ibọn naa ti ba a nitori o le dabaru ayẹwo ti wọn ṣe fun un lẹyin iku rẹ.

Iroyin iku Precious ti da rogbodiyan silẹ, ti awọn ọdọ kan si yabo ileeṣẹ ọlọpaa Gomoa Buduburam ni Ghana.

Àkọlé fídíò, Funmi Adewara: Tele Medicine' ní a fi ń ṣàyẹ̀wò èèyàn ìdá ọgọtá láti dènà ìtànkálẹ̀ Covid

Ohun ti wọn n beere fun ni idi ti awọn ọlọpaa ṣe yin ibọn pa Precious.

Wọn fẹsun kan awon ọlọpaa pe wọn fẹ pa a, ni wọn ṣe yinbọn lu u.

Amọ, Ọga ọlọpaa ni ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.