Alaafin of Oyo: Wo olorì Aláàfin tí àwọn èèyàn ń pariwo pé ó jọ Bobrisky

Olori Anu ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olori anu ati Bobrisky

Gbogbo ọmọ Naijiria lo fẹẹ mọ Bobrisky, iyẹn Idrisu Okunẹyẹ, Ọdọkunrin to n ṣe iṣe obinrin, to n mura bii obinrin.

Amọṣa, kii ṣe tori eyi ni iroyin yii ṣe jẹyọ bi ko sẹ ohun to pa Bobrisky ati iyawo Alaafin, Olori Aanu Adeyẹmi pọ.

Ni aipẹ yii ni iroyin kan pe olori Aanu jade si gbangba walia loju opo ayelujara rẹ to si faraya lori awọn ọrọ iwọsi tawọn eeyan kan n sọ sii loju opo ayelujara.

Olori anu ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olori anu ati Bobrisky

Koda, Olori tun sọ ọrọ yii debi pe awọn eeyan kan n fi oun we Bobrisky pe awọn mejeeji jọra pupọ.

Lootọ mejimeji l'Eduwa da eniyan, gẹgẹ bi awọn agba ṣe maa n sọ, ṣugbọn ọrọ yii ko pa olori lẹrin rara.

Olori Anu ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Alamy

"kato wi ka to fọ, wọn a maa wi pe o jọ Bobrisky, ṣe Bobrisky kii ṣe eeyan ni. Ẹ jọwọ ẹ wọrọ miran sọ."

Eyi lohun tawọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ka mọ oju opo ayelujara rẹ kan.

Olori Anu ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olori Anu/Bobrisky

Amọṣa, lati fi idi ọrọ naa mulẹ gan, awa pẹlu lọ soju opo ayelujara Olori laafin Iku Baba yeye naa.

Ko si aniani pe arẹwa ni olori Anu ti n gbe ọla baba, Alaafin yọ. Koda, gbogbo aworan to wa nibẹ ko sẹni ti ko ni rii pe Olori laafin nla niyi, afi ẹni ti oju ba n dun.

Olori Anu ati Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olori Anu/Bobrisky

Olori Aaanu Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen anu

Àkọlé àwòrán, Alaafin Oyo kò dàgbà jù fún mi, ohun tó wù mí ní mo ṣe pẹ̀lú ayé mi- Olori Aanu

Alaafin Oyo kò dàgbà jù fún mi, ohun tó wù mí ní mo ṣe pẹ̀lú ayé mi- Olori Aanu

Ọkan lara awọn olori Iku Baba Yeye, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla III, Olori Anuoluwapọ Adeyẹmi ti kan lu oju opo ayelujara lati fun awọn to n sọrọ nipa igbeyawo oun ati Ọbalaye naa lesi.

Loju opo instagram rẹ lo ti fesi si awọn to n ṣe marimasọ lori igbeyawo rẹ, eyi to ni wọn ni nitori ati lee di olori lo fi lọ fẹ Alaafin.

O ni ohun to ba wu ẹlẹnu ni ko maa fi ẹnu wọn sọ, amọṣa, Kabiyesi Alaafin ko dagba ju fun oun lati fẹ.

Olori Aanu nu: "Ọkọ mi ko dagba ju fun mi o, ohun to wu mi ni mo fi igbe aye nmi ṣe"

Aworan iroyin naa

Oríṣun àwòrán, Instablog9ja

O ni awọn kan tilẹ tun n sọrọ si oun pe oun jọ Bobrisky. "Ṣe Bobrisky kii ṣe eeyan ni?" ni esi to fi da wọn lohun.

Olori Aaanu Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen aanu

O fi kun un pe pupọ awọn to wa n sọrọ yii ni wọn maa n gba ẹyin wa bẹbẹ fun ohun kan tabi omiran lọwọ oun.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....