Nigeria COVID-19 cases: Abẹ́rẹ́ àjẹsára kò tíì sí fún COVID-19, síbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí ń fi ẹ̀mí wọn wéwu

ọkan lara awọn oṣiṣẹ kolẹ-kodọti

Ọwọja arun coronavirus n fojojumọ peleke sii lorilẹ-ede Naijiria.

Ko tii si abẹrẹ ajẹsara arun naa nitosi, sibẹ omilẹgbẹ awọn ọdọmọkunrin ti wọn n ko idọti lati ojule de ojule ni agbegbe Karu nitosi Abuja lo n fi ọwọ lasan ṣe iṣẹ, laisi ibomu tabi ibọwọ.

Eyi n mu ọpọlọpọ ewu wa fun wọn lati ko arun yii eleyii to ti mu eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹrindinlogoji bi a ṣe n sọrọ yii.

Ọmọ ogun ọdun ni Ibrahim, ara awọn kolẹ-kodọti ni oun naa. Ni ọdun mẹta sẹyin lo fi ilu rẹ ni Katsina silẹ wa si ilu Abuja fun igbe aye to larinrin sii.

Amọṣa, iṣẹ kolẹ-kodọti lo ri ṣe eyi ti ko si lee fun un ju aadọta si ọgọrun un naira.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Lojumọ nigbamiran, Ibrahim ni oun a maa pa to ẹgbẹrun meji naira, tabi ẹgbẹrun kan abọ naira nigba ti ọja ko ba ya.

"Lara awọn nnkan ti mo n ri ṣa kiri lati igba ti arun naa ti bẹrẹ ni ibomu, ibọwọ, igo ọṣẹ apakokoro Sanitaisa atawọn ohun eelo idaabobo ṣugbọn mi o ni idaabobo kankan.

ọkan lara awọn oṣiṣẹ kolẹ-kodọti

"Mi o bẹru coronavirus nitori bi mi o ṣe mi o le e jẹ"- Ibrahim

Bi ọpọlọpọ awọn ọdọkunrin miran ti wọn ti rinrinajo kuro lawọn ipinlẹ miran lorilẹ-ede Naijiria wa si Abuja ni Ibrahim lati lee ri igbe aye to dara sii.

Lati ojule de ojule ni wọn n lọ lati rii pe imọtoto wa bi o tilẹ jẹ pe eyi naa ri bakan.

Ọkan ninu wọn, Sani ṣalaye pe nigba ti ofin igbele wa nilẹ, ọpọ ile ni wọn ko jẹ ki oun wọ mọ lati ko idọti wọn nitori ibẹru ajakalẹ arun coronavirus.

ọkan lara awọn oṣiṣẹ kolẹ-kodọti

Awọn oṣiṣẹ kolẹ-kodọti wa lara awọn to n foju wina lasiko ajakalẹ arun yii.

Olutunde Boroffice to jẹ Ọga agba ileeṣẹ Chanja Datti Ltd ati alakoso Waste Africa ṣalaye pe o ṣoro fun ijọba lati kan si awọn eeyan yii nitori pupọ wọn ni ko forukọ silẹ pẹlu ijọba.

O ni, koda, ko si si ẹni to mọ ibi ti wọn n da awọn idọti ohun eelo ilera ti wọn n ko si pẹlu.

Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù