WASSCE: Ìpínlẹ̀ Delta fòfin de olùkọ́ 41 tó ṣe màgòmágó nínú ìdánwò

Delta

Oríṣun àwòrán, Google

Ipinlẹ Delta ti fofin de awọn olukọ ile iwe girama mọkanlelogoji ti wọn ṣe magomago ninu idanwo aṣekagba ti wọn ṣẹṣẹ pari.

Komisọnna fun eto ẹkọ nipinlẹ Delta, Patrick Ukah lo fi lede bẹẹ ninu atẹjade ti wọn fi lede.

Ukah ni ajọ to n risi ọrọ idanwo, Examination Ethics Disciplinary Committee ni ipinlẹ naa ti bẹrẹ igbesẹ lati fi iya tọtọ jẹ awọn olukọ to wu iwa magomago.

Awọn olukọ yii ko ni gba igbẹga lẹnu iṣẹ fun ọdun kan, wọn si gbọdọ duro si ibi ti awọn ọmọ ti n ṣe idanwo fun ọdun mẹta.

Kọmisọnna naa ni awọn ti gbe igbesẹ lati ri wi pe eleyii wa si imuṣẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Aṣa: Ọ̀rọ̀ Ẹ̀yán ni Bunmi Femi Amao ń kọ́ wa lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lóri BBC Yoruba

Bakan naa ni ijọba gbe oriyin fun awọn to ṣe daadaa ninu idanwo naa,paapaa awọn olukọ ti ko fi aaye gba iwa magomago ni agbegbe wọn lasiko idanwo naa.

Christina Samuel

Oríṣun àwòrán, others

48 yr old woman wrote WAEC: Wo ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta tó ti pé ọdún 48 tó ń ṣe ìdánwò WAEC, kó le di nọ́ọ́sí

Ọjọ ti pẹ ti Arabinrin Christina Samuel ti ni erongba láti di nọọsi, sugbọn afojusun rẹ ko wa si ìmúṣẹ, nitori pe o yára lọ sile ọkọ.

O ti pe ẹni ọdun mejidinlaadọta bayii, to si jẹ pe iṣẹ́ oko lo n ṣe lati gbọ bukaata awọn ọmọ rẹ.

Nkan iyalẹnu to wa nibẹ ni pe o darapọ mọ àwọn to n ṣe idanwo WAEC lọwọ lọwọ lati ṣe idanwo, lati le mu afojusun rẹ ṣẹ.

Akọbi rẹ wa ni ipele keji ni fasiti to ti n kọ nipa imọ iṣegun oyinbo.

Lati bi ọdun kan ni Christina ti n fi owo pamọ, lati le fi orúkọ silẹ fun idanwo, lai wo bukaata awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta.

Gẹgẹ bi ọrọ awọn eléde Gẹẹsi to sọ pe "ẹni ti ko ba mura silẹ fun àṣeyọrí, n mura silẹ lati fìdírẹmi."

Ni ṣe ni Christina pa isẹ oko ti, ko le ri aaye gbajumọ iwe kika, ni imurasilẹ fun idanwo.

Àkọlé fídíò, Mistura Oseni Akintunde: Ara múmú kìí ṣe oríṣun ìfipábánilòpọ̀, ìran àwòjù ló ń fà á

Lọwọ-lọwọ, oun ati awọn ẹgbẹ́ ọmọ rẹ obinrin lo jọ n joko ṣe idanwo WAEC.

Ìbátan rẹ obinrin lo fi ọrọ naa sita lori Instagram, pẹlu aworan anti rẹ ninu aṣọ ileewe.

O fi kun ọrọ rẹ pe ẹru kọkọ n ba anti òun lati gbe igbesẹ, sugbọn o bori ẹru.

O ni nkan to daju ni pe "Christina yoo si di nọọsi, bose lẹni ọgọta ọdun, lẹyin ti awọn ọmọ rẹ ba ti pari ẹ̀kọ́ wọn, ti gbogbo àwọn yoo si le pese owo fun ẹ̀kọ́ rẹ".