Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!

Oríṣun àwòrán, @Oladapo
Agba ọjọ ninu onkọwe lede Yoruba kan tun ti ki aye pe o digbose!
Àjànàkú sùn bí òkè, erin wó kò le dìdi.Gbajúgbajà òǹkọ̀wé èdè Yorùbá, Lawuyi Ogunniran tí gbogbo àwọn olólùfẹ́ ìwé ìtàn Yorùbá mọ̀ sí Eégún Aláré ti dágbére fún ayé ní ẹnì ọdún márùnlélọ́gọ́rin.
Awọn ẹbi oloogbe ni Baba ko ṣaisan rara ki ọlọjọ to de.
Wọn ni koko ko ni ara ọta le, ati pe Baba Lawuyi ṣi ba ninu wọn sọrọ ni aarọ ana ki ọlọjọ to kan ilẹkun ni ọjọ kọkanlelogun, osu kẹsan an.
- Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn Adebayo Faleti, ìran Yorùbá ń ṣe ilédè rẹ!
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ìjọba Kaduna kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìdárò Emir Zazzau, Buhari, Tinubu, Babangida náà ń ṣèdárò
Ọpọ awọn onkọwe lo n ṣe idaro Baba Lawuyi Ogunniran ti ọpọ n pe ni Eegun Alare re ibi agba n re lẹni ọdun marunlelọgọrin.
Wọn ṣapejuwe baba ni Olufọkansin tootọ, Ọrẹ atata, Baba rere to huwa igbe aye atata to tun jẹ abinu funfun bi ẹmu
Lára àwọn ìwé tí olóògbé Lawuyi Ogunniran kọ nígbà ayé wọn ní wọ́nyí:
Àrẹ Àgó
Aríkúyẹrí
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú mi lẹ́rú ní 1837 - Ajayi Crowther
Awọn iwe miran ti Oloogbe Lawuyi Ogunniran tun kọ ni:
Ọmọ Alátẹ Ìlẹ̀kẹ̀
Níbo Láyé Dori kọ?

Oríṣun àwòrán, @Oladapo
Awọn iwe miran ti Lawuyi Ogunniran kọ ni:
Ìbàdàn Mesì Ọ̀gọ̀.
Atari ajanaku
Olọrun o mawada
Awọn ẹbi ni àwọn yoo kéde ètò ìsìnkú láìpẹ́.
Bẹẹ lawọn eeyan miran tun ki oriki iku pe o tun ti doro bi o se maa n daa: Ikú dóró ikú ṣìka pẹlu adura pe ki baba Sùn un re ó.
Ó tún dàrìnnàkòÓ tún dojú àláÓ tún di bẹ́ni jọ́niÓ tún di béèyàn jọ̀ọ̀yàn.Ó dìgbà o baba

Oríṣun àwòrán, @Ladapo
Àjànàkú sùn bí òkè, erin wó kò le dìde.
Gbajúgbajà òǹkọ̀wé èdè Yorùbá, Lawuyi Ogunniran tí gbogbo àwọn olólùfẹ́ ìwé ìtàn Yorùbá mọ̀ sí Eégún Aláré ti dágbére fún ayé.
Awọn miran ni Bónírèsé Lawuyi ò fíngbá mọ́ èyí tó ti fín ò lè parun. Sùn un re o, baba

Oríṣun àwòrán, @Ladapo
Àjànàkú sùn bí òkè,Erin ṣubú kò leè dìdeLáwuyì ònígègé àràSùn-ùn-re o!
Ki Olorun ko dẹlẹ fun agba ọjẹ onkọwe yii ni adura BBC Yoruba


















