Ọlọ́jọ́ Festival 2020: Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú

Olojo

Ọdọọdun ni ọdun Ọlọjọ maa n waye fun gbogbo ọmọ kaarọ, o jiire paapa awọn ọmọ Ile-Ifẹ ni ilẹ Yoruba.

Gẹgẹ bi iṣẹ lọdọọdun, Oba Ogunwusi ni yoo kọkọ side nipa wiwọ Ile-Odua ki o to wọ ade Aare lati jẹ ki ayẹyẹ naa bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Olojo

Lẹyin naa ni ayẹyẹ ti wọn n pe ni Gbajure yoo waye kaakiri awọn ojuko kan ni ilu Ifẹ, ti awọn araalu yoo si ma tẹle wọn kaakiri lati ṣe ajọyọ naa.

Bakan naa ni Oba Ogunwusi yoo gbalejo awọn to ẹlẹsin Ogun, Sango ati Osun ni aafin ọba pẹlu ayẹyẹ lorisirisi.

Ni Ọjọ Keje to jẹ kokaari eto, Ooni yoo gbalejo ọpọlọpọ awọn eniyan lati okeere ati kaakiri orilẹ-ede Naijiria ti wọn yoo wa lati wa ba wọn ṣe ayẹyẹ.

Olojo

Ni ọdun to kọja, aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari to peju si ibi ayẹyẹ aṣekagba naa rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ati gbogbo Adulawọ lagbaye lati ma ṣe gbagbe iṣẹṣe ati aṣa wọn.