Abiola Ebila: ''Operation Burst'' ti mú arákùnrin Eji olórí ''One Million Boys'' tó gba ipò Ebila

Aworan Ebila ati Ekugbemi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ebila

''Operation Burst'' ti mú Eji, tó gba ipò Ebila olórí ''One Million Boys'' ní ìpínlẹ̀ Oyo Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe pa Ebila, olórí àwọn "One million boys" n'Ibadan

Ọwọ awọn agbofinro to n ṣiṣẹ pọ nipinlẹ Oyo ti a mọ si 'Operation Burst' ti tẹ igbakeji Abiola Ebila, to jẹ olori ẹgbẹ okunkun ''One Million Boys'' to n da ipinlẹ Oyo ruBí ẹgbẹ́ One Million Boys ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé àti ọṣẹ́ tó ṣe n'Ibadan .

Ọga ajọ ''Operation Burst'' ajagun fẹyinti, Col. Oladipo Ajibola lo fidi ọrọ yii mulẹ Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú .

Laipẹ yii ni ajọ ọlọpaa ''Operation Burst'' yegi fun Ebila nibi to ti fẹ ji eeyan gba lati wa owo.

Lati igba ti Ebila ti fi iku ṣe ifa jẹ ni ''Eji'' ti gba ipo olori ninu ẹgbẹ okunkun ''One Million Boys.''

Eji tọ jẹ igbakeji Ebila naa ti wa ni gbaga awọn ọlọpaa bayii, yoo si foju ba ileẹjọ laipẹ.

Ọga ajọ ''Operation Burst'' ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ''One Million Boys'' ti fi ipinlẹ Oyo silẹ lọ sawọn ipinlẹ mii nitori awọn oṣiṣẹ eleto aabo ko foju wọn balẹ.

Awọn operation burst

Oríṣun àwòrán, others

O ni ajọ ''Operation Burst'' ti mu ọpọlọpọ ọmọ Yahoo, ẹlẹgbẹ okunkun atawọn ọdanran mii yatọ si Ebila to ti fi iku ṣe ifa jẹ.

Ajagun fẹyinti, Col. Ajibola sọ pe ọwọja ''Operation Burst'' ti de awọn agbegbe tawọn ẹlẹgbẹ okunkun ti n ṣọṣẹ bi Foko,Odo Oba,Olomi Olodo, ati ẹkun Oke-Ogun to fi mọ gbogbo Oyo ipinlẹ Oyo lapapọ.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Ko ṣai gboṣuba kare fun Gomina Seyi Makinde fun bi o ti n gbaruku ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati gbogun ti iwa ibajẹ nipinlẹ Oyo.

O rọ awọn obi lati mojuto awọn ọmọ wọn bi wọn ti n gbaradi lati wọle pada lọjọ Aje wi pe ki wọn ranti ọmọ ẹni wọn ọn ṣe.