Hanan Buhari wedding: 'Cartoon' tí Bulama yà nípa ìgbéyàwó ọmọ mi kò bójúmu tó - Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari
Iyawo Aarẹ Naijiria, Aisha Buhari ti sọ pe katun ti gbajugbaja ayaworan, Mustapha Bulama ya, eyii to ṣafihan igbeyawo ọmọ rẹ, Hanan Buhari ti awọn ọmọ Naijiria si n ri sinu odo ko bojumu to.
Agbẹnusọ iyawo Aarẹ, Aliyu Abdulahi lo fi ọrọ naa to BBC leti.
O ni awọn ọmọ olori ilu lẹtọ lati ṣe igbeyawo ni asiko to yẹ, ko si ni nnkan ṣe pẹlu boya awọn eeyan ilu fẹran ijọba awọn obi wọn tabi bẹẹ kọ.
Aliyu ṣalaye pe "Katun ti Mustapha Bulama ya ko bojumu rara nitori igbeyawo ọhun kii ṣe ọna aibikita fun awọn ara ilu, idi eyii lo mu ki aya Aarẹ ṣe ipade pẹlu awọn alabaṣiṣẹ rẹ pe oun ko fẹ igbeyawo alariwo ṣaaju ọjọ igbeyawo naa."
O tẹsiwaju pe "Aworan ti aya Aarẹ fi lede lori ayelujara kii ṣe lati fi yọ suti ete si awọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn o jẹ ọna lati fi ẹmi imoore han si awọn to ba idile rẹ ṣajọyọ igbeyawo ọhun."

Oríṣun àwòrán, @Bulamacartoons
"Igbeyawo ọmọ Aarẹ Buhari jẹ ọkan gboogi lara awọn igbeyawo onirẹlẹ julọ ti awọn to n tukọ ijọba yoo ṣe ninu itan orilẹ-ede Naijiria."
Ni ti fidio kan to n tan kalẹ lori ayelujara, nibi ti tọkọ-taya ti n jo ti awọn eeyan kan si n na wọn lowo, Aliyu ni kii ṣe ile ijọba ni Abuja ni wọn ti ya fidio ọhun, ṣugbọn iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti iyawo dele ọkọ rẹ tan ni Kaduna.
Aliyu ni iyawo Aisha Buhari mọ pe arun Covid-19 ṣi wa lawujọ, nitori naa lo ṣe ri daju pe gbogbo awọn to peju sibi igbeyawo ọmọ rẹ tẹle ilana ijinasiraẹni ti awọn eleto ilera gbe kalẹ.
Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni igbeyawo Hanan, to jẹ ọmọ Muhammadu Buhari waye, eyii to jẹ akoko ti ọpọ ọmọ Naijiria n sunkun inira ati ebi nitori bi ounjẹ, ina ijọba ati epo bẹntori ṣe gbowolori.
Onwoye ohun to n lọ lawujọ kan to n fi ilu Kano ṣebugbe, Sani Musa sọ fun BBC pe, ni ṣe lo yẹ ki idile Aarẹ sun ọjọ igbeyawo naa siwaju nitori bi ọrọ aje Naijiria ṣe ri lasiko yii.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Olólùfẹ́ míì tó ń dọ́fun tòló láti fẹ́ ọmọ ààrẹ tún yọjú síta

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Bashir
Ọrọ ifẹ, bii adanwo ni, bẹẹ si ni oro ọfa ifẹ ju oro ibọn lọ fun ẹni to ba ni iriri rẹ.
Boya eyi lo mu ki ọkunrin kan, Abdullahi Bashir fi n fi ẹsẹ tọ igboro ilu Abuja kiri, lati se alabapade, Hanan, ọmọbinrin aarẹ Muhammadu Buhari.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Abamẹta ni ọmọ aarẹ naa se igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tinubu, yé é sọ̀rọ̀ abẹ́lẹ̀, bọ́ sí gbangba láti bèèrè àtúntò Nàíjíríà lọ́dọ̀ Buhari - Afẹnifẹrẹ
- Wo àànfàní ‘Masturbation’, fífún ara rẹ̀ ní adùn ìbálòpọ̀
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
- Àwòráń ọdún Ashura àwọn ẹlẹ́sìn Shiite tí ọ̀pọ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lórí ayélujára
- Risikat olójú búlù dí aya Wasiu ní ìlànà Islam, tẹbí tará péjú síbẹ̀
- Ó ń bọ̀ lọ́nà! Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Jenifa ṣi aṣọ lójú àwọn fíìmù tuntun tẹ́ẹ ti ń retí
- Ìdí ti mo fi da sọ́ọ̀sì rú lásìkò ìgbéyàwó ìyáwó mi tó ló fẹ́ ọkọ míran- Osadebe
Amọ oniruuru awọn ọkunrin lo ti jade sita lati kede ifẹ ti wọn ni si Hanan, ni kete ti wọn gbọ pe o fẹ se igbeyawo,to si wu wọn lati fi se aya wọn.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Koda, ọkan lara wọn ni Abba Ahmed, ẹni to kede pe oun setan lati pa ara oun ti ọmọ aarẹ ba fi se igbeyawo lẹyin oun.
Ọpẹlọpẹ ileesẹ ọlọpaa to parọwa si ọkunrin naa, ti ko fi se bo se wi.
Nibayii, Abdullahi Bashir, ẹni ọdun mejilelogun to tun ti yọju sita lori itakun agbaye, to si ni aise alabapade ọmọ aarẹ nilu Abuja lati fẹ, da irẹwẹsi si oun lara.
Amọ Bashir, tii se ẹlomiran to tun sẹsẹ kede ifẹ rẹ si Hanan loju opo itakun agbaye, ni to ba jẹ pe ọmọ aarẹ fẹ oun ni, maalu aadọjọ ni oun ko ba fi san owo ori rẹ.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Sugbọn ọkunrin naa, ni kete to gbọ pe oloruka ti gba oruka, ti Hanan si ti lọ sile ọkọ rẹ, lo ba gba fun Ọlọrun.
Bashir, tii se darandaran nipinlẹ Adamawa lo kede pe oun ti yofẹ pẹlu ọmọ aarẹ ati awọn aworan fọto to n ya.
O ni to ba see se ni, obinrin naa lo wu oun lati fi se aya.
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá dènà ọkùnrin tó fẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí ọmọbìnrin Buhari

Oríṣun àwòrán, Aishabuhari
Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kano ni oun ti pẹtu sinu arakunrin kan, Abba Ahmed, to ni oun yoo pa ara oun ti ọmọ aarẹ Buhari, Hanan ko ba fẹ oun.
Ahmed ti fi lede bayii pe oun ti jawọ ninu ero bẹẹ, nitori o ti han gbangba pe iru ero bẹẹ ko dara rara, ati wi pe ko fihan pe oun fẹran Hanan.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abdullahi Haruna ni awọn fi iwe pe Ahmed , ti wọn si ba sọrọ iyanju lori ẹrọ ayeluyara ko to di wi pe o jawo ninu ero lati pa ara rẹ.
Ahmed ni oun yi ẹrọ oun pada lori ati pa ara oun nitori ọmọ Buhari nitori ero naa ko dara rara, oun ko si ni ṣe iru rẹ mọ.
- Ayẹyẹ igbeyawo melo ni Aarẹ Buhari lọ?
- Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!
- Toyin Abraham pé 40, wo ohun márùn ún tó mú dá yàtọ̀ láàrín ogójì ọdún
- Facebook mú àyípadà bá àtẹ̀jíṣẹ́ síra ẹni lórí òpó Instagram, wo àwọn ǹkan tó kàn ọ níbẹ̀
- Bí mo bá wọlé padà, mí ò lè yàn Ize Iyamu tàbí Osagiobare sípò olùbádámọ́ràn- Obaseki

Oríṣun àwòrán, Aishabuhari
Amọ, ni Ọjọ Eti opin ọṣẹ yii ni Hanan Buhari ṣe igbeyawo pẹlu Turad Shaban.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Inu ile Aarẹ Buhari ati Aisha Buhari ni Abuja ni ayẹyẹ igbeyawo naa ti waye, ti iyawo aarẹ Buhari si fi si oju opo Instagram rẹ wi pe oun dupẹ lọwọ Olọrun pe o yọri si rere.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Hanan kọ ẹkọ imọ gẹgẹ bi ayaworan ni fasiti Ravensbourne ni Ilẹ Gẹẹsi, nigba ti ọkọ rẹ jẹ oluranlọwọ pataki si minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Baba Turad Sha'aban jẹ aṣofin tẹlẹri ni Ile Igbimọ Aṣofin to ṣoju ẹkun Zaria ni ọdun 2003 si 2007.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
- Owó oúnjẹ ni mo lọ ọ gbà, oyún ọmọ tí mo jù sí àkìtàn ni mó gbé wálé- Dupe, ìyá Muiz
- Ènìyàn 156 míràn ló tún kó Coronavirus ní Nàìjíríà ní ọjọ́ Ẹtì
- Olórin Kano tí wọ́n dájọ́ ikú fún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
- Nàìjíríà làwọn ní ìfẹ́ sí ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Russia ṣe
- Wo ọ̀nà ìsanwó tuntun fún àwọn oníbárà iná mọ̀nàmọ́ná ní Eko (EKDC)
- Àwọn dókítà yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódí lọ́jọ́ Ajé
















