Health workers Strike: Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lábẹ́ àsìá JOHESU fagilé ìyanṣẹ́lódì káàkiri Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ oṣiṣẹ eleto ilẹra lapapọ labẹ ẹgbẹ JOHESU ti kesi awọn oṣiṣẹ wọn lati pada si ẹnu iṣẹ.
Ọjọ meje ṣẹyin ni wọn gunlẹ iyanṣelodi lati pe akiyesi ijọba si awọn ohun to jẹ ẹdun kan fun wọn.
Amọ nibayii, awọn adari ẹgbẹ JOHESU naa ti wa paṣẹ fun wọn lati pada si ẹnu iṣẹ kaakiri orilẹede Niajiria.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Wo àwọn báńkì tó wà lẹ́yìn àwọn olówó èlé bí MMM
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
JOHESU ni awọn gbegile iyanṣẹlodi naa bi o tilẹ jẹpe ijọba apapọ ko i tii dahun si ibeere wọn.
Ohun ti wọn n bere fun ni ki ijọba san owo oṣu ti wọn jẹ wọn, ki wọn si san owo ajẹmọnu ti ijamba ba ṣẹlẹ si oṣiṣẹ ilera lẹnu iṣẹ.
Amọ, titi di wakati yii ijọba apapọ ko dahun si ibeere wọn, ki wọn to gunlẹ iyanṣẹlodi lati kilo fun ijọba.
- Ìjọba Kaduna kéde ọjọ́ mẹ́ta fún ìdárò Emir Zazzau, Buhari, Tinubu, Babangida náà ń ṣèdárò
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Sudan tí bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò lórí bí US yóò ṣe yọ òrúkọ̀ wọn kúrò nínù ikọ̀ agbẹ́sùnmọ̀mí àgbáyé
- Áṣẹyin kìlọ̀ fáwọn adarí olóṣèlú Nàìjíríà láti ṣe ohun tó yẹ nítorí ará ọ̀run ń wò wọ́n!
Nibayii, ẹgbẹ JOHESU ni awọn ọmọ ẹgbẹ yoo ṣe ipade lati ri wi pe awọn wa wọrọkọ fi sada lori igbesẹ ijọba yii, eleyii ti ko dun mọ wọn ninu.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ eleto ilera marun un lo wa labẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ JOHESU.
Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2020 ni awọn oṣiṣẹ ilera naa gunle iyanṣẹlodi, ki wọn to ṣẹṣẹ pada si ẹnu iṣẹ bayii.
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera, JOHESU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì káàkiri Nàìjíríà
Egberin ọtẹ lọrọ iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorilẹede Naijiria yii o.
Lẹyin ọjọ mẹta pere ti ẹgbẹ awọn dokita da iyanṣẹlodi ti wọn gunle duro, ẹgbẹ gbogbo oṣiṣẹ eleto ilera ni Naijiria, Joint Health Sector Unions, JOHESU naa ti kede iyanṣẹlodi kaakiri orilẹede Naijiria.
Ẹgbẹ JOHESU paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ eleto ilera da iṣẹ silẹ laago mejila oru ọjọ Aiku ọjọ kẹtala oṣu kẹsan an ọdun 2020.
- Ẹ̀yin tó ń tajà lẹ́gbẹ́ẹ títì, ẹ̀ wá 'bi gbà kọ́jọ́ méje tó pé! - Ìjọba Oyo
- Ọkọ mi kò fẹ́ràn oúnjẹ òyìnbó àfi ti ìbílẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Iléẹjọ́ gíga Akure kọ̀ láti gba onídùróó olórí ìjọ Sotitobire
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó ní òun ló jí ọmọ gbé láti parọ́ mọ́ pásítọ̀ ìjọ Sotitobire
- Ó mà ṣe o! Gold Kolawole, ọmọ tó sọnù ní ṣọ́ọ́ṣì Sotitobire kò bá pé ọdún méjì lónìí
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ JOHESU kede iyanṣẹlodi ọhun ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.
Awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ti kọkọ ṣepade pọ pẹlu ijọba apapọ lọjọ Ẹti lori erongba rẹ lati gunle iyanṣẹlodi.
Ẹgbẹ JOHESU sọ ninu atẹjade naa pe iyanṣẹlodi ọhun yoo tẹsiwaju nitori ijọba ko ṣetan lati ṣe ohun tawọn n fẹ fawọn oṣiṣẹ eleto ilera.
Ẹgbẹ naa ti kọkọ fun ijọba ni ọjọ mẹẹdogun pe awọn yoo gunle iynaṣẹlodi ki wọn to bẹrẹ lọjọ Aiku.
Lara ohun ti wọn n beere lọwọ ijọba atunṣe owo idojutofo fu itọja coronavirus, sisan owo oṣu ti ijọba n jẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera to fi mọ owo oṣu wọn kẹrin ati ẹkarun un ọdun 2018 to wa nilẹ.
Amọ aiṣetan ijọba lati ṣe gbogbo nnkan yii lo mu wọn pada gunle iyanṣẹlodi lọjọ Aiku.
Àwọn dókítà Nàìjíríà ti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn
Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria ti da iyanṣẹlodi ti wọn gunle duro fun saa diẹ.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Aliyu Sokunbo sọ fu awọn akọroyin pe ẹgbẹ ọhun ti gunle idunadura miran pẹlu ijọba apapọ lori awọn ohun ti wọn n bere fun.
O ni lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu ijọba apapọ ni wọn pinnu lati da iyanṣẹlodi ọhu duro fun oṣe meji lati wo ibi ti ọrọ awọn ati ijọba yoo yuọri si.
Ṣaaju ni ijọba apapọ ti sọ oun ti fi biliọnu mẹsan an din diẹ naira kun owo ajẹmọnu owo Covid-19 wọn, eyii to jẹ wọn fun oṣu kẹfa ọdun 2020.
- A ti gba àwọn òṣìṣẹ́ 15,000 làti ṣètò ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ Ondo lóṣù kẹwàá - INEC
- Àìsí iṣẹ́ nígboro lọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi fẹ́ gba iṣẹ́ Amotekun - Toogun
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Gbèsè Nàìjíríà ti lé ní 18 tírílíọ́ọ́nù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari- DMO
- Wo bí iṣẹ́ abẹ wákàtí mẹ́fà, tí wọ́n fi dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ tẹ̀, ṣe lọ
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Mínísítà ní kò bójúmu fáwọn dókítà láti woṣẹ́ níran lásìkò àrùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba apapọ ti paṣẹ fun awọn dokita agba nile iwosan rẹ gbogbo, pe ki wọn fi awọn agunbanirọ to jẹ dokita rọpo awọn dokita to n yanṣẹ lodi.
Ijọba apapọ paṣẹ pe ki wọn fi awọn dokita agunbanirọ to n sinru ilu lọwọ, rọpo awọn dokita iṣegun to n yanṣẹ lodi lawọn ileewosan to jẹ ti ijọba apapọ naa.
Ijọba ni oun n gbe igbesẹ naa ki iṣẹ ipese ilera ati itọju awọn alaisan ma baa dawọ duro nibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Afenifere fara ya lórí bí Tinubu ṣe jókòó kí Ooni
- Háà ilẹ̀ wẹ! ọ̀dọ́ 47,000 fẹ́ di Amotekun, agbófinró yẹ̀ wọ́n wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́
- Aáwọ̀ oyè PDP gbé Fayose àti Seyi Makinde kọlu ara wọn, ìjà ń bọ̀
- Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà
- Bàbálọ́jà márùn ún la ó ò ní l'Oyo tí Makinde bá lè buwọ́lu ìyànsípò YK Abass
- Ìjọba, e yé dẹ́yẹ sí wa mọ́, àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ṣèwọ́de n'Ibadan
- Auxiliary gbé èèyàn mẹ́fà tó ń jáwèé ayédèrú fáwọn awakọ̀ lọ sí ilèẹjọ́ ní Ibadan
Minisita feto ilera, Dokita Osagie Ehanire lo pa aṣẹ yii lọjọru nilu Abuja lasiko to n sọrọ lori iyanṣẹlodi awọn dokita nile iwosan ijọba, NARD.

Oríṣun àwòrán, others
Iyansẹlodi naa n waye lori sisan owo ajẹmọnu fun ewu ti wọn la kọja lasiko ajakalẹ arun COVID-19 atawọn ẹdun miran.
Minisita Ehanire ni "ko si aniani pe, ojuṣe awọn dokita ati gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni lati doola ẹmi.
Ko si yẹ ko jẹ pe awọn dokita bẹẹ lo wa n da iṣẹ silẹ niru asiko bayii ti Naijiria n ba ajakalẹ arun finra."
O ni iru asiko yii lo yẹ ki gbogbo oṣiṣẹ lẹka eto ilera parapọ, wa koju ọta ọmọniyan yii, nitori naa, ohun to ku diẹ ka a to ni idaṣẹsilẹ naa.
O fi kun un pe, bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ti mojuto ibeere yii, ti ijiroro lori awọn yooku si ti de ipele to lapẹẹrẹ, suuru ni awọn dokita naa ko ba fi yanju ọrọ naa.
"Ohun to ṣe pataki fun ijọba ni lati wa awọn ọna gbogbo to ba yẹ, lati fi rii daju pe irora iyanṣẹlodi naa ko pọ lapọju fun araalu.
Idi niyi ti ijọba fi paṣẹ pe, ki awọn dokita agba lawọn ile iwosan ijọba apapọ maa lo dokita agunbanirọ, lati maa tọ awọn to n gba itọju pajawiri lọdọ wọn.
O wa ke s'awọn dokita ti n woṣẹ niran naa lati pada si ẹnu iṣẹ wọn, ki wọn lee tẹnpẹlẹ mọ ijiroro wọn to n lọ lọwọ pẹlu ijọba apapọ, lori awọn ibeere wọn naa.
Iná míràn tún fẹ́ ràn lẹ́ka ilera Nàìjíríà
A n jekuru ọrọ l'agboeto ilera lorilẹede Naijiria ko tan lawo, ṣe ni wọn tun n gbọn ọwọ rẹ sinu awo.
Lẹyin ti awọn dokita bẹrẹ iyanṣẹlodi wọn lọjọ Aje, ti ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria si ti n pariwo, awọn oṣiṣẹ eto ilera yoku naa ti gbe ikilọ sita pe awọn pẹlu yoo gunle iyanselodi bẹrẹ bi ijọba apapọ ba kuna lati sise lori ẹdun wọn.
Ninu ọrọ to ba awon akọroyin sọ nilu Abuja, agbarijọpọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹka eto ilera lorilẹede Naijiria salaye pe ijoba ti n mu awon lọbọ lori ijiroro won.
- Ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn NUJ ìpínlẹ Oyo bà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó lọ ìpàdé tí Femi Fani Kayode pè ní Ibadan wí
- Àrà mánigbàgbé tí Baba Legba dá lágbo tíátà rèé
- Àwọn ọ̀daràn tó jí ìbejì ọmọ Akeugbagold kó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lòníì
- Àjọ ECOWAS yan Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo gẹgẹ bíi aàrẹ tuntun
- Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi
Ninu ọrọ to sọ lorukọ awọn ẹgbẹ naa, alaga apapọ, JOHESU, Bio Josiahrọ minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ, Festus Keyamọ SAN lati kewaju ijiroro naa dipi Chris Ngige to n ṣe kokaari rẹ tẹlẹ
Lara awon ẹdun ọkan awọn oṣiṣẹ naa ni sisan aṣẹku owo ajẹmọnu oo asiko ajakalẹ arun COVID-19 fun awọn oṣiṣẹ naa ni ileewosan ijoba apapọ eleyii ti wọn ni o jẹ ida mẹwaa dipo ida ọgọta ninu ọgọrun ti o jẹ adehun ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ati ijoba.
Bakan naa lo ke s'awọn ijobaipinlẹ ati ibilẹ ti wọn ko tii bẹrẹ si nii ṣe iṣẹ lori sisan owo ajẹmonu asiko ajakalẹ arun COVID-19 lati bẹrẹ si nii san an lẹyẹ o ṣọka.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Àwọn Dókítà Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìyànṣẹlódí lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ̀ yẹ àdéhùn rẹ̀ pẹ̀lú wọn

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria ti bẹrẹ iyanṣẹlodi loni ọjọ aje.
Ẹgbẹ naa ni igbesẹ yii ko ṣẹyin bi ijọba apapọ ko ṣe mu adehun ṣẹ lori awọn ohun ti wọn jọ fẹnuko le lori.
National Association of Resident Doctors (NARD) ṣalaye pe lati osu kẹfa ni wọn ti ṣepade pẹlu ijọba apapọ lori igbesẹ yii.
O to ida ogoji dokita Naijiria to wa ninu ẹgbẹ yii ti wọn n beere fun ẹkunwo owo oṣu, itọju to peye lẹnu iṣẹ, atunṣe to yẹ si awọn ile iwosan Naijiria paapaa lasiko Coronavirus yii
Aarẹ ẹgbẹ yii, Dokita Aliyu Sokomba sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn dokita to n tọju alaisan coronavirus naa yoo darapọ mọ wọn lasiko yii laiyọ ẹnikẹni silẹ
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Nítorí aìsan owó àjẹmọ́nú, àwọn dókítà yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódí lọ́jọ́ Ajé

Oríṣun àwòrán, others
Ẹgbẹ awọn dokita nileeẹkọṣẹ iṣegun gbogbo lorilẹede Naijiria, NARD ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọgbọọrọ bẹrẹ lati ọjọ Aje, ọjọ keje oṣu kẹsan ọdun 2020.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita lẹyin ipade igbimọ iṣakoso rẹ lo ti kede yii.
Wọn ni lai jẹ pe ijọba gbe igbesẹ lori awọn ẹdun ọkan wọn ti wọn gbe ka iwaju ijọba awọn yoo tẹsiwaju lori igbesẹ naa.
- Ọ̀la òde yìí ni ìrìnàjò sí ilẹ̀ òkèèrè yóò padà bẹrẹ ní Nàìjíríà
- Èèmọ̀! Ọmọbìnrin ọdún 25 gún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa nítorí ó ní ko lọ ṣẹ́ oyún
- Èèyàn 125 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- A kú oríire! Oró agbọ́n leè wo àìsàn jẹjẹrẹ ọmú sàn, wo ohun tí wàá lò pọ̀ mọ́ra wọn
- Daniel Prude: Ìbòjú tí àwọn ọlọ́pàá New York fi bo ọkunrin ọhun ló ṣe ikú pà á
Lara awọn ohun to fa ẹhonu naa ni sisan owoona fun eto dokita abẹnu nileeṣẹ ẹkọṣẹ iṣegun Residency funding, owo gba ma binu fun ajakalẹ arun COVID-19, sisan owo ewu ẹnu iṣẹ (hazard allowance) pẹlu owo ajẹẹlẹ owo osu ọdun 2014, 2015 ati 2016.
Awọn dokita naa ti kọkọ lọ fun iyanṣẹlodi onikilọ ọlọjọ mẹkanlelogun lati fi fa ijọba leti ṣugbọn ti ko si ọrọ kankan latọdọ ijọba titi di bi a ṣe n sọrọ yii.
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
- Ọmọ Nàìjíríà kan gbé Fásitì Oxford lọ sílé ẹjọ́ tàko oríkí ọrọ 'Mortgage' nínú ìwé àtúmọ̀ ọrọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn olè tó kó góòlù àti ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ nílé MKO Abiola l'Eko
- Ó sàn kí ẹ pa mí ju kí ẹ ba oko tí mo gbin igbó sí jẹ́ lọ- Afurasi Clement sí NDLEA
- Mo ṣetán láti fi ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún Anthony Joshua- Efe Ajagba
- Ara ló ń ta àwọn ẹgbẹ́ NURTW tó ń pariwo mi kiri, APC ni wọ́n bá lọ nígbà náà l'Oyo- Auxiliary

Oríṣun àwòrán, others

















