Èèmọ̀! Ọmọbìnrin ọdún 25 gún ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa nítorí ó ní ko lọ ṣẹ́ oyún

Onyinye Chime

Oríṣun àwòrán, Other

Esio! Kinni ọrọ ifẹ ti wa da bayii?

Ọmọbinrin ọdun mẹẹdọgbọn kan ni iroyin sọ pe o gun ọrẹkunrin rẹ pa lẹyin ti o sọ fun un pe ki o lọ ṣẹ oyun to wa ninu rẹ.

Onyinye Chime tako ọrẹkunrin rẹ Eleyi Azubuike wi pe ko si ohun to jọọ bẹẹ ki ọrọ to bẹyin yọ.

Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni Nkpor, lẹba ilu Onitsha, ni ijọba ibilẹ Idemili ipinlẹ Anambra lapa ila oorun orilẹede Naijiria.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iroyin to tẹ awọn lọwọ sọ pe ninu yara ni Oyinye ti gun Azubuike ọrẹkunrin pa.

Ohun ti a gbọ ni pe Azubuike to jẹ ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn kọ lati fun Onyinye lowo lati ṣẹ oyun inu rẹ ati fun itọju ara rẹ lo fa aawọ laarin wọn.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Ẹnikan to mọ nipa ọrọ naa sọ fawọn akọroyin pe lootọọ ni Onyinye fi ẹjọ Azubuike sun awọn kan, amọ ko si ẹni to mọ pe o le gun ọrẹkunrin rẹ lọbẹ.

IIeeṣẹ ọlọpaa awọn agbofinro gbiyanju lati gbe Azubuike lọ si ile iwosan amọ ọwọ ti bọ sori ki wọn to de ibẹ.

Àkọlé fídíò, Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe apa oju ọbẹ wa lara oku Azubuike, ati pe wọn ri ọbẹ gba nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii si n lọ lọwọ lori lori ati mọ wulẹwulẹ iṣẹlẹ naa.