Edo election 2020: Ọlọ́pàá méjì kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole, APC ní kìí ṣe ojú lásán

Oríṣun àwòrán, others
Ori ko alaga ana lẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole yọ lọjọ Iṣẹgun, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn ọẹọpaa meji ti wọn jẹ ẹṣọ rẹ.
Oshiomhole lo lewaju ikọ ipolongo ibo Pasitọ Osagie Ize-Iyamu gẹgẹ bi gomino ipinlẹ naa lọ si Usen nigba ti ọkọ akẹru kan ya lọ kọlu awọn ọkọ to n ba a kọwọrin lọ sibi ipolongo naa lagbegbe Oluku Junction ni ijọba ibilẹ ila oorun Ariwa ipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Adams Oshiomhole fi sita ṣalaye pe ni nnkan bii agogo mejila ọsan ni iṣẹlẹ naa ṣẹ.
Ọkọ tirela naa kọlu ọkan lara awọn ọkọ Toyota Hilux to n ba a kọwọrin lọ silu Usen nibi ti oun ati Pasitọ Ize-Iyamu to jẹ oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC yoo ti ba awọn araalu naa sọrọ lori idi ti wọn fi gbọdọ di ibo wọn fun APC.
Meji ninu awọn ọlọpaa to wa ninu ọkọ naa jade laye ti awọn miran si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ileewosan.
Awọn ikọ rẹ ti sọ pe, igbagbọ awọn ni pe ọgbọn lati gbẹmi Adams Oshiomhole ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ko tii jade pẹlu iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa.
Nibayii igbimọ olupolongo idibo APC ni ipinlẹ Edo ni awọn ti fi eto ipolongo rọ naa lati yẹ awọn to ku ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa sii.
- Máa gbé kẹ̀kẹ́ rẹ lọ, àwọn akọròyìn kọ̀ ìpàkọ́ sí Femi Fani Kayọde
- Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Ọkùnrin kan da ṣọ́ọ̀ṣì rú lásìkò ìgbéyàwó, Ó ní òun lọkọ àárọ̀ ìyàwó tuntun
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ìwọ tó ń ṣí ara sílẹ̀ lọ ṣọ́ọ̀ṣì, ṣé apàyàn kọ́ ni ẹ́ báyìí?- Mike Bamiloye











