Komla Dumor: Victoria Rubadir ọmọ Kenya ló gba àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor BBC World News

Victoria Rubadiri to jẹ akọroyin ati aṣewadi abẹlẹ to tun jẹ olootu eto lori ẹrọ amohunmaworan lo gba ami ẹyẹ Komla Dumor BBC World News ọdun 2020.
Olootu eto ile ișẹ mohunmaworan Citizen ni Kenya ni Rubadiri ti o si ti ma a n ṣe atọkun eto to gbajumọ julọ nile iṣẹ naa.
O jẹ akọroyin to n ṣe oniruuru nkan pọ ni iha ilaoorun ilẹ Afirika ti o si ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ọpọ awọn gbajugbaja oloselu ati awọn ilumọọka miran ni Kenya.
Ile iṣẹ BBC ṣe agbekalẹ ifoye yẹnisi ami ẹyẹ Komla Dumor lati buyi fun atọkun ile iṣẹ BBC World News to sa dede ku lọdun 2014 lẹni ọdun mọkanlelogoji.
Rubadiri ni ẹni kẹẹfa to gba ami ẹyẹ Komla Dumor ni ilẹ Africa, oun lo tẹle Solomon Serwanjja, Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure ati Nancy Kacungira.
Oun ni enikeji ti yoo gba ami ẹyẹ naa ni orileede Kenya.
" Komla jẹ oniroyin to moye to si mohun ohun to n ṣe, botilẹ jẹ pe apaṣẹ waa ni, sibẹ o jẹ alaanu, ati ẹni to maa n ru ọmọlakeji soke.
Rubadiri yoo bẹrẹ irin ajo olosu mẹta pẹlu BBC ti yoo si lọ gba ẹkọ imọ ni BBC Academy ko to darapọ mọ awon oṣiṣẹ BBC News eka ti amohunmaworan, Radio ati tori ayelujara, eyi yoo fun lanfani lati fi imọ kun imọ jakejado ẹka BBC News
" O ni imọ, o si le fọ awọn ootọ ọrọ si wẹwẹ, bakan naa ni awọn ero iworan yoo maa fọkan baa lọ. O jẹ enikan ti mo nifẹ si pupọ, ti mo si fẹ dabi tirẹ" ọrọ Rubadiri ree.
"Inu mi dun pe n o ni awọn imọ ni BBC kun eyi ti mo ni tẹlẹ, eyi yoo si ran mi lọwọ lati le fikun lukun pẹlu awọn ero iworan mi labẹlě ni ẹkun ati jakejado agbaye nibikibi ti mo ba ti n ṣe iṣẹ mi"
Bi ẹnu rẹ se da șaṣa jẹ nkan to wu awọn onidajọ eto igbaniwọle naa lori, ati nipa bi o ṣ n sọ itan ilẹ Adulawọ labẹle ati ni gbangba, to fi mọ ori ayelujara.
Inu wa dun lati gba Victoria gẹgẹ bi ọkan lara wa lati gbe ifaraji rẹ wọ ile iṣẹ BBC gẹgẹ bi Jamie Angus to jẹ adari BBC World Group ṣe sọ.
"Komla Dumor ni agbara lati sọ itan jakejado agbaye ki o si fi nkan to pa aye pọ ati oye olukuluku gbee kalẹ.
A n reti Victoria lati mun iwoye rẹ naa wa si oju taye o fi kun.
















