Natalia Mufutau ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Àkọlé fídíò, Natalia Mufuta ìyá Yakub, Kamil àti Adam sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ń sọ èdè mẹ́rin pàpọ

Ede Yoruba, Gẹeṣi, Polish ati Finnish ni awon ọmọ mẹtẹẹta n kọ- Adewumi Waliu Mufutau.

Ọpọ àwọn ọmọ Yoruba to wa ni Naijiria ni awọn ọmọ wọn ko gbọ ede Yoruba daadaa ni eyi to ti n kọ awọn onwoye ede lominu lasiko yii.

Ṣugbọn inu BBC Yoruba dun lati ṣawari Adewumi Waliu Mufutau ti o jẹ ọmọ bibi ilu Ṣaki ni ipinlẹ Oyo ṣugbọn to fi orilẹ-ede Finland ṣe ibujoko rẹ to si n kọ awọn ọmọ rẹ ni ede Yoruba.

Natalia Mufutau to jẹ iya awọn ọmọ yii wa lati orilẹ-ede Poland.

O si ṣalaye pe ede mẹrin ni awọn Adam, Kamil ati Yakub ẹgbọn wón le sọ daadaa, iyẹn Yoruba, ede Oyinbo, Polish ati Finish to jẹ ede Finland ti wón n gbe.

O tun sọ nipa pataki ki ọmọ ni idanimọ ninu aye ki o le kọ iwa ọmọluwabi bi o ṣe yẹ.

Natalie wa gba awọn obi Yoruba ni imọran lati dide si iṣẹ iya ni pataki lati kọ ọmọ wọn ni aṣa ati iṣe bii ibówọfagba ti o jẹ Yoruba logun ninu iwa ọmọluwabi.

O sọrọ nipa ibaṣepọ to wa laarin oun ati awọn ẹbi Mufutau ni Saki ni eyi ti o dara pupọ.