Kow your Ovulation date: Wo bí o ṣe le ṣe ònkà àsìkò tí o bá n yé ẹyin tó ṣeéṣe fún ẹ láti lóyún

inu obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọpọlọpọ ìgbà, aini òye nipa bi ara obinrin ṣe ri, to fi mọ asiko ti ara obinrin ba n gbé fun iloyun tabi ye ẹyin (ovulation), lo maa n fa airọmọbi fun tọkọtaya.

Ko fẹ ẹ si ẹni ti ko mọ nkan oṣu obinrin (menstruation).

Sugbọn, diẹ lo mọ rírì asiko ti obinrin ba n ye ẹyin, eyi to maa n waye ni ọjọ mẹrinla ṣaaju ki nkan oṣu to o bẹrẹ.

Tokotaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Asiko yii ni ẹyin ọmọ n jade ninu ara obinrin lati inu ẹ̀yà ara ti a n pe ni ovary.

Ẹyin naa yoo lọ sinu ọ̀pá kan ti wọn n pe ni fallopian tube.

Inu ọ̀pá yii ni àtọ̀ (sperm) ọkunrin, yoo ti da pọ mọ ọ lati ṣọ ọ di oyun, ti ibalopọ ba waye.

Gẹgẹ bi awọn onimọ nipa ọrọ oyun níní ati ọmọ bíbí ṣe sọ, asiko 'ovulation' lo daju julọ fun obinrin lati lóyún.

Dokita Joseph Akinde, salaye pe ti tọkọtaya ba ni ibalopọ ni ọjọ kan tabi meji ṣaaju 'ovulation', obìnrin naa yoo loyun.

Sugbọn, bi asiko ti obinrin kọọkan n ṣe nkan oṣu ṣe yatọ, naa ni asiko ti wọn n ye ẹyin yatọ.

Àkọlé fídíò, Mr Macaroni sọ nípa eré tí Fraky freaky, Sugar Daddy, You are doing well, freaky spicy fẹ́

Dokita Akinde ṣalaye pe to ba jẹ pe ọjọ mẹrindinlọgbọn ni apapọ ọjọ to ma n wa ni aarin nkan oṣu rẹ meji, wo àpẹẹrẹ yii.

"Ka ni pe o bẹrẹ nkan oṣu rẹ ni ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020, ti òmíràn tun bẹrẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, eyi tumọ si pe ọjọ kẹẹdogun lo yẹ ki o ye ẹyin."

"Fun obinrin to ba jẹ pe ọjọ mejidinlọgbọn ni ti ẹ, ọjọ mẹrinla ṣaaju nkan oṣu miran ni yoo ye ẹyin."

O fi kun ọrọ rẹ pe, ọjọ mejilelọgbọn lo ma n wa laarin nkan oṣu meji, fun awọn obinrin kan. Eyi si tumọ si pe ọjọ kejidinlogun rẹ̀ ni wọn o ma a ye ẹyin.

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Bawo ni ẹyin ṣe n de ara obinrin?

Ni ibẹrẹ pẹpẹ, ẹyin ọmọ bi i miliọnu meji ni wọn maa n bi mọ ọmọbinrin kọọkan.

To ba ti bàlágà, ẹyin naa yoo ma a jade diẹdiẹ l'oṣooṣu, gẹgẹ bi ẹjẹ nkan oṣu, iyẹn ti ko ba ni ibalopọ pẹlu ọkùnrin.

Àpẹẹrẹ pe o n ye ẹyin ni eyi jẹ.

Gẹgẹ bi Dokita Akinde ṣe sọ, awọn obinrin kan yoo ri ẹjẹ bintin, inu rírun tabi dídùn laarin isẹju diẹ si wakati mẹrinlelogun. Àmọ́, ko ni i ju wakati mẹrinlelogun lọ.

Obinrin kan ti ẹ sọ pe ọmú oun maa n tobi si i lasiko ti oun ba n ye ẹyin.

Ohun kan to daju ni pe àpẹẹrẹ ti obinrin kọọkan yoo ri yatọ si ara wọn.

Eyin obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọna ti o fi le ṣe onka tabi ìṣirò asiko ti o n ye ẹyin:

Dokita sọ pe o le lo àwọn ọna bi i :

1. Kikọ akọsilẹ tabi lo onka ọjọ (calendar) fun nkan oṣu rẹ

[ a] Ya iwe kan sọtọ fun akọsilẹ yii

[b ] Ni gbogbo igba ti o ba ri nkan oṣu rẹ, kọ déètì ọjọ akọkọ silẹ tabi fa ìlà si lori kalẹnda.

[ c] Kọ déètì ọjọ to ba pari silẹ bakanna.

[d ] Iye ọjọ to ba wa laarin ọjọ akọkọ nkan oṣu kan àti ọjọ akọkọ omiran ni kalẹnda rẹ (menstrual cycle)

[e ] Ọjọ kẹrinla ni ọjọ ti wa a ye ẹyin saba ma n jẹ lai fi iye ọjọ to wa lori kalẹnda nkan oṣu rẹ ṣe.

Àkọlé fídíò, jkkkkk

2. Lilo odiwọn bi ara ṣe gbona tabi tutu si:

Odiwọn yii gbọdọ waye lasiko ti ara wa ni ìsinmi.

Dokita Akinde sọ pe obinrin le fi ẹrọ tamomita si abẹ ahọn rẹ nigba to ba ṣẹṣẹ jí, ko to o fi ori ibusun rẹ silẹ.

To ba n se eyi ni gbogbo igba, yoo sakiyesi pe o lọ silẹ ju bi o ṣe yẹ lọ ni ọjọ kan, ko tun to o gbera pada. Ọjọ naa ni o ye ẹyin.

Àkọlé fídíò, Risikat Moromoke Azeez: Inú èmí àti Òbí mi dùn nígbà ti Risi bí ọmọ olójú búlù- Wasiu

3. Lilo irin'ṣẹ ayẹwo 'ovulation'

Àwọn irin'ṣẹ kan wà lati fi ṣe ayẹwo ati onka ọjọ ti eroja leutinizing hormone (LH), ba pọ si lara obinrin.

Eroja yii lo ma n ran ile ẹyin lọwọ lati ṣíṣe daadaa. O si ma n lọ soke laarin wakati mejila si mẹrindinlogoji ṣaaju ọjọ ti obinrin kọọkan yoo ye ẹyin.

Onimọ miran nipa iloyun ati ìbímọ obinrin, Dokita Olusegun Akeredolu sọ pe o le lo ìtọ̀ tabi itọ́ rẹ lati ṣe ayẹwo yii.

Dokita Akinde sọ pe "Ti o ba ri ìlà meji loju irin'ṣẹ naa, o tumọ si pe o ti ye ẹyin.

4. Ikun tabi nkan to n jade ni oju ara obinrin

Oriṣiriṣi nkan lo maa n jade ni oju ara obinrin laarin ibẹrẹ nkan oṣu kan si omiran.

Gẹgẹ bi itakun ayelujara eto ilera Medical NewsToday ṣe sọ, ibẹrẹ kalẹnda obìnrin ni nkan oṣu to saba ma n waye fun ọjọ márùn-ún.

Ẹ̀jẹ̀ si lo saaba maa n jẹ.

Ọjọ kárùn-ún si ikẹwa lẹyin nkan oṣu, nkankan kii saba jade tabi ko jẹ bintin. Nkan to ba jade naa yoo lẹ mọ ọ lọwọ ti o ba fi ọwọ kan an. Obìnrin ko le loyun lasiko yii.

Ọjọ kẹwàá si ọjọ kẹrinla ni ibẹrẹ yiye ẹyin; nkan ti yoo jáde yoo tun yatọ. Bẹẹ si ni eroja to n mu ki ara obinrin gbé fun ibalopọ, estrogen, yoo pọ si.

Ni ọjọ ti ọjọ kẹrinla gan-an-gan ti wa a ye ẹyin, nkan ti yoo jade ni oju ara rẹ ko ni i ki, yoo da bi omi, yoo si ma a fà ti o ba fi ọwọ kan. Eyi tumọ si pe o n ye ẹyin.

Laarin ọjọ kẹrinla si ọjọ kejilelogun, eroja progesterone yoo pọ si lara obinrin. Eyi yoo si mu ki ikun to n jade ni oju ara obinrin ko gbẹ.

Ko ni i pọ ni asiko naa.

Bi nkan oṣu rẹ ba ti n sunmọ ọjọ ti yoo bẹrẹ, nkan ti yoo jáde ni oju ara yoo ki, yoo si ma a lẹ mọ ọwọ. O si tun ṣe e ṣe ki nkan o ma jade ni ọjọ kan tabi meji ṣaaju nkan oṣu.

Sugbọn o, Dokita Akeredolu sọ pe aisan ibà, àárẹ ara tabi aarun oju ara le ṣe idiwọ fun ṣíṣe onka yiye ẹyin.

Idi ti ṣíṣe onka bi o ṣe n ye ẹyin ṣe jẹ pataki

Títọ pinpin asiko ti obinrin n ye ẹyin yoo ran tọkọtaya lọwọ lati ni òye kikun nipa asiko ti oyun le de, ki wọn o le ṣe eto ibalopọ wọn si asiko naa.

Àkọlé fídíò, Painter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!

Dokita Akinde sọ pe eyi wulo pupọ fun awọn obinrin ti ọkọ wọn ko si ni itòsí tabi to ni iyawo pupọ.

"Sugbọn fun tọkọtaya ti ọrọ wọn ko ri bayii, wọn le ma a ni ibalopọ, o kere tan, ẹẹmẹta ni ọsẹ, lai pa ọjọ ti obinrin n ye ẹyin jẹ, to ba jẹ pe wọn n wa oyun."

Àkọlé fídíò, Florida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

Yatọ si eyi, o tun le wulo fun ifeto si ọmọ bibi fun tọkọtaya ti ko fẹ ẹ loyun, nipa yiyago fun ibalopọ lasiko ti ara obinrin ba gbé fun oyun níní.

Tokotaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ipari, ṣíṣe ìṣirò bi obinrin ṣe n ye ẹyin yoo ran an lọwọ lati mọ pato ọjọ ti nkan oṣu rẹ to n bọ yoo bẹrẹ. Eyi yoo jẹ ki o mura silẹ fun.