Peers of Heaven: Ààrẹ ẹgbẹ́ Emèrè ní àwọn ti wà tipẹ́, wọn kò pariwo síta ni

Oríṣun àwòrán, Others
"Ẹgbẹ Emere ti wa tipẹ, a ko kan pariwo sita ni, paapa laarin awọn oniṣẹ'ṣe."
Eyi nikan ti Oloye Oyelola Elebubon sọ fun BBC Yoruba lori ajọdun ẹgbẹ naa to waye laipẹ yii.
O ni "Ẹgbẹ yii bẹrẹ lati ara pe awa ti a jẹ ọmọ ẹgbẹ ma n ba ara wa pade ni ode tabi ariya. Ṣugbọn ẹru ma n ba wa lati sọ pe nkan bayii ni a jẹ. A si ma n pe ara wa ni ẹgbẹ ooṣa."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Wo oríṣìí ìlù Yorùbá, ìwúlò wọn àti ba ṣe ń lò wọ́n
- Oyedepo àti ìjọba ń tahùn síra lórí bí ìjọba ṣe ń gba àkóso àwọn ilé ìjọsìn
- EFCC tún gbé Mompha lórí ẹ̀ṣùn lílu jìbìtì lórí ayélujára
- Ọlọ́pàá méjì wọ gàù lóri bí afurasí apanìyàn l‘Akinyele ṣe sá lọ
- Ìrìnna ọkọ́ òfúrufú s'ílẹ̀ òkèèrè bẹ̀rẹ̀ padà ní Nàìjíríà
- Jegede (PDP) ti yan Aṣojúṣòfin Ikengboju gẹ́gẹ́ bí ìgbákejì rẹ̀ tí wọ́n yóò jọ díje dupò
O ni ọdun mejila sẹyin ni oun gba imisi lọdọ awọn ẹgbẹ pe ki oun ma a polongo nipa awọn ẹlẹgbẹ ọrun.
O ṣe pataki ki awọn eeyan mọ pe "a o ki n ṣe ọmọ buruku. Awa naa le ṣe daada."

Oríṣun àwòrán, others
Elebuibon ni Ọjọbọ ni awọn ma n ṣe ipade ni aago mejila ọsan si lawọn ma n bẹrẹ ipade
"Nibi ipade naa, a ma n gba awọn adura to gbona gidigidi. Awọn eeyan ma n mu ẹbẹ adura wa fun awọn ẹbi wọn. Adura naa ma n gba, wọn n jẹri."
A ma n da ara wa mọ laarin eero. Nkan ti a fi ma n ki ara wa ni pe " Elére ọmọ! Ẹnikeji yoo si dahun pe, "Onitẹsiwaju".
Ṣugbọn ilẹkẹ ọwọ la fi ma n da ẹni to ba ni ooṣa ẹgbẹ sile. A o ki ẹni naa pe "A kii ka o! Oun naa yoo dahun pe "Aṣẹẹjẹ o. " A o si jọ sọ papọ pe "bọlọhun fẹ, oju o ni wa a ti".

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ ẹgbẹ Emere ni ko dara bi awọn ile ijọsin ṣe ma n fi igbalẹ na awọn elere ọmọ lati le wọn kuro ninu ẹgbẹ.
O ni awọn fẹ ki araye mọ pe ki wọn mase ya ẹgbẹ mọ. O ni ti wọn ba ṣe bẹ ẹ, wọn n le ire, ayọ ati ibukun jinna si ọmọ naa ni.
Wo ìyàtọ̀ ńlá tó wà láàrin Oṣó, Àjẹ́ àti Emèrè

Lati ọjọ pipẹ ni ọrọ oṣo, ajẹ ati emere ti ma n jẹyọ ni aarin awọn ọmọ Yoruba, ati kaakiri ilẹ adulawọ.
Awọn elede Gẹẹsi si maa n pe wọn ni witches and wizards.
Ṣugbọn, o ṣeeṣe ki ọpọ eeyan ma mọ iyatọ to wa laarin awọn ẹgbẹ mẹtẹẹta.
- Bàbà ìyàwó ló yẹ kí ọkùnrin dọ̀bálẹ̀ fún, kìí ṣe ìyàwò tó fẹ́ fẹ́ - Yemi Elebuibon
- Ènìyàn lásán ní ọba ilẹ̀ Yoruba tí kò bá ṣe ètùtù, ẹ má tẹ ìṣẹ̀ṣe mọ́lẹ̀ - Elebuibon
- Ọ̀nà tó fi le è mọ gbájúẹ̀ babaláwo - Ẹlẹ́buìbọn
- 'Ìbọn dún láàfin Ọ̀ọ̀ni ilé ifẹ̀ lóòtọ́, ṣùgbọ́n kò séwù'
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Àwòrán àwòdamiẹnu rèé lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Osogbo
- Ẹsẹ̀ kò gbèrò ní ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo
BBC Yoruba ba Araba ilu Oṣogbo to tun jẹ onimọ nipa aṣa ati ẹsin adayeba nilẹ Yoruba, Oloye Yẹmi Ẹlẹbuibọn, sọrọ lati jẹ ka mọ iyatọ laarin awọn eeyan mẹtẹẹta naa.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni iyatọ wa laarin oṣo, ajẹ, ati emere.
Iyatọ laarin Emere, Ajẹ ati Oṣo:
- Awọn ti a n pe ni ajẹ, ni awọn ni ìyà mi, lati ipilẹ aye ni Olodumare ti da wọn. Wọn jẹ ọkan lara awọn ẹmi airi, ti a n pe ni Ajogbo - awọn ẹmi airi to ma n yọ da eeyan laamu
- Kii ṣe gbogbo ajẹ lo ma n ṣe buruku, tako bi awọn eeyan ṣe ma n bẹru ti wọn ba gbọ nipa ajẹ
- Ajẹ wa fun rere ati buburu
- Obinrin lo ma n jẹ ajẹ, ọkunrin ni oṣo.
Awọn nkan to ma n fa ati ajẹ fi ma n yọ eeyan lẹnu
Ni ibẹrẹ pẹpẹ, ọmọ eniyan lo dalẹ, eyi to mu ki awọn ajẹ binu.
Adehun ti awọn ajẹ ṣe nigba ti wọn n bọ si aye ni pe, gbogbo eeyan yoo ma a gbe pọ ni alaafia, ṣugbọn, ọmọ eeyan lo kọkọ yẹ adehun.
Awọn ọmọ eeyan ma n lẹ oko mọ ọmọ ẹyẹ, wọn ma n pa wọn.
Eyi lo mu wọn fi ẹjọ sun Olodumare.
Éníyán la n pe awọn ìyà mi, ènìyàn ni a n pe ọmọ ènìyàn.
Bi wọn ṣe fi ẹjọ sun yii, mu ki Olodumare ni oun yoo ran ikọ kan lati wo nkan to n ṣẹlẹ.
Awọn ọmọ eniyan mọ pe awọn ti ṣe nkan ti ko tọ ọ, eyi to mu wọn lọ ke ba awọn ti yoo gba wọn silẹ.
Wọn de ọdọ babalawo kan ti orukọ rẹ n jẹ Abẹ. Oun lo si gba wọn ni imọran lati mu adiyẹ meji to jẹ kan naa wa a.
O la adiyẹ naa si meji, wọn si ki ẹnu wọn bọ ara wọn.
Wọn gbe sinu awo amọ, wọn si lọ gbe si bebe odo.
Ninu irinajo iranṣẹ olodumare, àpèrè ayọrunbọ ni yoo gun wa si aye, eyi to dabi ẹlikọpita laye ode oni.
Bibalẹ ti àpèrè rẹ balẹ sile aye, bebe odo ti awọn ọmọ eeyan gbe ẹbọ si lo balẹ si i.
Riri to ri ẹyẹ meji ti wọn gbe sibẹ - to ti ku, to ki ẹnu bọ ara wọn l'ẹnu, pẹlu iyẹ wọn to fọn kaakiri ilẹ, o ro ninu ara rẹ pe, a jẹ pe ẹyẹ lo n ba ara wọn ja.
Abọ yii lo jẹ fun Olodumare, pe awọn ẹlẹyẹ naa lo n pa ara wọn.
Eyi mu ki awọn ọmọ eniyan tun ma a ba iwa ọdalẹ wọn lọ.
Ni awọn ìyà mi naa ba tun pada si ọdọ Olodurmare lati fi ẹjọ sun. Olodumare sọ fun wọn pe ọtọ ni iroyin ti ikọ oun mu wa.
Lo ba fun wọn ni imọran pe ki awọn naa o ma a na ẹni to ba le wọn, bu ẹni to ba bu wọn, pa ẹni to ba pa wọn.
Bi awọn ìyà mi gba aṣẹ niyi, ti wọn si bẹrẹ si i da ọmọ eeyan laamu - ori ffiọ, inu rirun, iṣẹ ti ko lọ deede, wọn n mu ẹjẹ wọn, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Nigba ti ara ni awọn ọmọ eeyan, wọn lọ ọ fi ẹjọ sun olodumare, ṣugbọn o sọ fun wọn pe ko si nkan ti oun le ṣe si, nitori awọn lo kọkọ dalẹ, to yẹ adehun.
Ṣugbọn Olodumare kọ wọn ni ọgbọn pe, etutu ati ẹbọ riru ni ọna abayọ - lilo iyọnu tabi ẹbẹ awọn ajẹ.
Idi niyii ti ọmọ eeyan fi ma n ṣe iyọnu awọn ajẹ, ki wọn o ma ba a da wọn laamu mọ.
Odu ifa to ba jade ni yoo sọ nkan ti yoo wa ninu ẹbọ ajẹ. O le jẹ okete, akika, awọn nnkan inu ẹran bi ifun, ati ẹdọ, o si le jẹ ẹyin adiyẹ.
Ọna wo ni eeyan fi n di ajẹ?
Oloye Ẹlẹbuibọn sọ pe ọrọ naa dabi orin Yoruba kan to sọ pe "iya lo jẹ iya agba, to ko owo lọ ọ ra ajẹ."
O sọ pe ẹlomiran ma n ti itori pe oun fẹ ẹ gba ẹsan, ko lọ ọ gba ajẹ. Iya ma n fun ọmọ rẹ ni ajẹ, ẹlomii si wa to yẹ pe lati ọrun lo ti gba ajẹ.
Awọn wo ni Emere?
- Orukọ miran fun emere ni Abiku - iyẹn awọn ọmọ ti ori wọn ko gbó, ti ẹmi wọn ko gùn.
- Elemere ni wọn ma n pe wọn, ko si si ẹni to ma n fẹ ẹ sọ sita pe emere ni ọmọ ti oun bi.
- Iru awọn ọmọ yii ti ma n ni adehun pẹlu awọn ẹgbẹ wọn l'ode ọrun nipa asiko ti wọn fẹ ẹ fi aye silẹ.
- Amọ, ojuṣe awọn obi ni lati du ẹmi awọn ọmọ naa. Ifa lo si le sọ itumọ bi awọn obi yoo ṣe ba adehun tabi ipin awọn naa jẹ.
- Oriṣiriṣi ni wọn, awọn to dara wa lara wọn, awọn to jẹ idakeji naa si wa. Awọn ọmọ naa si lo ma n sọ bi wọn ṣe fẹ ẹ rin irinajo aye wọn.
- Awọn obi kii mọ iru ọmọ ti wọn bi, wiwo ẹsẹntaye ọmọ tabi difa lo ma n jẹ ki wọn o mọ.
- To ba ti to asiko ti wọn da, oriṣiriṣi ọna ni awọn ẹgbẹ wọn ma n gba yọju si wọn, ti wọn o si ma a sọ fun wọn pe "asiko ti to, ma a bọ".
- Obi ti ko ba mọ iru awọn ilana bayii, lati so ẹmi wọn rọ, wahala nla ni wọn ma n koju.
Yatọ si ti ajẹ, ọrun ni wọn ti ma n ya emere, wọn kii fun yan. Idi si niyii ti ifa fi ṣaba ma n sọ pe ki iru wsn o fẹ babalawo gẹgẹ bi ọkọ, fun amojuto.
"Ifa ni olugbala wọn, nitori ẹ si ni wọn ti ma n pe ifa ni Ọdundun, ti i du ori elemere".
Tọkunrin-tobinrin lo ma n jẹ emere, ṣugbọn obinrin lo pọju ninu wọn.
'Àwa Emèrè Onítẹ̀síwájú la ṣèpàdé nílé Elebuibon, kìí ṣe Oṣó àti Àjẹ́'

Oríṣun àwòrán, others
Alaye ni ẹkunrẹrẹ ti n waye lori ipade kan to waye laipẹ yii nile Oloye Ifayemi Elebuibọn ninu eyi ti wọn ni awọn Oso ati Ajẹ peju si.
Bẹẹ ba gbagbe, irọlẹ ọjọ Ẹti la kọkọ mu iroyin wa fun yin pe awọn Oso ati Ajẹ naa se ipade nilu Osogbo nile baba Awo, Elebuibon.
Sugbọn alaye miran to yọju sita lọjọ Aiku lo sisọ loju rẹ pe, ẹgbẹ awọn Emere onitẹsiwaju lo se ipade, kii se ẹgbẹ awọn Oṣo ati Ajẹ, gẹgẹ bi iroyin ti gbe sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nǹkan wọ̀lú! Afurasí ikú ọ̀wọọ̀wọ́ l'Akinyele jápa mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́
- Wo ọmọ Nàíjíríà tí wọn fi pósí ‘₦34m’ sin
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Ẹ fura, iyọ̀ onímájèlé tó dóde ti gbẹ̀mí èèyàn méje!
- Ta bá yá owó lókèèrè kò láìfí, ìpèsè ohun amáyédẹrùn là ń ṣe – Lai Mohammed
- Ìtàn ayé Alájọ Ṣómólú rèé, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
- Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ Donald Trump, àbúrò rẹ̀ Robert, dèrò ọrun
Ninu alaye rẹ fun BBC Yoruba, alakoso ẹgbẹ awọn Emere Onitẹsiwaju lọrun, ti wọn pe ni Progressive 'Peers of Heaven' Society, Oloye Oyelola aya Elebuibon ni iroyin to ni awọn ajẹ lo se ipade ko ri bẹẹ.
O ni " Awa Emere kii se Ajẹ abi Oṣo amọ ẹlẹgbẹ ọrun ni wa."
Aya Elebuibon fikun pe, lootọ ni awọn se ipade ajọdun akọkọ nile Araba awo nilu Osogbo, nibi ti Baba Awo Ifayemi Elebuibon to bawọn sọ ọrọ apilẹkọ.
Gẹgẹ bi Oloye aya Elebuibon ti wi, ẹgbẹ Emere Onitẹsiwaju ti n sisẹ kara lati se amulo awọn abuda rere to wa ninu ọmọ ẹgbẹ kọọkan fun isẹ rere.

Oríṣun àwòrán, others
O fikun pe awọn abuda rere naa ni wọn yoo lo fun idagbasoke awujọ wa ati orilẹede Naijiria lapapọ.
Agbára Oṣó àti Àjẹ́ yóò mú àgbéga bá ìmọ̀ ẹ̀rọ Nàíjíríà - Elebuibon
Gbajugbaja onimọ nipa iṣegun ibilẹ nilẹ Yoruba, to tun jẹ Araba nipinlẹ Oṣun, Ifayemi Elebuibon, ti gba ipade nla ajọdun ayẹyẹ apapọ ẹgbẹ awọn oṣo ati ajẹ.
Nibi ipade yii ni onimọ iṣegun ibilẹ naa ti fi ọrọ lede pe, itajẹsilẹ lewu pupọ fun idagbasoke orilẹ-ede yii.
Nigba to n ba ipejọpọ naa sọrọ lọjọbọ, eyi to jẹ akọkọ iru ayẹyẹ bẹẹ ti ẹgbẹ itẹsiwaju awọn ajẹ ati oṣo ipinlẹ Oṣun yoo se, Elebuibọn rọ ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi ṣada, lori ipaniyan to n waye lorilẹede Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìdẹra dé fún Nàíjíríà! Sani Abacha tún gbé owó míì dé láti Ireland
- Ibùdó ìyàsọ́tọ̀ ni mo wà, ló fi pẹ́ kí ń tó sọ̀rọ̀ lórí tírélà tó já l‘Eko - Omotola Jalade Ekeinde
- Ire ṣ'ọjọ́-ìbí, Mide àti ọkọ rẹ̀ lẹ̀pọ̀, Iyabo Ojo f'aṣọ ilẹ̀ Afirika dárà
- Funke Akindele fún mi lówó tí mo fi gba ilé, kò ra ilé fún mi o - Ajirebi
- Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC mií Lanre Razak jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́
- Ìpànìyàn tún wáyé ní Akinyele, àwọn ará àdúgbò ṣe ìwọ́de
O ni ki wọn ṣe eyi ki ibinu Ọlọrun to sọkalẹ sori orilẹede yii.
Gẹgẹ bi baba onifa yii ṣe sọ ọ, wọn gbudọ tọwọ iwa ipaniyan lemọ lemọ to n waye ni iha Ariwa orilẹ-ede yii bọlẹ.
Bakan naa lo ni iwa ipaniyan lati fi eeyan ṣoogun owo ni iha Guusu Naijiria gbọdọ dopin, ki abamọ ma ba a gbẹyin rẹ.
O tun gba awọn onimọ iṣegun ibilẹ nimọran lati mọ daadaa nipa ẹsin wọn, ki wọn ma si faaye gba ọrọ ti ko ba ba ohun ti wọn n ṣe mu.
Elebuibon tun rọ wọn ki wọn wa ni iduro deede ati ṣiṣe ododo pẹlu awọn eeyan lati jẹ eeyan ire lawujọ.

O ni gbogbo ẹda alaaye lo ni ẹgbẹ ọrun kan tabi omiran ti wọn n ṣe, o si tẹnu mọ ọ pe, mimọ ẹgbẹ ẹni daadaa ati ṣiṣe ifẹ inu wọn, maa n ran irinajo ẹda laye lọwọ.
"Iye itajẹsilẹ ati ifiniṣẹṣo owo ni Naijiria n kọ ni lominu.
Ki ijọba ni gboogbo ipele mu opin wa si eyi, ki Eleduwa to rọjo ibinu rẹ le orilẹede lori.
Mo rọ ẹyin ajẹ ati oṣo ki ẹ maa gbe igbe aye ododo, eyi ti wọn mọ awọn oniṣegun ibilẹ fun, ki ẹ si jẹ ki ẹsin awọn baba nla baba wa ṣe atunṣe ọna yin pada tori ohun nikan lo lee daabo bo iru eeyan ti ẹ jẹ lagbaye".

Oríṣun àwòrán, others
Ninu ọrọ rẹ, Oloye Arabinrin Oyelola Elebuibon sọ wi pe pataki ipade naa ni lati fihan gbogbo agbaye pe, jijẹ oṣo tabi ajẹ kii ṣe nkan ibi, gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin kan ṣe n wo o.
O ni bi wọn ba lo awọn agbara to wa ninu rẹ daadaa, o lee mu ayipada rere ba imọ ẹrọ orilẹ-ede kan, ko si tun gba ogo wọn pada fun idagbasoke.
O wa parọwa lapapọ pe ki ijọba Naijiria mojuto eto aabo awọn ara ilu lasiko yii nitori bi ọrọ ṣe n lọ yii ko dara to.
Lafikun, o rọ awọn ọmọ ẹgbẹ Oso ati Ajẹ lati ni ifarajin ninu ilu pẹlu bi ohun gbogbo ṣe le to.
O ni rinrin deede ati ṣiṣe ododo ni ko jẹ koko ọrọ wọn ni gbogbo igba.

















