Osun Osogbo: Àwọn èèbó aláwọ̀ funfun gbé Ọ̀ṣun lárugẹ

Ilu Oṣogbo sọkutu wọwọ loni pẹlu obitibiti ero lasiko asekagba ọdun Ọṣun Oṣogbo to waye loni.
Lati nkan bi aago mẹfa idaji ni awọn ara ilu ati orisirisi awọn onilu ti korajọ siwaju aafin Ataọja tilu Oṣogbo, lati se ajọyọ ọdun Ọṣun Oṣogbo ti ọdun yii.
Ọpọlọpọ awọn eniyan jankan-jankan lo wa lati orisirisi ipinlẹ ni orilẹede yii ati ni awọn orilẹede miran lagbaye, lati kopa ninu ọdun naa, eyi ti ko yọ awọn oyinbo alawọ funfun sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ní Khafi BB Naija yóò pàdánu tí iṣẹ́ ba bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀?
- Wo àwọn oúnjẹ tí àṣẹ Buhari leè mú kó gbówó lórí
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- "Ẹ̀yin obìnrin, ẹ lọ kọ́ iṣẹ́ káfíńtà torí ó lówó lórí ju iṣẹ́ aránṣọ lọ"
- Àwọn ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Ọyọ nìkan ni yóò rí iṣẹ́ àgbàṣe gbà lábẹ́ ìjọba mi - Seyi Makinde
Lara awọn wọ ki ilu mọ ni ilẹ Yoruba to wa nibi ayẹyẹ ọdun Ọsun Osogbo ti ọdun yii ni, Aare Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Aare Gani Adams, Oloye Nikẹ Davies Okundaye, ti gbogbo eeyan mọ̀ si Nikky Afrikana ati awọn lọba lọba nilẹ Yoruba.

Arugba Osun Osogbo jade ni deede aago mẹwa ku ogun isẹju aarọ, ti ọgọọrọ awọn eniyan siwaju rẹ pẹlu ijo ati ayọ, ti wọn si n se adura ti wọn kigbe "Ore yeye ooooooo."
Bi awọn onilu gangan ati bata se n lu ilu lọ niwaju arugba naa, ni awọn agbofinro n sọ ọ loju lẹsẹ, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni sunmọ ọdọ rẹ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ikọ BBC Yoruba, ọkan lara awọn ontaja to wa nibi ọdun naa saroye pe aje ko bu igba jẹ lọdun yii, nitori pe witiwiti pọ lọdun to kọja ju ti ọdun yi lọ.
Lara awọn isẹlẹ arimaleelọ to waye nibi ọdun naa ni, asọ alaranbara ati asọ funfun ti awọn olujọsin Ọsun wọ, awọn alageere lọkunrin lobirin tiwọn n fi ijo da awọn eniyan laraya ati ọpọlọpọ awọn ọdọmọkunrin ti wọn mu pankẹrẹ lọwọ ti wọn si n na ara wọn.

Ninu ile iya Osun ni ati fi oju ganni ọpọlọpọ eniyan ti wọn n se adura, lara awọn oloye ilu ti o wa ninu ile naa wi pe ile mimọ ni ile iya Osun jẹ, ati wi pe wọn kii wọ bata wọ ibẹ.
Awọn lẹgbẹlẹgbẹ-loyeloye ati ọkanọjọkan ẹlẹgbẹjẹgbẹ lawujọ ti n ṣe ikini fun Kabiyesi Ataọja ti ilu Ọṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji, ti Kabiyesi naa si n wure fun wọn.













