CBN Policy: Buhari pàṣẹ fún báńkì àpapọ́ láti dẹ́kun owó ìrànwọ́ fáwọn tó ń gbé oúnjẹ wọ Nàìjíríà

Ọlọja kan ni idi igba rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ ni aṣẹ naa yoo ran eto ọgbin labẹle lọwọ

Ni ọjọ iṣẹgun ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari kede si eti awọn gomina to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pe, oun ti paṣẹ fun banki apapọ ilẹ wa, lati yee se akanse pasi paarọ owo Naira ilẹ wa si tilẹ okeere fun awọn to ba fẹ ko ounjẹ wọ orilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi aarẹ ṣe sọ, igbesẹ yii yoo dena bi kiko ounjẹ wọle lati ilẹ okeere ṣe n ṣakoba fun idagbasoke eto ọgbin labẹle.

Ṣe ẹ si mọ wi pe ko si bi a ba ṣe fa gburu, ti gburu ko ni fa igbo, eyi lo mu ka ṣe ayẹwo awọn ounjẹ ti a n ko wọ orilẹede Naijiria lati oke okun atawọn to ṣeeṣe ko gbowo lori nitori igbesẹ yii.

Eyi ni awọn ohun jijẹ ti a n ko wọ orilẹede Naijiria lati ilẹ okeere gẹgẹ bii ajọ iṣọkan agbaye fun ọdun 2019 ti gbe kalẹ: