Torí Portable, aṣọ kanṣoṣo ni mò ń wọ̀ kiri fún ọjọ́ mẹ́ta – Stelliza

Portable ati Stelliza

“Ọlọrun a fun ẹyin naa ni ọmọ ologo. Kii ṣe ọmọ ologo ti wọn maa yẹyẹ rẹ o, ọmọ ologo “with grace” ni Ọlọhun a fun un yin”.

Gẹgẹ bo ṣe wà níinú fídíò míì táa rí lórí ayélujára, arabinrin to jọ pe oun ni oluranlọwọ pataki fun gbajugbaja olorin nni, Habeeb Okikiola (Portable), arabinrin Stelliza sọ pe nnkan ti oju oun ri lasiko ti ọlọpaa gbe Portable titi di igba ti o farahan nile ẹjọ kii ṣe kekere rara.

Eyi jẹ jade ninu ọrọ ti oun ati ọga rẹ Portable n sọ ninu ọkọ nigba ti wọn n gbe e lọle lẹyin ti wọn san gbogbo beeli ti ile ẹjọ beere fun.

“A dupẹ gidi lọwọ gbogbo ẹyin tẹẹ kan si wa, ẹyin tẹẹ pe mi lori foonu, ẹ ma binu pe mi o le gbe ipe yin.

Ẹ ṣaa ti ri bi mo ṣe ri... ti mi o fi le gbe foonu yin”

Eyi ni ọrọ Stelliza ti Portable naa si n daa lohun pe lootọ ni oju rẹ ko tilẹ dan mọ fun ọjọ mẹta ti awọn fi wọ wahala yẹn o si ṣeleri fun un pe oun yoo fun ni owo ko fi “bizza”.

“Ko sibi too ti le blow, too ba wa ninu iho ilẹ gan waa lowo, ẹ ṣeun o gbogbo ẹyin ololufẹ mi”.

Ẹwẹ, Portable ni aanu ni oun ri gba oun si mọ ọ loore.

O gbadura pe Ọlọrun a fun awọn ololufẹ rẹ naa ni ọmọ ologo. “Kii ṣe ọmọ ologo ti wọn maa yẹyẹ rẹ o, ọmọ ologo “with grace” ni Ọlọhun a fun un yin”.

Portable gba ìtúsílẹ̀ ní àhámọ́ ìjọba, ohun tó sọ nígbà tó jáde rèé

Portable

Oríṣun àwòrán, @portablebaeby

Habeeb Okikiola Portable ti gba itusilẹ ni ahamọ ijọba lẹyin ti ile ẹjọ ni ki wọn fun ni beeli laarọ ọjọ Aje.

Iroyin ni ki adajọ to gbọ ẹsun ti wọn fi kan an to pari iṣẹ lọjọ Aje ni olorin naa ti ṣe ohun gbogbo ti wọn ni ko ṣe ko to le maa lọ sile.

Bo tilẹ jẹ pe ọkọ ọgba ẹwọn Ilaro ni wọn fi gbe kuro nile ẹjọ ṣaaju, ko sun ọgba ẹwọn naa mọju.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muyiwa Adejobi sọ fun awọn akọroyin pe gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Portable ni wọn le gba beeli rẹ niwọn igba to ba ni awọn ohun amuyẹ ti wọn bere lọwọ rẹ, o le maa lọ sile.

Ninu fidio kan to ṣe lẹyin to kuro ni ahammọ tan lo ti sọ pe ẹkọ gidi ni oun kọ lara iṣẹlẹ to sọ ohun dero ile ẹjọ.

O ni “Mo ti kọ ekọ gidi latari iṣẹlẹ yii.”

Lẹyin naa lo fi ẹmi imoore han si awọn ololufẹ rẹ fun atilẹyin wọn ṣaaju ati lasiko igbẹjọ ọhun.

Ilé ẹjọ́ gba béèlì Portable pẹ̀lú pípèsè Onídúró méjì, N500K, N300K àmọ́ ...

Portable

Ki lo de ti Portable ṣe pẹ ko to jade kuro nile ẹjọ?

Ọpọlọpọ eeyan lo duro titi lati igba ti igbẹjọ gbajugbaja olorin ti ẹnu kii ṣi lori rẹ, Habeeb Okikiola ti pari amọ ti ko jade kuro nile ẹjọ.

Awọn eeyan ti n woye pe ki lo le tun maa da a duro nigba ti wọn ti sun igbẹjọ ọhun siwaju amọ ti ohun ati awọn agbẹjọro ṣi wa ninu ile ẹjọ.

Ẹwẹ, awọn agbẹjọro Portable ni awọn n gbiyanju titi lati wa ojutuu si awọn beeli ti ile ẹjọ fun un ko ma baa lọ si atimọle amọ aridaju boya wọn ri i yanju, boya yoo lọ si atimọle abi yoo lọ si ile ko tii ye.

Akọroyin wa jabọ pe gẹgẹ bi agbẹjọro fun Portable ṣe sọ ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo, o jẹ ko di mimọ pe nnkan bii ida aadọrun ninu ọgọrun ni awọn ti ri gbe ṣe ninu gbogbo ọrọ beeli ti ile ẹjọ pa laṣẹ.

Ẹwẹ, agbẹjọro naa ko ṣalaye ewo gaan ni wọn ri gbe ṣe ninu gbogbo rẹ.

Torinaa, ko si ẹni to lee sọ ibi ti igbiyanju lati ko Portable yọ ninu ẹjọ labẹ ofin ja si ayafi pe ẹjọ gbogbo, o di ọjọ ti wọn sun igbẹjọ naa si.

Ki lo ṣẹlẹ ninu ile ẹjọ?

Ṣe ni ara Portable rọ̀ wọ̀ọ̀ ninu akoto ile ẹjọ nibi to ti kawọ pọnyin jẹjẹ lai janpata to n wo oju adajọ ati awọn agbẹjọro.

Gẹgẹ bi ile ẹjọ giga ipinlẹ ogun to wa ni agbegbe Ifo ṣe bẹrẹ igbẹjọ gbajugbaja olorin Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable olorin Zazu, ọna mii ni igbẹjọ naa gba yọ o.

Akọroyin BBC Yoruba fabọ jẹni pe lasiko ti igbẹjọ naa n lọ lọwọ ile ẹjọ ka ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa sita.

Isọri meji gboogi ni wọn pin ẹsun ti wọn fi kan Portable si amọ isọri akọkọ ni abala meji, bẹẹ si ni isọri keji ni abala mẹta.

Akọkọ ẹsun naa ni abala meji ninu, ohun si ni pe pe o lu eeyan meji ti wọn si fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa.

Ile ẹjọ kọ lati darukọ awọn mejeji ti Portable lu ninu ile ẹjọ, wn ni awn yoo sọ ọ to ba ya.

Bakan naa, isọri ẹsun keji ni abala mẹta, akọkọ si ni ṣe pẹlu pe o ji awọn ohun elo orin bii duuru, gbohungbohun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Portable ni ile ẹjọ

Ilé ẹjọ sọ ìdí tí Portable yóò fi wà látìmọ́lé Ilaro títí di ìgbà tí yóò rí béèlì san

Idi ti ile ẹjọ fi sọ pe wọn yoo gbe Portable lọ si ọgba ẹwọn to wa ni ilu Ilaro ni wipe, o gbudọ wa ni ahamọ titi di igba ti yoo ri awọn beeli ti wọn fun un ṣẹ.

Ṣe ni wọn tun fi ede Yoruba ṣalaye awọn nnkan ti wọn sọ fun Portable ti wọn si bii pe ṣe gbogbo rẹ ye e. Wọn ṣe eyi nitori wipe ede Yoruba ni ọpọ mọ ti olorin naa maa n sọ ju.

Ki ni beeli ti wọn fun Portable?

Ile ẹjọ

Ile ẹjọ paa laṣẹ fun Habeeb Okikiola pe ko wa oniduro meji. Ọkan ninu wọn gbudọ jẹ ibatan rẹ ko si san ẹgbẹrun lọnaa ọọdunrun naira (N300,000) ati pe ẹni naa gbudọ ni ilẹ ara tirẹ ni agbegbe ipinlẹ Ogun.

Oniduro keji ti wọn ni ki Portable wa le ma jẹ ibatan rẹ amọ o gbudọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000).

Ile ẹjọ sun igbẹjọ Portable siwaju

Portable

Nibayii, yala yoo wa ni ahamọ ni o tabi yoo san beeli ti wọn fun un, Habeeb Okikiola yoo tun farahan niwaju adajọ ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2023.

Ẹwẹ, akọroyin BBC Yoruba jabọ pe awọn agbẹjọro Portable n sọrọ lọwọ ninu ile ẹjọ lati wo bi wọn ṣe le ri beeli naa san pẹlu gbogbo oniduro ti ile ẹjọ beere fun.

Bi wọn ba ri eyi ṣe, ko ni nilo ki Portable wa ni atimọle Ilaro mọ, yoo gba ile rẹ wa lati jẹjọ ni ọjọ ti wọn sun igbẹjọ naa si ni.

Portable níwájú adájọ́, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ

Portable

Ni yajoyajo bo ṣe n tẹ wa lọwọ ni pe Habeeb Okikiola ti gbogbo eeyan mọ si Portable olorin Zazu ti de iwaju adajọ bayii ni ile ẹjọ to wa ni agbegbe Ifo nipinlẹ Ogun.

Akọroyin BBC Yoruba jabọ pe ṣe ni ita ati inu ile ẹjọ kun fọfọ fun ero atawọn oniroyin ti wọn fẹ mọ abajade igbẹjọ naa.

Portable
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Ileeṣẹ Ọlọpaa ti fi ọrọ sita lori iru ẹṣẹ ti gbajugbaja olorin ti ẹnu kii ṣi lori rẹ, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ṣẹ.

Ileeṣẹ naa ti fi aridaju han ni ọjọ Abamẹta pe Portable yoo foju ba ile ẹjọ fun ẹsun mẹfa latari bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu u laipẹ yii.

Eyi waye lẹyin ti ọpọlọpọ fidio gba ori ayelujara kan ni Ọjọ Iṣẹgun eyi ti olorin naa ti n gbena woju awọn ọlọpaa ni ile igbafẹ rẹ kan to wa ni ipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, Muyiwa Adejobi ti wa fi oniruuru ọrọ sita loju opo Twitter rẹ lati ṣalaye iru ẹsun ti Portable yoo koju.

Adejobi jẹ ko di mimọ nigba to n fesi si eeyan kan lori Twitter to ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati fi Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo jofin nigba to sọrọ to tabuku ẹya amọ wọn wa fẹ fi ofin gbe Portable bayii.

O fesi wipe: “O da mi loju pe ẹ rii bi mo ṣe yanju ọrọ ti MC, amọ ni ti Portable, ẹsun to le ni mẹfa ni yoo jẹjọ le lori, yatọ fun pe ko jẹ ki wọn fi ofin gbe e ati pe o ṣe ọlọpaa kan leṣe.

Ile ẹjọ Ifo

Àánú ni mo ṣe fún Manny Monie, ohun tó ṣẹ́lẹ̀ láàrin wa rèé tó fi tọ ọlọ́pàá lọ - Portable

Gbajugbaja olorin takasufe, Habib Okikiola, ti a mọ si Portable ti sọrọ jade bi lori igbesẹ ọlọpaa lati wa fi tipa mu nile ọti rẹ.

Bakan naa lo tun tan imọlẹ si awọn ẹsun ti osisẹ rẹ, Manny Monie se lọ fi ẹjọ rẹ sun ileeṣẹ ọlọpaa Ogun.

Isẹlẹ naa si lo fa bi rogbodiyan to waye laarin Portable ati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọjọ Isẹgun.

Portable, ninu fidio to gbe sori ayelujara ni oun ba ọmọ isẹ oun, iyẹn Manny Monie wi nitori ko mọ ọtun yatọ si osi ni.

"Ọmọ isẹ mi ni, ẹni ki wọn ma ba wi, jẹjẹ ni mo wa, ti wọn wa n ba mi pe ki n ran awọn lọwọ.

"Mo ran lọwọ tan, mo ra foonu fun ẹ, mo fun ẹ ni ounjẹ, o sun ni ile mi.

"Mo le gbogbo wọn danu nitori ko si apẹẹrẹ pe wọn nifẹ ara wọn."

Ile ẹjọ Ifo