Àwọn ẹ̀sùn mẹ́fa tí Portable yóò jẹ́jọ́ lé lórí rèé – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Portable

Oríṣun àwòrán, Golden Pixel/Portable

Ileeṣẹ Ọlọpaa ti fi ọrọ sita lori iru ẹṣẹ ti gbajugbaja olorin ti ẹnu kii ṣi lori rẹ, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ṣẹ.

Ileeṣẹ naa ti fi aridaju han ni ọjọ Abamẹta pe Portable yoo foju ba ile ẹjọ fun ẹsun mẹfa latari bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu u laipẹ yii.

Eyi waye lẹyin ti ọpọlọpọ fidio gba ori ayelujara kan ni Ọjọ Iṣẹgun eyi ti olorin naa ti n gbena woju awọn ọlọpaa ni ile igbafẹ rẹ kan to wa ni ipinlẹ Ogun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, Muyiwa Adejobi ti wa fi oniruuru ọrọ sita loju opo Twitter rẹ lati ṣalaye iru ẹsun ti Portable yoo koju.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Adejobi jẹ ko di mimọ nigba to n fesi si eeyan kan lori Twitter to ni ileeṣẹ ọlọpaa kọ lati fi Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo jofin nigba to sọrọ to tabuku ẹya amọ wọn wa fẹ fi ofin gbe Portable bayii.

O fesi wipe: “O da mi loju pe ẹ rii bi mo ṣe yanju ọrọ ti MC, amọ ni ti Portable, ẹsun to le ni mẹfa ni yoo jẹjọ le lori, yatọ fun pe ko jẹ ki wọn fi ofin gbe e ati pe o ṣe ọlọpaa kan leṣe.

Diẹ lara awọn ẹsun ti wọn ka si Portable lẹsẹ?

“Yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe o lu ọkunrin kan ni agbegbe Otta ti ẹni naa si fi ẹsun kan an lọdọ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ̀ Ogun.

Ọpọlọpọ ẹsun ni awọn eeyan tun ti fi kan an nipa ṣiṣe ikọlu si wọn torinaa, a o fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Adejobi sọ pe ko si oju iṣaju labẹ ofin “torinaa ẹ jẹ ko foju ba ile ẹjọ ki a si gba awọn adajọ laye lati gbọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an. Ko kọja ofin rara.”

Ẹwẹm awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi aridaju han pe wọn fi panpẹ ofin mu Portable ni ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ti wọn si ni wọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti wọn fun un ni gbedeke oni wakati mejilelaadọrin lati bọwọ fun ipe ti ọlọpaa fi pe e.

Mi ò mọ̀ pé ọlọ́pàá làwọn tó wá mú mi ló jẹ́ kí n gbéná wojú wọn – Portable

Portable

Oríṣun àwòrán, Portable

Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable, ti ṣalaye eredi to fi gbena woju awọn ọlọpaa to gbiyanju lati fi ṣikun ofin mu nile ọti rẹ kan to wa nipinlẹ Ogun.

Ṣaaju nileeṣẹ ọlọpaa naa ti kọkọ fun Portable lọjọ mẹta pere lati yọju si agọ wọn lẹyin ti fidio ibi to ti kọ ki wọn mu fa ori ayelujara ya.

Iroyin ni igba marun un ọtọtọ ni awọn ọlọpaa ti fi iwe pe Portable amọ o kọ lati da wọn lohun ki wọn to lọ fi ṣikun ofin mu nile ọti rẹ.

Ninu fidio mii to tun ti gba ori ayelujara bayii ni Portable ti n sọ niwaju ọga ọlọpaa pe oun ko mọ pe ọlọpaa lawọn to wa mu oun lo jẹ ki oun wu irufẹ iwa ti oun wu si wọn.

Ti ẹ ko ba gbabe, asiko ti wọn wa mu Portable nile ọti rẹ lo kọ jalẹ fun awọn ọlọpaa naa to si n bere lọwọ wọn eredi ti wọn fi wa mu oun.

O ni “Ọmọ ijọba ni mi, ijọba ni mo n ba ṣiṣẹ, ẹ ko le wa mu.”

“Mi o jale, mi o si paayan, kii ṣe ọna ẹburu ni mo fi pa owo ti mo n na.”

Ẹsun to le ni mẹfa ni Portable yoo koju nile ẹjọ - Ọlọpaa

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe Portable yoo foju bale ẹjọ lori oniruru ẹsun.

Alukoro ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejo lo fi ọrọ naa lede loju opo Twiter rẹ.

Muyiwa Adejobi

Oríṣun àwòrán, @Princemoye1

Adejobi ni ẹsun to le ni mẹfa ọtọtọ ni Portable yoo koju nile ẹjọ.

O ni “Ẹsun ti Portable yoo jejọ rẹ nile ẹjọ le ni mẹfa, yatọ si pe o kọ ki awọn ọlọpaa mu, o tun ṣe ọlọpaa leṣe.”

“Yoo foju bale ẹjọ lori ẹsun pe o lu ọmọkunrin kan nilu bara niluu Otta, eyii to kọ iwe mọ ni ọọfisi kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun.”

Ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ ọba mú Portable fún ẹsún ìwà ipá

Portable

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ọlọpaa mu gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikitiola ti ọpọ eniyan mọ si Portable.

Ọwọ ọlọpaa tẹ lẹyin ti wọn kede pe wọn fun un ni wakatiu mejilelaadọrin lati wa jọwọ ara rẹ ni agọ ọlọpaa.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni wọn ti ke si Portable lati yọju si agọ ọlọpaa tabi ki wọn wa fi panpẹ ọba mu.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn fi panpẹ mu lẹyin to kọ lati yọju si agọ ọlọpaa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ fun awọn ọlọpaa pe lootọ ni Portable wa ni agọ awọn.

Bakan naa ni wọn fikun un pe yoo wa nibẹ titi di Ọjọ Aje ti yoo lọ foju ba ileẹjọ.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe ẹsun iwa ipa ati dida alaafia agbegbe ru ni wọn fi kan an ti yoo si wa wi ti ẹnu rẹ.

‘Baboon challenge’ gba orí ayélujára lẹ́yìn tí Portable pe ara rẹ̀ ní ọ̀bọ

N ṣe ní ọ̀rọ̀ di àwàdà kẹríkẹrì nígbà tí gbajúgbajà olórin tàkasúfèé nnì, Habeeb Okikiola, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable gba ọ̀nà àrà yọ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá fẹ́ nawọ́ gan lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Àwọn ọlọ́pàá ló lọ sí ibi iṣẹ́ Portable pẹ̀lú èròńgbà láti fi póró òfin gbe, lẹ́yìn tó kọ̀ láti yọjú sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ̀wé ránṣẹ́ si nígbà márùn-ún.

Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ̀ Portable tó gbajúmọ̀ fún orin rẹ̀, Zazzu, ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe onírúurú nǹkan láti lè má jẹ̀ẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá rí òun mú.

Portable ní àgbà ìlúmọ̀ọ́ká ni òun nítorí náà àwọn ọlọ́pàá kò lè fi póró òfin gbé òun.

Portable

Oríṣun àwòrán, Portable/Instagram

Èmi ni Zazzu, ìnàkí ni mí, ọ̀gbà ẹranko ni mò ń gbé - Portable

Bákan náà ni akọrin tó máa ń pe ara rẹ̀ ní Were Olorin yìí fi ara rẹ̀ wé ọ̀bọ àti ìnàkí àti pé ilé ẹranko ní òun ń gbé.

“Àwọn òṣìṣẹ́ yín ní kí wọ́n mú mi, ẹ fẹ́ di ìlú mọ̀ọ́ká mú, ṣe oníjìbìtì ni mí bi?”

“Gbogbo nǹkan tí mo ní, iṣẹ́ ọwọ́ mi ni mo fi rà á, kí ló dé tẹ ṣe wá mú mi?”

“Ṣé ẹ mọ̀ nǹkan tó ń gbé inú mi, ẹ mọ̀ nǹkan tó ń ṣe mi ni, kí ni ẹ̀ ń wá?”

“Ọ̀bọ ni mí, ilé àwọn ẹ̀ranko ni mò ń gbé, Zazzu, ẹẹẹẹẹẹẹ”

“Inú igbó lo ti ma blow, wọ́n lé mi títí láti Lekki, mo sá wá inú igbó, ẹ tún lé mi wá inú igbó.”

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Àwọn aláwàdà bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ọ̀rọ̀ Portable yii láti fi ṣàwàdà

Lẹ́yìn tí fídíò Portable náà gba orí ayélujára ni àwọn aláwàdà orí ayélujára kan, ọ̀pọ̀ aláwàdà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀nyí láti fi dẹ́rìnín pẹ̀kẹ́ àwọn ènìyàn.

Lára àwọn tó ti lo Zazzu Challenge yii ni Mr Sabinus, Agbainaki, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Àkọlé fídíò, Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

Ọjọ́ mẹ́ta péré la fún Portable láti yọjú sí àgọ́ wa bíbẹ́ẹ̀kọ́... - Ọlọ́pàá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fún gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Habeeb Okikiola, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable ní ọjọ́ mẹ́ta láti yọjú sí àgọ́ àwọn tàbí kí àwọn fi póró òfin gbé e.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni Portable ti kọ́kọ́ fi àwọn fídíò méjì kan sórí ayélujára níbi tó ti ń sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn ọlọ́pàá tó fẹ́ mu ní ọ́fíìsì rẹ̀.

Nínú fídíò náà ló ti ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn oníjìbìtì orí ayélujára kó àwọn ọlọ́pàá wá sí ibi iṣẹ́ òun láti wá kó àwọn òṣìṣẹ́ òun láì ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kankan.

Nígbà tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ń bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta péré ni àwọn fún Portable láti yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá àwọn bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn máa fi póró òfin gbe.

Bàbá Portable ti ṣe ìlérí láti mu wá sí àgọ́ wa

Oyeyemi ní ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Portable láti yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ṣùgbọ́n tó kọ̀ láti yọjú.

Ó ní nǹkan tí àwọn ń pe Portable fún kò ṣẹ̀yìn bí ẹnìkan ṣe wá fi ẹjọ́ Portable sùn pé òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wá na òun mọ́ ibi iṣẹ́ òun tí wọ́n sì tún ti ilé iṣẹ́ òun pa.

“Láti ìgbà náà láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Portable àma tó kọ̀ láti yọjú kódà á tún fi ìwé mìíràn ránṣẹ́ pé gba ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ àmọ́ ó tún kọ̀ láti yọjú síbẹ̀ náà.

“Bàbá Portable ti bẹ̀ wá pé òun máa mu wá sí àgọ́ ọlọ́pàá fúnra òun àmọ́ tí bàbá rẹ̀ náà bá kọ̀ láti mu yọjú sí wa títí ọjọ́ Ẹtì, a máa fi póró òfin gbé e.”

Kí ló fa wàhálà láàrín ọlọ́pàá àti Portable, tó fi já ara rẹ̀ sí ìhòòhò?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fesi si fidio to n ja ranyin lori ayelujara nibi ti gbajugbaja olorin takasufe, Alan Abraham ti ọpọ mọ si Portable, ti fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn fẹ fi panpẹ mu oun ni ọna aitọ.

Ninu Fidio naa, ti Portable funra rẹ gbe sori afẹfẹ Twitter ati Instagram rẹ, lo ti bọ asọ kruo lọrun, to si n laagun bọyọ.

O ni awọn ọlọpaa wa da ile igbafẹ oun ru, ti wọn si fẹ fi panpẹ mu oun ni ọna aitọ.

Ninu fidio naa lo ti n beere ni ọwọ awọn ọlọpaa naa pe ki ni oun ṣe fun awọn ọlọpaa ti wọn ti wa fi panpẹ mu oun.

Ki ni Portable sọ ninu fidio?

Ọmọ ijọba ni mi, ijọba APC ni mo n sisẹ fun - Portable figbe ta fawọn ọlọpaa

Ninu fidio to wa lori Twitter naa ni wọn ti ri Portable to ni awọn ọlọpaa ti wọle tọ oun wa lai nidi, ti wọn si ni awọn fẹ fi panpẹ mu oun.

O fi ẹsun kan wọn pe wọn fẹ wa da ileeṣẹ oun ru ,ki wọn si ko awọn eniyan nibẹ

‘’Ki ni mo ṣe fun ẹyin ọlọpaa, ṣe mo jọ ọmọ Yahoo ni, gbogbo nkan ti mo ni lo gba aṣẹ ijọba, lẹgit ni.

Ki lẹ wa ṣe ni ọfisi mi, ki lo de ti ẹ ni mo wa under arrest? Ki ni mo ṣe fun yin?

Ẹ kan wọle wa lai ro tẹlẹ, kini mo ṣe ti ẹ fi fẹ panpẹ ọba mu mi?

Bakan naa ni Portable n sọ fun awọn ọlọpaa ninu fidio naa pe ọmọ ijọba ni oun, ti oun si ṣiṣẹ fun ijọba APC.

Ohun ti Ọlọpaa sọ ree...

Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ninu ọrọ rẹ ni Portable n da wahala silẹ ni agbegbe rẹ, ni awọn ṣe fẹ fi panpẹ ọba mu.

Oyeyemi ni igba marun un ni awọn ti kọ iwe ipẹjọ sii lati wa si agọ ọlọpaa amọ o kọ lati yọju si wọn.

O ni awọn tun fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si baba rẹ, ti Portable tun kọ lati yọju si agọ ọlọpaa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni ọga ọlọpaa ni ẹka agbegbe Portable, lo ni ẹkunrẹrẹ iroyin ti wọn fi kan an.

O ni ọpọ igba ni Portable ti ran awọn onijagidijagan lati lọ maa lu awọn eniyan, to si n da alaafia agbegbe naa jẹ.

"A ti gba asẹ nile ẹjọ lati fi agbara ofin gbe Portable"

Amọ Oyeyemi ni Baba Portable ti ni ki awọn fun oun di opin ọṣẹ lati mu Portable wa si agọ ọlọpaa lati yọju si wọn.

‘’Portable n da wahala silẹ ni agbegbe rẹ, a si ti gba iwe lati ileẹjọ lati fi panpẹ mu nitori o kọ lati yọju si agọ ọlọpaa.’’

‘’A wa ọlọpaa ko dede lọ si ibẹ, wọn fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa ni to si kọ lati yọju.’’

‘’Niṣe ni Portable bọ ara rẹ si ihoho nigba ti a de ibẹ lati wa fi panpẹ mu, to si bẹrẹ si ni pariwo.’’

‘’ Baba rẹ ti fi da wa loju pe yoo jọju si agọ ọlọpaa titi opin ọṣẹ.’’

‘’Amọ̀ ti ko ba yọju, a o fi tipatipa mu lọ si agọ ọlọpaa lati wa ro ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.’’