Wọ́n fipá mú mi lọ ilé ẹ̀kọ́ ni, iṣẹ́ amúlùúdùn gan ni mo fẹ́ràn láti ṣe - Adeleke

Aworan Ademola Adeleke

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti salaye idi to se fẹran ijo jijo ati orin eyi ti ọpọ eeyan mọ si.

Ademola Adeleke ni ọpọ mọ fun bi o ṣe ma fi ijo dabira to ba ti wa ni agbo oselu tabi ibi igbafẹ.

Gomina Adeleke sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto ifọrọwanilẹnuwo kan nileesẹ mohunmaworan Arise to wa nilu Eko.

Lasiko to idahun si ibeere pe ki ni ibasepọ rẹ pẹlu ijo ati bi ko se ni se akoba fun isejọba rẹ nipinlẹ Osun si lo ti sọrọ nipa ifẹ ọkan rẹ naa.

Adeleke ni ibi oun se n jo eyi ti ọpọ eeyan nifẹ si, ko sẹyin ifẹ ti oun gan ni si orin kikọ ati ijo jijo.

O wa salaye pe isẹ amuluudun ni oun fẹran lati se sugbọn awọn obi oun kọ jalẹ pe oun gbọdọ lọ si ile ẹkọ.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

"Mo maa n pa owo Dọla lasiko ti mo ba lọ fun idije ijo jijo"

Adeleke ni oun fẹran orin ati ijo nitori pe o ma tu oun lara pupọ ati pe ko jẹ ohun iyalẹnu pe awọn ọmọ ati ọmọ ẹgbọn oun mu orin at ijo gẹgẹ isẹ.

"Isẹ amuludun lo wu mi lati se sugbọn lasiko ti a n dagba, baba wa ko ni igbagbọ ninu nnkan bayẹn.

Baba wa fẹran pe ka kawe lati di Dokita tabi Agbẹjọro.

"Wọn fipa mu mi pe ki lọ si ile ẹkọ, koda, nigba ti mo wa ni Amẹrika lasiko ti Micheal Jackson ti wa nita.

Mo maa n lọ kaakiri lati kopa ninu idije ijo, ti mo si maa n pawo owo dọla.

Ademola Adeleke ati B Red

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke

"Ko ya mi lẹnu bi ọmọ mi ati ọmọ ẹgbọn mi, Davido se di gbajumọ olorin yika agbaye"

Gomina Adeleke ni ko jẹ ohun iyalẹnu fun oun bi awọn ọmọ oun B Red àti Shina Rambo pẹlu ọmọ ẹgbọn oun, eyiun David Adeleke, ti ọpọ mọ si Davido, se n se orire latara isẹ orin kikọ.

O ni o seese pe ara oun ni wọn ti mu isẹ orin kikọ nitori o jẹ nnkan ti oun fẹran ju.

"Ti mo ba lọ ode, ti n ko ba ti jo, awọn eeyan maa n bi mi pe ki lo sẹlẹ.

"Mo lodi si pe ka wa ni ibi kan, ka wa dakẹ, ka ma dun ara wa ninu"

Davido ati Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Davido

B Red, Davido ati Shina Rambo

Oríṣun àwòrán, B Red

"Asiko ijo wa, Asiko isẹ, ko tako ara wọn lara"

Gomina tẹsiwaju pe bi awọn kan se tabuku rẹ bi o se jo ni ko nikan se pẹlu isẹjọba rẹ.

Adeleke ni oun ko ni fi aye fun ẹnukẹni lati dari igbesi aye rẹ ati gbogbo nnkan lo ni asiko

"N ko le sọ pe nitori mo di sẹnẹtọ tabi Gomina, ma go fun nnkan ti mo fẹran.

"Sugbọn gbogbo nnkan lo ni asiko, ti asiko ba to fun lati ijo, ma jo

Àkọlé fídíò, Goroso Ekiti: N kò kábàámọ̀ pé mo gbọ́ Ekiti, òhun ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ gómìnà

Tọ́ọ̀gì 781 tó da ìbò rú yíká Nàíjíríà ti bọ́ sí gbaga wa - Ọ̀gá ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria kede pa awọn ti mu awọn eniyan to le ni ẹẹdẹgbẹrin to da wahala silẹ lasiko idibo kaakiri ni Naijiria.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba sọ eyi ni ọjọ Aje lasiko to n se ipade pẹlu awọ̀n kọmiṣọnna ọlọpaa to wa ni ipinlẹ mẹrindinlogoji ati ilu Abuja.

Gẹgẹ bi ọrọ ọga agba ọlọpaa naa, iye awọn ti wọn ti mu bayii le ni ẹẹdẹgbẹrin (781).

"Awọn oloṣelu kan fẹ da alaafia orilẹede yii ru nigba ṣiṣe agbatẹru fawọn janduku lasiko idibo"

Alkali Baba ni awọn ẹniyan to le ni igba, ni awọn fi panpẹ ọba mu lasiko idibo sipo aarẹ kaakiri Naijiria ni awọn agọ idibo to le ni ọgọjọ.

O ni lasiko idibo sipo gomina ati idibo sipo aṣojuṣofin ipinlẹ, ni awọn mu awọn onijagidijagan to le ni ẹẹdẹgbẹta ni awọn agọ idibo to le ni ọọdunrun.

Ninu ọrọ rẹ, ọga agba ọlọpaa ni Naijiria naa ni ipade pẹlu awọn kọmiṣọnna naa pọn dandan nitori jagidijagan le da alaafia orilẹede Naijiria ru.

Baba ni awọn oloṣelu kan n gbiyanju lati da alaafia orilẹede yii ru nigba ṣiṣe agbatẹru fun awọn onijagidijagan lasiko idibo.

Bakan naa lo fikun un pe awọn ti wọn mu naa tapa si ofin to rọ mọ eto idibo ni Naijiria.

Ọga agba ọlọpaa naa tun bu ẹnu atẹ lu awọn olosẹlu ti wọn n sọrọ kubakugbe tabi sọrọ ẹlẹyamẹya lasiko idibo ati lẹyin idibo naa.

Usman Alkali Baba wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati gba alaafia laaye fun ilọsiwaju kaakiri orilẹede Naijiria.