Màmá tó dáná sun ọmọ, aya ọmọ àti ọmọ-ọmọ méjì jáde láyé

Iya agba kan, Iforiti Oloro, to dana sun ọmọ rẹ Victor Oloro, iyawo ọmọ rẹ Rachael Oloro atawọn ọmọ wọn meji, Toluwani ati Blessed ni ọsẹ meji sẹyin, lo ti dagbere faye.
Ọmọ iya naa, Augustine Oloro to fidi ọrọ naa mulẹ lakoko to n ba BBC Yoruba sọrọ.
Augustine wi pe iya oun dakẹ nile iwosan to ti n gba itọju lana ọjọ Isẹgun lẹyin igbiyanju lati doola ẹmi rẹ.
Augustine to jẹ akọbi iya agba naa ati awọn ọlọpaa, ni wọn gbe Iforiti lọ ile iwosan ijọba apapọ FMC to wa nilu Owo.
Iya agba naa lo farapa lakoko to gbiyanju lati dana sun ara rẹ lẹyin iku ọmọ rẹ to ti dana sun ṣaaju.
Iya naa lo ni iyawo ọmọ ohun ni oun fẹẹ dana sun lai mọ pe yoo mu ẹmi ọmọ oun lọ.
Awọn aladugbo ti wọn kẹẹfin eefin ati oorun to n jade lati inu ile naa ni wọn sare wọle lati pa ina ọhun, ti wọn si doola ẹmi rẹ.
Ṣaaju ki o too dana sun ara rẹ, Iforiti lo kọ lati jẹun tabi mu ohunkohun lẹyin to gbọ iro iku ọmọ rẹ, Victor.
Victor lo padanu ẹmi rẹ latari ifarapa to ni ninu ina ti iya rẹ fi ṣe jamba fun oun ati aya rẹ.
Ẹwẹ, awọn agbofinro lo ti ni awọn ko ni ẹjọ kankan lati ṣe mọ lẹyin ti ẹni afẹsunkan ti jade laye.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lẹyin ti Iforiri ti padanu ẹmi rẹ.
Odunlami ni ko si ẹjọ lati ṣe lori iṣẹlẹ naa mọ nitori pe ẹnikan ṣoṣo ti wọn le gbe lọ ile ẹjọ fun iṣekupani lo tun ti dagbere faye leyi to mu ki ẹjọ naa o ku funra rẹ.
'Ìyàwó ọmọ rẹ̀ ni Màmá ní sínú tó fi dáná sunlé, kò mọ̀ pé yóò pa ọmọ rẹ̀'
Laipẹ yii la mu iroyin kan wa fun yin nipa mama agba kan to dana sun ile, eyi to seku pa ọmọ rẹati aya ọmọ rẹ, ti ọmọ-ọmọ rẹ meji si fara pa.
BBC Yoruba wa kan si adugbo ti isẹlẹ naa ti waye nilu Apọnmu nipinlẹ Ondo.
Nibẹ la si ti bawọn aladugbo sọrọ nipa bi isẹlẹ naa se waye.
Ọkan lara awọn aladugbo to ba wa sọrọ ni mama naa ti orukọ rẹ n jẹ Iforiti Oloro, ti buru ju, to si nika ninu.
Ọkunrin naa salaye pe lootọ ni ohun ti awọn ọmọ mama naa se fun ko dara to nitori pe wọn ko fun ni ounjẹ jẹ.
Eyi si ni wọn lo bi mama agba naa, ẹni ọdun marundinlọgọrin ninu, to se fi ogunsọ ati epo eebo dana sun ile tawọn idile ọmọ rẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Comrade Lucky Franca Ijeoma
"Aya ọmọ Mama lo ni sinu to se dana sun ile lai mọ pe ina naa yoo pa idile ọmọ rẹ run"
Aladugbo naa tẹsiwaju pe ko si ẹni to le sọ pato lori idi ti mama naa fi se ohun to se yii, to fi dana sun ile.
O ni mama naa sọ fun awọn pe iyawo ọmọ oun ni oun ni sinu lai mọ pe igbesẹ didana sun ile naa yoo pa ọmọ oun.
O fikun pe mama naa ti buru ju, ọti, ẹja ati obi si lo n ta, ti gbogbo aladugbo si mọ bi ẹni mọ owo.
O fikun pe owu aini odiwọn ni mama n jẹ, eyi to fi gbe igbesẹ didana sun ile, to si fi epo eebo si aha, o sana si, to si sọ sinu ile.
"Mama ti di gbogbo ferese ile, to si tun ti ilẹkun tawọn ọmọ rẹ le gba sita lẹyin to ti ina bọle"
Aladugbo naa salaye pe aago kan abọ oru ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2023 ni isẹlẹ naa waye.
O ni oru mọju ọjọ ibo gomina si ni isẹlẹ naa.
"Sadede ni mo gbọ gbi, ti ina si sọ ninu yara naa, mama ti di gbogbo ferese ile naa, to si tun ti ilẹkun tawọn ọmọ rẹ le gba sita.
O ni ọmọ mama lo tiraka lati fa awọn ọmọ rẹ yọ pẹlu awọn aladugbo, ti wọn si gbe wọn lọ sile iwosan.
Bakan naa lo yọ iyawo rẹ, ti oun naa si n mi hẹlẹ hẹlẹ, o ti rẹ ẹ.
Amọ o se ni laanu pe ọmọ mama ati iyawo rẹ lo jẹ Ọlọrun nipe."
"Mama gan fẹ da ina sun ara rẹ ni igba keji, o ni ẹsẹ oun ti pọju"
Awọn aladugbo naa ni mama gan setan lati jona mọ inu ile naa.
Ọ ni mama yii gan tun fẹ dana sun ara rẹ nigba keji lẹyin ti wọn yọ ninu ile tan nitori o ni ẹsẹ oun ti pọ ju.
Aladugbo naa ni ọp ijamba ni mama naa ti se sẹyin fun aya ọmọ rẹ, debi pe o ju foonu ti obinrin naa n lo fun isẹ POS sinu kanga lasiko kan.
Amọ o sọ pe lẹyin ti isẹlẹ naa waye, awọn ọmọ mama yoku kọ lati setọju iya naa, ti wn si fi silẹ fun ọjọ marun lai fun ni ounjẹ.
Amọ o ni mama naa ko ku, bẹẹ ni ko se aisan titi tawọn ọlọpaa fi wa gbe lọ si agọ wọn.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye saaju?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu iya ẹni ọdun márùndínlọ́gọ́rin kan lori ẹsun pe o dana sun ọmọ rẹ ọkunrin, iyawo ọmọ rẹ naa atawọn ọmọ wọn meji mọle.
Iya agba naa, Iforiti Oloro, n gbe pẹlu ọmọ rẹ ọhun ati ẹbi rẹ niluu Aponmu, to wa lopona ilu Akure si Ondo.
Iroyin ni asiko ti awọn oloogbe naa n sun ni afurasi ọhun lọ dana sun ile tin wọn wa.
Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Korede Michael sọ pe ṣadede lawọn ri ile awọn eeyan naa to n jo ni nnkan bii aago meji oru, ki wọn to ja ferese ile naa lati yọ awọn to wa ninu rẹ.
O ni “Iya agba naa, ọmọ rẹ to n jẹ Victor Oloro, iyawo rẹ Rachael atawọn ọmọ wọn, Toluwani ati Blessing lo wa ninu ile nigba to sọ ina sibẹ.”

Oríṣun àwòrán, Andrew Jerry
"Wọn ti jona kọja ala"
“Lẹsẹ kan naa ni a ko wọn sinu ọkọ ti a si gbe wọn lọ sile iwosan ijọba to wa niluu Akure.”
Korede sọ siwaju si pe nigba ti wọn yoo fi dele iwosan ijọba, UNIMED niluu Akure, wọn ni ki awọn gbe wọn lọ sile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa niluu Ọwọ nitori ina ọhun ti jo wọn kọja ala.
O ṣalaye siweaju si pe “O ṣeni laanu pe ọmọ abikẹyin ku ni kete ti a de ilu Ọwọ.”
“Lọjọ Isinmi, ọmọ iya agba naa ati iyawo rẹ jade laye nigba ti ọmọ kan ṣoṣo to ku wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.”
Iya agba ọhun, Iforiti ko farapa ninu ina naa rara.
Amọ awọn eeyan adugbo ni iya agba naa ti kọkọ gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ lọdun 2022 nigba to ko sinu kọnga.
Korede ni “Awọn ọmọ rẹ ko le ni ko kuro ninu ile naa lẹyin to bẹrẹ si n ṣiwa wu nitori ọkọ rẹ to ti di oloogbe lo kọ ile naa.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami to fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin sọ pe awọn ti tare ẹjọ naa si ẹkọ to n ṣewadii iwa ọdaran, SCID.






