Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọmọ ọ̀dọ̀ tó pa ọ̀gá, ọmọ rẹ̀ ní Eko

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ilé ẹjọ́ gíga tó wà ní Ikeja ní ìpínlẹ̀ Eko, ti dá ẹjọ́ ikú nípa yíyẹ igi fún arákùnrin kan, Joseph Ogbu lórí fẹ́sùn ìpànìyàn.
Ogbu ni wọ́n ní ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó pa ìyá àgbà kan, Ajoke John, ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún.
Bákan náà ní Joseph tún pa ọmọ màmá náà, Oreoluwa John, ẹni ọdún méjìdínlógójì tó ń bá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀ ní agbègbè Surulere ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ogbu tó jẹ́ ọmọ bíbí ìjọba ìbílẹ̀ Oju ní ìpínlẹ̀ Benue, ṣekúpa àwọn ọ̀gá rẹ̀ yìí ní ilé wọn tó wà ní ojúlé kẹrin, Ogunlana Drive, Surulere.
Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kẹfà, ọdún 2019 ni Joseph Ogbu hu iwa ika ọhun.
"Ogbu kò jiyàn lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọn fi kàn-án, èyí túmọ̀ sí pé ó hu ìwà ìpànìyàn náà"
Lẹ́yìn ọjọ́ kan tí wọ́n gba Ogbu síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀, ló ṣekúpa àwọn ènìyàn yìí.
Adájọ́ Modupe Nicole-Clay ní àwọn tó fẹ̀sùn kan Ogbu rí ẹ̀rí tó dájú láti fi ìdí ẹjọ́ wọn múlẹ̀ nípa kókó ẹ̀sùn mẹ́ta tí wọ́n kà sí Ogbu lọ́rùn.
Lára àwọn ẹ̀sùn náà ni èyí tó jẹ mọ́ ìwà ìdigunjalè àti ìpànìyàn, àdájọ́ sì ní Ogbun ló jẹ̀bi gbogbo àwọn ẹ̀sùn náà pátá.
Nicole-Clay ní afurasí ọ̀hún ní òun nìkan ni òun ń gbé pẹ̀lú àwọn ìyá àti ọmọ rẹ̀ tó pa, tó sì jẹ́ wí pé òun nìkan ni ẹlẹ́rìí tó wà lórí ẹjọ́ ọ̀hún.
“Ó pa Adejoke nípa fí fun-un lọ́rùn pa, tó sì gún Oreoluwa lọ́bẹ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.”
Adájọ́ ní níwọ̀n ìgbà tí Ogbu kò ti jiyàn lórí àwọn ẹ̀sùn yìí, ó túmọ̀ sí pé ó gbà wí pé òun ṣẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí, tó sì tún hu ìwà ọ̀daràn.
“Mo ti gbé àwọn ẹ̀rí aṣọ́nà, ọlọ́kadà, Yahaya Ibrahim kan, ọmọ ọ̀dọ́ àti àyẹ̀wò ọlọ́pàá yẹ̀wò fínífíní dáadáa.”

Oríṣun àwòrán, Facebook
"Apànìyàn náà kò le ṣàlàyé bí ẹ̀rù àwọn ọ̀gá rẹ̀ tó pa, ṣe dé ọwọ́ rẹ̀ nígbà tí ọlọ́pàá mu"
Adajo naa tẹsiwaju pe “Ogbu kò le ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bá àwọn ẹrù tó jí kó nílé àwọn ọ̀gá rẹ̀ tó pa, ṣe dé ọwọ́ rẹ̀ ní aago méjì òru ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gan.”
“Ilé ẹjọ́ yìí faramọ́ gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú rẹ̀ pé Ogbu jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án.”
“Ilé ẹjọ́ yìí ri pé Ogbu Joseph Ogbu jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn tí wọn kà si lọ́rùn, fún ìdí èyí, a dá ẹjọ́ pé kí wọ́n lọ yẹgi fún ọ, títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lọ́rùn rẹ, kí Olúwa dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jìn ọ́.”
Ogbu rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ilé ẹjọ́ láti bojú àánú wo òun nígbà tó ní kìí ṣe wí pé ìyá àgbà náà, Ajoke John kú lójú òun.

Oríṣun àwòrán, Linda Ikeji

Oríṣun àwòrán, Linda Ikeji
Agbẹjọ́rò ìjọba, Olanrewaju Daud ti ṣaájú rọ ilé ẹjọ́ láti dá ẹjọ́ náà bó ṣe tọ́, kí wọ́n fìyà jẹ Ogbu fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀.
Daud ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́ ni Ogbu ṣekúpa àwọn ọ̀gá rẹ̀ yìí tó sì tún jàwọ́n lólè ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn fóònù àti amóhùnmáwòrán.
Ó ní àwọn nǹkan tí Ogbu ṣe yìí lòdì sí abala 222 àti 297 òfin ìwà ọ̀daràn ìpínlẹ̀ Eko tọdún 2015.
Ọlọ́pàá kéde orúkọ̀ àfurasí 20 tí wọn mú pé ó da ìbò rú

Ile iṣẹ ọlọpaa orilẹede yii ti fi panpẹ ofin mu awọn afurasi janduku ogun lori ẹsun wi pe wọn lọwọ ninu idunkokomọni, ti wọn si tun dabaru ilana eto idibo.
Pẹlu bi eto idibo ọdun 2023 ti pari, awọn kan ni iroyin gbe wi pe wọn dunkoko mọ awọn ẹya kan lati mase dibo, ti wọn si tun da awọn kan lọwọkọ lati dibo wọn.
Orukọ awọn tọọgi ogun to ti wa ni atimọle eyi ti alukoro ile iṣẹ ọlọpa fi lede lori ẹrọ ayelujara Twitter rẹ, lo si ti n da awuyewuye silẹ bayi.
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa, Muyiwa Adejobi, ninu atẹjade kan to fisita ni ”ile iṣẹ ọlọpa ti lakaka lati fi ofin mu awọn janduku Ogun, ti wọn kopa ninu madaru eto idibo ọdun yii”.
Ọrukọ awọn afurasi janduku ti ile isẹ ọlọpa mu
1. BASHARI HARUNA
2. MUSTAPHA YAHAYA
3. SAMA’ILA ABDULRAHMAN
4. USAINI ABDULLAHI
5. ADO ISIYA
6. IBRAHIM ABDULLAHI
7. MOHAMMED AHMED
8. SURAJA ABBAS
9. USMAN MUSA
10. FARITA SALE
11. BELLO BALA
12. IBRAHIM ABDULLAHI
13. NASIRU UMAR
14. IBRAHIM ABDULLAHI
15. BELLO BALA
16. SADIQ ALIYU
17. GARBA HASSAN
18. MUSA KAWU
19. BUHARI GARBA
20. ADO MUSA
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn eeyan kan fapa janu pe o yẹ ki orukọ MC Oluomo wa ni lara orukọ janduku ibo ti ọlọpaa gbe sita
Bi ile iṣẹ ọlọpaa ti fi awọn orukọ janduku to da ibo ru naa lede, ni awọn eeyan kan ti n fapa janu lori ẹrọ ayelujara.
Bẹẹ ni wọn n rọ ile isẹ ọlọpa lati fi orukọ alaga ajọ to n ri si akoso gareeji nipinlẹ Eko, MC Oluomo sara orukọ awọn to jẹbi ẹsun idunkokomọni lasiko eto idibo.
Bẹẹ ba gbagbe, Musuliu Akinsanya, ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluomo, ninu fọnran kan to wa lori ẹrọ ayelujara, lo ti n dukoko mọ awọn ẹya kan nilu Eko ṣaaju idibo ile igbimọ asofin ati ti gomina lati mase dibo fun ẹgbẹ oselu miran yatọ si ẹgbẹ oselu APC.
Amọ MC Oluomo ti sẹ lori ẹsun naa pe fidio naa ko wa lati dunkooko mọ ẹya kankan lati mase dibo.
Nigba ti awọn kan n gbosuba kare fun ile iṣẹ ọlọpaa lori agbejade awọn orukọ afurasi janduku yii.
Amọ awọn kan fi aidunu wọn han fun bi ile iṣẹ ọlọpaa ti n fọwọ ra ori ẹni ti o dunkoko mọ awọn ẹya miran ni gbangba.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















