Ohun tí mo bá Ọlọ́run sọ rèé, tí mo fi wọlé fún sáà kejì - Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti kede pe Ọlọrun funra rẹ lo lọwọ si iyansipo oun fun saa keji.
Makinde ni oun ti gbadura si Ọlọrun pe oun fẹ fi ogun rere silẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Oyo lasiko ti oun ba wọle fun saa keji.
Gomina Seyi Makinde sisọ loju ọrọ yii lasiko akanse isin idupẹ ti wọn se fun lori bo se wọle fun saa keji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Oyo.
Ile ijọsin Living Spring to wa ni Aduloju nilu Ibadan ni akanse isin idupẹ naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
"Gbogbo afojusun mi fun ipinlẹ Oyo wa ninu iwe atọnisọna fun idagbasoke ipinlẹ Oyo lati ọdun 2023 si 2027"
Ninu ọrọ rẹ, Makinde ni “Mo ti maa n sọ fun Ọlọrun pe ti n ko ba ni se daadaa lori aleefa, ki n si fa awọn eeyan kuro ninu oṣi bọ sinu ọrọ, n ko gbọdọ wọle sipo gomina fun saa keji.
Ohun gbogbo lo si lọ daadaa ba se fẹ, mo si le ni idasi Ọlọrun ni igbesẹ naa.
Mo wa duro sori pẹpẹ Ọlọrun lati seleri fawọn eeyan ipinlẹ Oyo pe maa sisẹ ju ti tẹl lọ.
Maa si mu ere ati mudunmudun ijọba wa fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.”
Gomina Seyi Makinde wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati mase bẹru nipa ihuwasi rẹ ni saa keji.
O ni gbogbo awọn afojusun oun fun ipinlẹ Oyo lo wa ni akọsilẹ ninu iwe atọnisọna fun idagbasoke to fẹsẹ mulẹ fun ipinlẹ Oyo lati ọdun 2023 si 2027, ti oun gbe jade lasiko ipolongo ibo fun saa keji naa.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Makinde wa fi ọwọ gbaya pe ijọba oun yoo maa se odiwọn awọn aseyọri rẹ lọdọọdun lati ri daju pe oun mu awọn afojusun naa sẹ.
Bakan naa lo wa safihan igbagbọ to ni ninu Ọlọrun ọba lati fun ẹda ni ọgbọn ati agbara lati se amusẹ awọn afojusun to ba gbe kalẹ.















