Rape Castration: Ìpínlẹ̀ Bauchi láwọn náà fẹ máà tẹ àwọn afipábánilopọ̀ lọ́dàá bíi ti Kaduna

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bauchi State Government
Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed ti sọ pe awọn yoo ṣagbeyẹwo ofin to n daabo bo awọn eeyan lọwọ ifipabanilopo nipa fifi ijiya titẹ lọda jẹ awọn ọdaran afipabanilopọ.
O fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n gbalejo Minisita feto ọrọ Obinrin ni Naijiria, Paulen Tallen nile ijọba Bauch lỌjọbọ.
Bi ọrọ yi ba di ootọ, Bauchi yoo pẹlu ipinlẹ Kaduna to kede laipẹ yi pe awọn yoo fi ijiya titẹ lọda jẹ awọn afipabanilopọ.
- Ìdí rèé tí mi ò fi yọjú sí ìgbìmọ̀ àjọ PFN- Fatoyinbo
- Ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀ di kàyééfì lásìkò yìí; ọwọ́ tẹ àwọn kan ní Ekiti
- Obìnrin kan rèé tó sọ ìrírí rẹ̀ lẹ́yìn tí ọkùnrin mẹ́ta fipá báa lòpọ̀
- Iyabo Ojo, Toyin Abraham, Mercy Aigbe, ta làwọn òṣèrébìnrin yìí gbè lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀?
- Ìfipábánilòpọ̀ kìí ṣe ìwà ọmọlúwàbí, àwọn òṣèré tíátà pariwo síta
- Ìdájọ́ ikú ni a fẹ́ fún àwọn afipábánilòpọ̀ - Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn
Yatọ si awọn mejeeji yi, ipinlẹ Ekiti naa lọna ati dẹkun iwa ibajẹ yi sọ pe awọn naa yoo tẹ afipabanilopọ lọda ni ipinlẹ ọhun.
Gomina Bala Mohammed ni awọn ti ṣaaju buwọlu ofin to n daabo bo awọn eeyan lọwọ iwa ipa to si ni awọn yoo fi atunto ofin naa sọwọ sile aṣofin ipinlẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bauchi State Government
''Lawọn ibi ta baa ri pe ofin yi ku diẹ kaato, awa naa yoo ṣatunse rẹ bi Kaduna ti ṣe ṣe ti wọn''
O ṣalaye pe ''A o fi aye silẹ ki titẹ lọda wa ninu ofin wa gẹgẹ bi ijiya ifipabanilopọ''
Mohammed ni oun mọ pe titẹle ofin yi le fẹ le diẹ ṣugbọn awọn yoo ṣe ni ibvamu pẹlu aṣa ati iṣẹṣe awọn eeyan Bauchi.
Mo tun fi kun un pe awọn yoo ṣe agbekalẹ igbimọ alaṣẹ ti yoo mojuto ọrọ titete fi ọmọ lọkọ.
O ni awọn onimọ ẹsin yoo wa ninu igbimọ yi.
Ninu ọrọ tirẹ, Minisita feto obinrin, Paulen Tallen ṣapejuwe ifipabanilopọ gẹgẹ bi iwa ipaniyan to lagbara.
- Wike, má gbé jàgídíjàgan wá sí Ondo, APC kò ní ṣ'èèrú nínú ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀- Kalejaye
- Èèmọ̀! Àwọn adigunjalè yabo ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n fipá bá obìnrin kan lòpọ̀, wọ́n yìnbọn fún òmíràn
- Kọ́ sí i nípa àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kí Aláboyún máa jẹ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arábìnrin tó fẹ́ ta alòkù kọ́ńdọ́ọ̀mù 324,000 padà f'áwọn èèyàn
- Mo ṣetán láti ṣe Paulo Costa bí ọṣẹ sẹ ń ṣojú lọ́la- Israel Adesanya















