Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

Lootọ iwa ifipabanilopọ ko ṣẹṣẹ maa waye, koda awọn kan tilẹ n sọ wi pe atigba iwaṣẹ lo ti n ṣẹlẹ.

Amọṣa awọn iran de iran gbogbo lo ti bẹnu atẹ lu u.

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii ko tii dẹkun, koda ti ẹnu lọwọlọwọ yii wa peleke sii paapaajulọ lorilẹede Naijiria.

Laarin oṣu kan sẹyin ko din ni omidan mẹrin ti awọn oniṣẹ ibi kan ti fipabalopọ ti wọn si tun gbẹmi wọn eleyii to mu ki ohun awọn eeyan tun goke sii lori ipe fun wiwojuutu si wahala ifipabanilopọ lawujọ wa.