#JusticeforTina: Ọmọ mi ṣèlérí pé òun yóò tọ́jú mi tó bá parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ti pá - ìyá Tina
Awọn ẹbi Tina Ezekwe to di ologbe lẹyin ti ọlọpaa kan yinbọn lu lagbegbe Iyana Oworo ni ipinlẹ Eko ti bẹ ijọba lati ṣewadii bi ọmọ wọn ṣe ku laipe ọjọ.
Tina jẹ Ọlọrun nipe ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2020 lẹyin ti ọlọpaa ọhun to ni oun ti mu ọti yo yibọn lu u ni igba to n gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu awakọ kan to tapa sofin igbele to wa nita lasiko naa nitori itankale ajakale arun Coronavirus to n ba agbaye finra.
Iṣẹlẹ naa da họwuhọwu silẹ lori itakun ayelujara ti ọpọ ọmọ Naijiria si n bere fun iwadii kikun ati idajọ ododo pẹlu ami #JusticeforTina.
- Èèyàn 328 tuntun míì ló lùgbàdì àrùn Coronavirus lọ́jọ́ Ẹti ní Naijiria
- Ìlànà tí ìjọba Eko gbé kalẹ̀ fún ìjọsìn lásìkò Covid-19 kò bá wa lára mu - Chris Okotie
- Ìyá àádọ́rin ọdún sọ bí ọkùnrin ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ṣe fipá bá lòpọ̀
- Saudi Arabia ti bèrẹ̀ sí ń ṣí àwọn Mọṣalaṣi rẹ̀ tó kù padà lẹ́yìn ìséde Covid 19 pèlú òfin
Inu ibanujẹ ọkan ni iya Tina wa nigba ti ikọ ileeṣẹ iroyin BBC ṣe abẹwo sile awọn obi rẹ.
Koda, iya Tina kọ lati jẹun, ni ṣe lo ṣa n pariwo Tina mi o, Tina mi o.
Ẹ wo fido yii fun ẹkunrẹrẹ.