Chris Okotie: Ìlànà tí ìjọba Eko gbé kalẹ̀ fún ìjọsìn lásìkò Covid-19 kò bá wa lára mu

Chris Okotie

Oríṣun àwòrán, @churchtimesng

Oludasilẹ ile ijọsin Household of God Church, Chris Okotie ti tako awọn ilana ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ ki wọn to le si awọn ile ijọsin pada.

O fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan to si sọ pe, imusẹ asọtẹlẹ inu bibẹli ti n waye bayi ati pe sise atunto ilana ijọsin sọọsi dabi ki eeyan kọdi iwọ ijọsin f'Ọlọrun.

Lọjọbọ ni ijọba Eko kede pe awọn eto ijọsin yoo bẹrẹ lawọn ile ijọsin pada.

Wọn ni awọn Musulumi yoo le ma jọsin pada lawọn mọsalasi lati ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹfa, nigba ti awọn Kristẹni yoo bẹrẹ ti wọn ni ọjọ Kọkanlelogun osu kan naa.

Ba kan naa ni wọn gbe awọn ilana kan kalẹ ti yoo mu ki sisi awọn ile ijọsin yi lọ ni irọwọrọsẹ nipa didẹkun itankalẹ arun Covid-19.

Ninu rẹ ni wọn ti sọ pe wiwọ ibomu di dandan ati pe awọn ti ọjọ ori wọn ko ba to ọdun mẹẹdogun tabi ti o kọja ọdun marundinlaadọrin ko ni le ba wọn kopa ninu ijọsin.

Chris Okotie

Oríṣun àwòrán, HouseHold of God Church

Àkọlé àwòrán, Okotie sọ pe bi iparun ti se ba Dagoni to jẹ ọlọrun awọn Philistini ni Coronavirus naa yoo ti se parẹ

Bẹẹ naa ni wọn laa kalẹ pe akojọpọ ijọsin ko gbọdo ju wakati kan lọ.

Nigba to n se itọka lati inu bibeli, Okotie sọ pe bi iparun ti se ba Dagoni to jẹ ọlọrun awọn Philistini ni Coronavirus naa yoo ti se parẹ.

O ni toun ti bi ile ijọsin oun ti se n duro de ki arun yi parẹ awọn ko ni ti ilẹkun ile ijọsin awọn pa ''titi ti ọba ọrun yoo fi pa gbogbo awọn ẹsẹ aye yi rẹ''

Àkọlé fídíò, #JusticeforTina: Àwọn obi Tina Ezekwe ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo pẹ̀lú omijé lójú