Akinyele local government: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti mú àwọn afurasí lórí ìpànìyàn tó wáyé

Oríṣun àwòrán, @NSEupdate
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyo ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi kan ni Ibadan lori iṣekupani Akinyele.
Awọn agbofinro fẹsun kan awọn afurasi yii pe wọn lọwọ ninu ipaniyan to waye lagbegbe Akinyele ni ilu Ibadan.
Olubadamọran pataki fun gomina Seyi Makinde, Fatai Owoseni lo kede ọrọ naa nibi ipade ita gbangba to waye ni Akinyele, eyi ti ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ kan gbe kalẹ.
Owoseni sọ pe ileeṣe ọlọpaa yoo fi awọn afurasi naa lede laipẹ.
- Ilé aṣofin Ondo fọwọ́ òsì júwe ilé fún aṣòfin mẹ́ta pé wọ́n tàpá sí òfin ilé
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Magu àti awọn alága EFCC míràn ṣe bá ìtìjú kúrò nípò
- Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń bèèrè owó lọ́wọ́ àwọn Alfa lórí ìsìnkú ẹni tó pokùnso
Owoseni ni "Gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ko si ilu ti ko si ofin tabi ẹṣẹ, mo fẹ fi da a yin loju pe ọwọ ti tẹ awọpn ọdaran to n gbẹmi eeyan ni Akinyele."
O tẹsiwaju pe ẹni to wa nidii ọrọ naa ti mu awọn agbofinro lọ si ọdọ awọn to fi eeyan joogun ati pe wọn ti wa ni atimọle.

Oríṣun àwòrán, @247NNU
Ni ti eto aabo ilu, Owoṣeni sọ pe iṣẹ gbogbo eeyan ni eto abo ilu jẹ, lẹyin naa lo sọ fun awọn eeyan naa pe ki wọn mu eto abo ara wọn lọkunkundun nitori oju ni alakan fi n ṣọri.
Ko din ni eeyan marun un ti wọn ti da ẹmi wọn legbodo lagbegbe Akinyele laarin oṣu Karun un si oṣu Kẹje ọdun 2020.
Ṣaaju ni ileeṣẹ BBC Yoruba ti jabọ pe wọn pa alaboyun kan ti wọn fi okuta fọ lori lagbegbe ọhun, yatọ si awọn eeyan miran ti wọn ti pa lagbegbe naa.
- Wọ̀nyí ni àwọn ẹjọ́ tó làmìlaaka ti EFCC ṣe lásìkò Ibrahim Magu
- Fọwọ́ kan obìnrin lọ́nà àìtọ́, kí o rẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá he- Àwọn aṣòfin yarí
- Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
- Ẹ̀yin ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tẹ fẹ́ ṣe àjọ̀dún lónìí, lákọ la ń dúró dè yín - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Ṣaaju ni Ajafẹtọ ọmọniyan kan ti fẹsun kan ọlọpaa ipinlẹ Oyo pe wọn ko ṣe to bo ti yẹ.
Àwọn ọlọ́pàá kò kọbiara si ọ̀rọ̀ ìwà ipá lásìkò ìgbéle Covid -19 ni ìwà ipá ṣe pọ̀ - Ajàfẹ́tọ obìnrin
Àwọn ọlọ́pàá kò kọbiara si ọ̀rọ̀ ìwà ipá lásìkò ìgbéle Covid -19 ni ìwà ipá ṣe pọ̀ - Ajàfẹ́tọ obìnrin
Láti ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìròyìn aburu nípa ìwà ipá nínú ilé àti ifipábánilòpọ̀ ti n peléke síi lágbàyé tí kò sì yọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ pẹ̀lú.
Èyí tó burú jùlọ níbẹ̀ ni pé, ní ọ̀pọ̀ ìgbá tí àwọn oníṣẹ́ nla ibi yìí bá bá àwọn ènìyàn yìí lòpọ̀ tipatipa tán, wọ́n a tún dá ẹ̀mí wọ́n légbodò.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mú kí BBC News yoruba ṣe ìwádìí ǹkan ti ó fàá tí àwọn ǹkan wọ̀nyìí fi ń peléke síi lójoojúmọ́.
Iṣẹlẹ to ṣaaju ariwo ifipabanilopọ:
Ojúmọ́ ọjọ́ kan lọ́sẹ̀ bíi méjì sẹ́yìn ni òkìkí kàn pé ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdun méjìlélógun kan Vera Omozuwa to jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni ilé iwé Uniben l'àwọn kan fipá bá lòpọ̀.
Ninú ilé ìjọsìn lásìkò tó lọ kàwé níbẹ̀ ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ti wọ́n sì tún pa á sibẹ̀.
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọdọ́ àti àwọn ajàfẹ́tọ ọmọniyan ló tú sigboro láti fẹ̀hónú hàn lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bí eléyìí ṣe n lọ lọ́wọ́ ní òmíràn tún ṣẹlẹ̀ ni ìlú Ibadan to tun di ariwo ikunlẹ abiyamọ.
- Kò ní sí ayẹyẹ ọdún Ojúde Oba lọ́dún yìí- Awujale ilẹ̀ Ijebu
- Wọ̀nyí ni àwọn ẹjọ́ tó làmìlaaka ti EFCC ṣe lásìkò Ibrahim Magu
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
Nígbà ti àwọn amòokùnṣìkà yìí tún bẹ́ sílé àwọn Barakat Bello tí wọ́n fípa ba ọmọ ọdún méjìdínlógún ọ̀hún lòpọ̀ nínú balùwẹ̀ ilẹ́ wọ́n tí wọ́n sì tún pa a síbẹ̀.
Èyí ni à n sọ lọ́wọ́ tí omíràn tún sẹ̀lẹ̀ nílùú Ibadan kan náà sí Azizat Somuyiwa eni ọdún makàndínlọ́gbọ̀n lágbàgbè Ijefun ni Moniya.
Ìròyìn sọ pé àwọn oníṣẹ́ ibi náà fọ òkúta mọ ọmọbinrin náà lórí ní idáji ọjọ karùn-ún, oṣù kẹfà bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ikú tirẹ jẹ mọ ìfinirúbọ̀ ní gẹ́gẹ bi àwọn ọlọ́pàá ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, others
Kò tán síbẹ̀, Nípìnlẹ̀ Ondo, ọkùnrin kan ti wọ́n ń pè ni Oniya lo sá ìyàwó rẹ̀ yánayàna nítori pe ìyàwó rẹ̀ kọ ìbálòpọ̀.
Obìnrin ọ̀hún ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Monisola Adeola ní ọkọ òun kò ṣẹ̀ṣẹ̀ má a lu òun lóri àwọn ǹkan ti kò nílárí, sùgbọ́n orí kó Monisola yọ nítóri kò bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn kí wọn tó gbà á sílẹ̀
Ọ̀kan nínú àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ obìnrin tó tún jẹ́ agbẹjọ́rọ̀ Toyin Taiwo Ojo tó bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀ jẹ́rìí sí pé ọ̀rọ̀ ìwà ipá ni àwujọ Nàìjíríà ń peléke síi lásìkò ìgbélé Coronavirus.
Kini a le sọ pe o fa eyi lasiko yii?: Minista fun ọrọ obinrin fesi pe:...
Arabinrin Pauline Tallen to je minista fun ọrọ obinrin ni Naijiria ti ni Isede konile-o-gbele lati dekun itankalẹ ajakalẹ arun Covid 19 lo faa.
O sọ eyi nibi ipade nile ijọba ni Abuja lasiko to n jabọ lori iṣoro ifipabanilopọ to n fẹju kaakiri Naijiria bayii.
O ni ọna abayọ ni ki gbogob ẹka eto idajọ ati agbofinro ati ara ilu dide papọ lati gbogun ti iwa buruku yii.
Loju àwọn agbẹjọro n kọ?
Amòfin Ojo ní ọ̀pọ̀ ǹkan lo fá idí ti èyí bi pọ̀, sùgbọ́n èyí to ga jùlọ níbẹ̀ ni pé, àwọn ọlọ́pàá kò ṣiṣẹ́ lásìkò kónílé-ó-gbéle nínú oṣù kẹrin ki wọ́n tó dẹwọ́ rẹ̀ silẹ̀.
Ajàfẹ́tọ́ obìnrin náà sọrọ lori iriri rẹ ni ọ̀pọ̀ ìgbà gẹ́gẹ́ bi amofin tí ẹjọ́ bá de àgọ́ ọlọ́pàá ti ọ̀rọ̀ náà sì jẹmọ́ ọ̀rọ̀ ipá nínú ilé ati iwa awọn agbofinro lori iru ọrọ bẹẹ.
O ni àwọn ọlọ́pàá maa n sọ fún àwọn ènìyàn wọ́nyìí pé ki wọ́n padà wá lẹ́yìn ti aàrùn Coronavirus ba ti kásẹ̀ nilẹ̀, tábi kí wọ́n lọ yànjú rẹ̀ nílé.
"Ẹ lọ yànjú rẹ̀ nílé, ọ̀rọ̀ obìnrin ní, Coronavirus wà níta, a kò le mú ẹnikẹni si agọ wá báyìí, ẹ padà wá ti Coronavirus ba pari."
Amòfin Ojo ní ǹkan tí àwọn ọlọ́pàá ń ṣe yìí ló fún àwọn ènìyàn burúkú yìí lágbára láti maa ṣiṣẹ́ ibi lásìkò Coronavirus.
O fi kún pé, àwọn ilé ẹjọ́ pẹ̀lú kò ṣíṣẹ nítori náà àwọn to yẹ kó kúrò lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá lọ silé ẹjọ́ náà ko le kúrò níbẹ̀.
Kíní ǹkan tó wọ́pọ̀ láàrín àwọn tó máa n lo ìwà ipá?
Amòfin Ojo sàlàyé pé láti ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ti òun ti ń bá àwọn tí wọ́n kojú ìwà ipá nínú ilé ṣiṣe òun ṣàkíyèsí pé ìtàn wọ́n máa n jọra.
O ní ọ̀pọ̀ awọn tó n lo ìwà ipá sábà máa fi àwọn àmìn yìí hàn:
- Wọ́n maa n fẹ ki obìnrin tàbí ọkùnrin náà jẹ tíwọn nìkan
- Wọ́n máà ń ṣọ ẹnìkejì wọ́n lọ́wọ́ lẹ́ṣẹ̀, yàlá, fóònù rẹ̀ àti ibi to n rì sí
- Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ti le ẹbí kúrò lára ẹni náà, òun ni yóò maa sọ irú ọ̀rẹ́ tí ó gbọdọ ni fún pẹ̀lú
O ní lẹ́yìn tí o bá ti ṣe àṣeyọri lórí àwọn ǹkan wọ́nyìí ni yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yọ́wọ́ ìwà.

Oríṣun àwòrán, Twitter/aduke
A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kíkún nípa àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Barakat Bello - Iléeṣẹ́ ọlapàá
Justice For Barakat: A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí kíkún nípa àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Barakat Bello - Iléeṣẹ́ ọlapàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ti gbe iwadii ọrọ Barakat Bello ti wọn pa lẹyin ti wọn fi ipa ba a lopọ tan lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ to n ri si iwa ọdaran, CID, ni ilu Ibadan.
Alukoro ileeṣẹ naa, Olugbenga Fadeyi lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.
O ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii ni kikun lori ohun to fa iṣẹlẹ naa ati idi ti wọn ṣe gba ẹmi ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni bo tilẹ jẹ pe wọn tete sin oku ọmọbinrin naa ki iwadii to bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, awọn agbofinro yoo tu iṣu de isalẹ ikoko bi ọrọ ọhun ṣe jẹ.
Fadeyi tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ko ni sinmi titi di igba ti yoo fi oju awọn oniṣẹ ibi ọhun lede.
Lẹyin lo rọ awọn eeyan to n gbe lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti nipa ohunkohun ti wọn ba mọ tabi ẹni ti wọn ba fura si lọna ati lee jẹ ki wọn pari iwadii naa lai fi akoko ṣofo.
Ọjọ iṣẹgun, ọjọ keji oṣu kẹfa ni awọn amokun-ṣeka wọle tọ Barakat Bello lagbegbe Akinyele, ni ilu Ibadan, ti wọn si gbẹmi rẹ lẹyin ti wọn fi ipa baa lopọ tan.
Èyí làwọn ohun tí a mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Barakat Bello, táwọn kan fipá bálòpọ̀ ní Ibadan

Ni ọjọ Iṣẹgun ni okiki iroyin kan kaakiri igun mẹrẹẹrin orilẹede Naijiria nipa iku omọdebinrin kan tawọn kan gba ẹmi ẹ lẹyin ti wsn fi ipa baa lo pọ.
Oniruuru iroyin lo si ti waye lori rẹ ti ọpọ awọn eekan si ti n ke sawọn agbofinro lati tete fi oju awọn aṣebi to ṣiṣẹ naa sita.
Amọṣa titi di bi a ṣe n sọrọ yii, diẹ lara awọn ti a mọ nipa iṣẹlẹ iku rẹ niyi:
- Awọn ẹbi oloogbe naa ṣalaye pe, ni iwoye wọn ọrọ iku rẹ, bi iku ile ko ba pani tode ko lee pani ni ọrọ ọhun.
- Iwẹ ni arabinrin naa fẹ lọ wẹ pẹlu iro nigba ti awọn oniṣẹ ibi naa kaa mọ ti wọn si ṣe isẹ ibi naa.
- Arabinrin naa japoro iku titi ki o to de; ki awọn eeyan to raye de ọdọ rẹ lo ti dagbere faye ninu agbara ẹjẹ.
- Awọn obi rẹ ni awọn gbẹri rẹ jẹ gẹgẹ bi smọ ti kii rin irinkurin.
- Barakat ni akọbi fun awọn obi rẹ, ọmọ meji si ni awọn obi rẹ bi.

Justice For Barakat: Nítòsí balùwẹ̀ ni wọ́n ti bá Barakat nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n fipá báa lòpọ̀- Ìyá Barakat
Ati ẹbi ati awọn aladugbo lo pejupesẹ lati kẹdun arabirin Barakat Bello, ọmọ ọdun mejidinlogun ti awọn oniṣẹ ibi kan gba ẹmi rẹ lẹyin ti wọn fi ipa baa lopọ lọjọ Iṣẹgun.
Lẹyin ti ijọba apapọ paṣẹ wi pe ki awọn ile ẹkọ di titi pa ni Barakat kuro ninu ọgba ile ẹkọ ti a ti n kọ nipa ilera ohun ọsin ati ohun ọgbin, "Federal College of Animal Health and Production", ni agbegbe Apata nilu Ibadan gẹgẹ bi akẹkọọ to n bẹ ni ipele akọkọ.
Adugbo Oloro ni agbegbe Akinyẹle nilu Ibadan ni Baraka n gbe pẹlu awọn obi rẹ lati igba naa.

Iya oloogbe Barakat, Arabinrin Kafayat Bello ba ikọ BBC Yoruba sọrọ lasiko ti a ṣe abẹwo si ile wọn lowurọ Ọjọru.
Arabirin Kafayat ni Baraka ati aburo rẹ ọmọkunrin ẹni ọdun bii meje si mẹjọ ni wọn fi silẹ ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Wọn ni lẹyin asiko diẹ ni aburo ti o jẹ ọkunrin jade lọ ra nnkan ti o si ku oloogbe nikan sile.
Igba ti aburo to jade lọ yoo fi pada sile ni o dede kan ẹgbọn rẹ ninu agbara ẹjẹ ni itosi baluwẹ wọn to n bẹ ni ẹyinkunle.

Ariwo ọmọkunrin naa lo jẹ ki o han si gbogbo aladugbo wi pe ọfọ ti ṣẹ.
Ike omi meji ti oloogbe pọn lati fi wẹ ṣi wa lẹgbẹ baluwẹ naa titi di asiko yii pẹlu ami agbara ẹjẹ oloogbe.

Lẹyin o rẹyin ni wọn kẹsi ọlọpaa ti ayẹwo iṣegun ṣi fihan nipa iku gbigbona ni oloogbe ku lẹyin ti wọn fi ipa baa lopọ tan.
Iya baraka ṣe apejuwe ọmọ rẹ ti di oloogbe gẹgẹ bii eyin ọọkan ati ogo idile ti oun ati baba rẹ n reti wi pe yoo tọju awọn ati aburo rẹ titi dọjọ alẹ.

O ni oun bẹ Ọlọrun lati fi oju aṣebi han ki o to di ọjọ meje.
Ẹgbọn iya oloogbe ti o ba wa sọrọ, Arakunrin Ọlalẹyẹ Dauda ni Baraka nikan lo le ṣe alaye bi ẹmi ṣe bọ lọrun oun.
Dauda sọ wi pe ọgbẹ ọkan nla ni iku ọmọbinrin naa da silẹ nitori o jẹ daadaa ti gbogbo eeyan fẹran nigba aye rẹ.
Lọjọ ti Baraka ku naa ni wọn sinku rẹ ni ilana ẹsin Islam.
Lọwọlọwọ bayii, ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori awọn olubi ẹda to da idile naa loro.
Justice For Barakat: Aráàlú tún fọnmú lori ọmọbìnrin míì ti wọn pa lásìkò ìbálòpọ̀ tipá

Oríṣun àwòrán, Twitter/aduke
Iroyin kan to n gbona loju opo ikansiraẹni Twitter ni aarọ Ọjọru lo n beere fun idajọ lori iku to pa omidan Barakat Bello.
Barakat, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ imọ nipa itọju ẹranko (Federal College of Animal Health and Reproduction) la gbọ pe o n gbe lagbegbe Akinyele nilu Ibadan, níbi ti awọn gende kan ti fipa baa lopọ, ki wọn to gbẹmi rẹ.
Barakat, ẹni taa gbọ pe wọn ti sin, ni ọpọ eeyan lori ayelujara wa n beere pe ki awọn agbofinro ṣe awari awọn to fi tipa ba lopọ, ti ẹmi rẹ fi bọ.
Iroyin naa ni ọmọdebinrin naa, tii ṣe ẹni ọdun mejidinlogun, to maa n da aṣọ hijab bori bii musulumi ododo, ni baba rẹ ba oku rẹ ni ayika ile wọn, ti wọn si sawari rẹ pe awọn ọkunrin kan lo fi tipa baa lopọ.
A gbọ pe ẹgbẹ awọn akẹkọọ nile ẹkọ giga nilẹ wa ti n figbe bọnu pe ki ìjọba tan ina wadii iku to pa omidan naa to jẹ ọkan lara wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bẹẹ ba si gbagbe, irufẹ iṣẹlẹ ifipabanilopọ yii ti waye laarin ọsẹ kan sira wọn fun ọmọbìnrin meji miran eyi to n mu ki awọn araalu figbe bọnu.
Ṣugbọn nigba ti BBC Yoruba kan si Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ni iṣẹlẹ naa ko tii de etigbọ awọn agbofinro rara.














