Wo ìtumọ̀ àti pàtàkì ọ̀pọ̀ oyè ẹ̀ṣìn nínú Islam

Oríṣun àwòrán, others
Kii ṣe ohun tuntun rara lati ri apemọ orukọ Alhaji ati Alhaja lẹyin orukọ awọn eeyan to ba ṣẹṣẹ ti ilẹ mimọ hajj de.
Ori ọpọ eeyan si lo maa n wu lati ri pe ẹni kan n jẹ Alhaji ati Alhaja, ti aimọye eeyan miran si maa n lakaka lati lọ si Mecca, ki araye lee maa fi Alhaji ati Alhaja si ẹyin orúkọ wọn.
Ṣugbọn iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti awọn obinrin kan to ti de lati ilẹ mimọ yari loju opo Twitter pe, ki ẹnikẹni mase pe awọn ni Alhaja.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- "Orin Shanku, Gbese, Já paa, Jesu máa párò lọ, inú Ọlọ́run kò dùn sí i - Bola Are
- A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa - Mama Fasoyin
- Pé ó gbà kí ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ bá ọ ní àjọṣepọ̀ kò ní kó fẹ́ ọ - Ṣọla Allyson
- Wo ọmọ ọdun mẹ́tàlá tó ń ta ''Hawaiian guitar'' sí orin Obey, Sunny àti tàkasúfèé
Ọrọ yii ni wọn n gba mọ ara wọn lọwọ ni aarọ ọjọ Ẹti, idi si ree ti BBC Yoruba fi n beere lọwọ onimọ kan nipa ẹṣin Islam pe ki ni itumọ Alhaji ati Alhaja pẹlu awọn oye apemọ orúkọ miran to wa ninu ẹsin islam.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Sheikh Abdulrazak Isola salaye pe, awọn eeyan to n gbero lati lọ si ilẹ mimọ Mecca ni wọn n pe ni Alhaji ati Alhaja, apemọ orúkọ lasan si ni pẹlu.
Isola ni Hajjum tumọ si adisọkan irinajo, Alhajjum si tumọ ẹni to gbero lati rinrin ajo sugbọn lẹyin to ba de tan, Visito abi Sahel, to túmọ̀ si olubẹwo ni wọn yoo pe.
"Ọna lati ṣe ayẹsi awọn eeyan to ti ilẹ mimọ de, ka si tun lee da wọn mọ yatọ si awọn eeyan ti ko tii lọ, ni wọn ṣe n pe wọn ni Alhaji abi Alhaja."
Sheikh Isola tun salaye siwaju lori awọn apemọ orúkọ tabi oye ẹṣin ti ọpọ musulumi n jẹ bii Malam, Alfa, Sheikh, Uztas, Imaam, Amir, Amirah ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, others
Ki ni itumọ ati pataki oye ẹṣin Islam:
Mallam:
Sheikh Isola ni ede Hausa ni Mallam. Muhaleem, ti itumọ rẹ jẹ olukọ, ni wọn sọ di Mallam.
Ṣugbọn o ni ọpọ eeyan lo n ṣe asise lati maa pe awọn Hausa ni Mọla abi Mallam.
Alfa:
Orúkọ miran ta tun n pe Malam ni Alfa, eyi tii ṣe olukọ to mọ keu, to si n kọ ni lẹkọọ rẹ.
Halifu ni ede larubawa tumọ si ẹgbẹrun kan, olukọ to si duro bii eeyan ẹgbẹrun kan ni wọn n pe ni Alfa.
Imaam:
Imaam ti Yoruba n pe ni Lemọmu ni itumọ rẹ n jẹ asiwaju, amọ o pe meji.
Imaamu ti gbogbo ilu pata wa, nigbati Imaamu adugbo kekere naa wa pẹlu.
Ojuse Imaamu ni lati maa sọrọ ẹṣin fun awọn musulumi ati ohun gbogbo ti Ọlọrun fẹ ki wọn ṣe, Imaamu si ni wọn maa n fi eto ẹṣin le lọwọ ni awujọ musulumi.
Imaamu ni ẹni akọkọ ninu ẹṣin islam, oun si ni yoo maa tọ ero ẹyin sọna, eeyan kii si beere lati jẹ Imaamu, wọn maa n fi eeyan jẹ ní.

Oríṣun àwòrán, others
Shehu/Sheikh :
Shehu tumọ si agbalagba, Sheikh si ni kurani n lo fun wọn, oye Shehu abi Sheikh yii si maa n lọ sọdọ ẹni to ba ku ni olori ile tabi ẹni ti imọ, oye abi ẹṣin rẹ pọ.
Ẹnikẹni to ba ti kọja ọgọ́ta ọdun ni wọn n pe bẹẹ
Gẹgẹ bi kurani ti ṣe alaye, Tunfulu ni wọn n pe ọmọde jojolo, ọdọ wa, lati ọdún mẹwa si mẹẹdọgbọn , lẹyin ọdọ lo kan Halum, fun awọn eeyan to kọja ọgbọn ọdún.
Uztas:
Ọjọgbọn ni wọn n pe ni Uztaz. Eyi ko si ninu Alukurani sugbọn o jẹ ara awọn ọrọ to de lẹyin lẹyin ti wọn maa fi n ṣe apejuwe awọn onimọ.
Onimọ ẹṣin nikan kọ ni wọn n pe ni Uztas, onimọ ẹ̀rọ, onirori tabi awọn isẹ to nii ṣe pẹlu imọ ijinlẹ.
Mukadam:
Ipo yii lo wa ni ọpọ ọna kaakiri. O wa ninu isẹ ologun ati ninu ẹsin Sufi.
Mukadam tumọ si ẹni ta to siwaju, ẹni kan lo tii siwaju pe ko maa dari ìjọ eeyan kekere kan, oun naa tun ni ọga.
Khalifa:
Khalifa ni ọga Mukadam, arole Shehu loju ọna ibẹlọrun ati isunmọ Ọlọrun ọba to wa.
Khalifa ni yoo fi Mukadam jẹ.
Amir:
Akọkọ oye lẹyin Anọbi ree, o tumọ si asiwaju abi apasẹ, Amir si ni wọn sọ di Emir.
Amirah si ni asiwaju tabi apasẹ fun awọn obinrin.














