Mercy Aigbe: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́wàá tí kìí ṣe Yorùbá

Oríṣun àwòrán, others
Agbo nla ni ẹka awọn oṣere tiata ni ede Yoruba, ti wọn si ni ogunlọgọ awọn oṣere tiata ti ko see fi ọwọ rọ danu.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn ni ede Yoruba dantọ ni ẹnu wọn lasiko ti wọn ba n ṣe sinima, sugbọn iyalẹnu lo jẹ pe awọn kan wa ninu wọn, ti kii ṣe ọmọ Yoruba.
Diẹ lara awọn ti kii ṣe ọmọ Yoruba ninu awọn oṣere naa ree:
Rachael Oniga:

Oríṣun àwòrán, Rachael Oniga
Bakan naa, agba ọjẹ oṣere tiata ni ede Yoruba ati oyinbo, Racheal Oniga jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Delta.
Gbajumọ oṣere yii, ti ede Yoruba yọ lẹnu rẹ lo wa lati ilu Eku ni ẹkun guusu Delta, to si n fi ede Yoruba sisọ jẹun.
Faithia Williams:

Oríṣun àwòrán, Faithia Williams
Faithia Williams tawọn eeyan mọ si Faithia Balogun tẹlẹ ni oju rẹ wọpọ ninu ere tiata Yoruba.
Faithia, tii ṣe iyawo gbajumọ oṣere miran, Saheed Balogun, ṣe jẹ agba ọjẹ oṣere to dangajia, naa lo tun jẹ adari ati Olootu ere sinima.
Ọmọ bibi ilu Okpara nijọba ibilẹ ila oorun Ethiope, nipinlẹ Delta si ni akikanju oṣere tiata yii.
Doris Simon:

Oríṣun àwòrán, Doris Simon
Ilumọọka oṣere bìnrin alawọ pupa yii lo wa lati agbegbe Okpella ni ẹba ilu Benin.
Obìnrin to n sọ ede Yoruba bii ẹni layin naa si lo ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ lori sinima to ṣe ni ede Yoruba.
Rykardo Agbor:

Oríṣun àwòrán, Rykardo Agbor
Ọmọ bibi ipinlẹ Delta naa ni Rykardo Agbor amọ to gbe ilu Eko dagba.
Yoruba yọ lẹnu gbajumọ oṣere tiata lọkunrin naa debi pe ko si owe ti ko lee pa ninu sinima, to si tun maa n ṣe tiata lede oyinbo pẹlu.
Kelvin Ikeduba:

Oríṣun àwòrán, Kelvin Ikeduba
Ilu Eko ni oṣere tiata yii gbe dagba, ti ede Yoruba si da lẹnu rẹ sugbọn ọmọ bibi ipinlẹ Delta ni oun naa n ṣe.
Agbegbe ẹya Igbo to wa ni Delta lawọn obi Kelvin ti wa, bo si ṣe n sere ni ede Yoruba naa lo n kopa ninu sinima oloyinbo.
Rose Odika:

Oríṣun àwòrán, Rose Odika
Agba ọjẹ pọnbele ni Rose Odika, to si ti di igi araba ninu sinima lede Yoruba bi o tilẹ jẹ pe ẹya miran lo ti wa.
Rose, ẹni to wa lati agbegbe Igbo nijọba ibilẹ Aniocha nipinlẹ Delta, lo tun jẹ gomina fun gbogbo awọn onitiata lede Yoruba nipinlẹ Oyo.
Liz Da Silva:

Oríṣun àwòrán, Liz Da Silva
O loju ẹni to lee gbagbọ pe ọmọbìnrin yii kii ṣe ọmọ Naijiria rara, debi pe yoo jẹ ọmọ Yoruba, ọmọ bibi orilẹ-ede Togo nii ṣe.
Elizabeth Ọmọwunmi Tekovi Da-Silva ni apetan orukọ rẹ, amọ ilu Eko ti wọn bi si lo ṣe iranlọwọ fun lati maa fi ede Yoruba jẹun.
Mercy Aigbe :

Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe
Odu ni Mercy Aigbe ninu awọn sinima ede Yoruba, kii si ṣe aimọ fun oloko rara nitori ẹwa ati ede Yoruba ẹnu rẹ to dantọ.
Ọmọ bibi ipinlẹ Edo ni gbajumọ oṣere tiata naa, to tun jẹ oludari ere sinima ati gbajugbaja oloko-owo.
Toyin Abraham:

Oríṣun àwòrán, Toyin abraham
Toyin Abraham jẹ ẹni taye n fẹ ninu tiata Yoruba, to si ti ṣe ọpọ sinima jade ni ede Yoruba.
Lootọ ni pe ilu Ibadan ti Toyin gbe dagba ṣe iranwọ fun lati gbọ ijinlẹ ede Yoruba amọ ọmọ bibi ilu Auchi nipinlẹ Edo nii ṣe.
Regina Chukwu:

Oríṣun àwòrán, Regina chukwu
Orukọ Regina Chukwu lasan ti to lati fihan pe kii ṣe ọmọ Yoruba, sugbọn ede Yoruba lo fi n jẹun ninu ere tiata lede Yoruba.
Ọmọ bibi ipinlẹ Enugu ni Regina sugbọn ilu Eko lo gbe dagba, to si n fi ede Yoruba dabira ninu sinima.












