Rachel Oniga is dead: Jide Kosoko, Hilda Dokubo, Yomi Fabiyi àtàwọn míì ṣèdárò Rachel Oniga tó lọ

Oríṣun àwòrán, Others
Ọpọ awọn osere ati ololufẹ ogbontarigi oṣere ni Rachel Oniga to jade laye lana ni wọn ti n kira wọn ku ara feraku.
Rachel Oniga to dagbere faye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.Mi kò mọ̀ pé àsìkò yìí ni máa dágbéré fún Rachel Oniga- Jide Kosoko
Jide Kosoko, agba ọjẹ osere naa ti sọrọ sita pe iku Oniga ṣe oun fuu.
O ni oun ko mọ pe ọrẹ bii ọmọ iya yii n dagbere lasiko yii fun oun ni.
- Fúnrara Bukola Saraki ló lọ sí EFCC láti lọ yanjú ọ̀rọ̀ ara rẹ̀- Agbẹnusọ Saraki
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá, ẹ ríi dájú pé ẹ tú gbogbo àṣírí nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Abba Kyari àti Hushpuppi - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀

Oríṣun àwòrán, @Jide Kosoko
Jide Kosoko ni nitootọ ni iku Rachel Oniga dun oun ṣugbọn oloogbe gbe igbeaye to wuni lori pupọ.
O dagbere fun oloogbe to ni o kọja akégbẹ ẹni lẹnu iṣẹ lasan pẹlu ileri pe gbogbo oṣere ni yoo maa ṣranti iṣẹ rere ati ohun maleegbagbe ti akinkanju obinrin yii, Rachel Oniga se silẹ lagbo tiata ko to lọ.
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá, ẹ ríi dájú pé ẹ tú gbogbo àṣírí nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Abba Kyari àti Hushpuppi - Àpapọ̀ Agbẹjọ́rọ̀
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- Fúnrara Bukola Saraki ló lọ sí EFCC láti lọ yanjú ọ̀rọ̀ ara rẹ̀- Agbẹnusọ Saraki

Oríṣun àwòrán, racheloniga
Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Rachel Oniga tó d'ágbére f'áyé
Ìtàn ìgbéayé gbajúgbajà òṣèré, Rachel Oniga tó jáde láyé rèé
Gbajugbaja oṣere tiata, Rachel Oniga ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, Actor's Guild of Nigeria, Emeka Rollas lo fidi iroyin naa mulẹ pe pe lootọ ni oṣerebinrin naa ti jẹ Ọlọrun nipe.
Rolla ni ọmọ oloogbe ọhun sọ fun oun pe oṣerebirin naa dagbere faye ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọgbọn ọjọ, oṣu Keje, ọdun 2021 yii.
Ṣugbọn o fi kun pe oun ko tii le ṣalaye ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa.
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Èyí ni àlàyé lórí ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín
- 'Hàá, irú ikú tí ọmọ mí kú kò tọ́ síi, aláànú mí ní'
- Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu
Wo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Rachel Oniga
- Ọmọ bibi ilu Eku, nipinlẹ Delta ni Rachel Oniga
- Wọn bi i ni ipinlẹ Eko ninu oṣu Karun un, ọdun 1957, lagbegbe Ebute Metta
- O kawe nile ẹkọ Princess Girls School, to wa ni Abule Oja, Yaba, niluu Eko
- Ọlọrun fi ọmọ mẹta ta Rachel lọrẹ ṣugbọn oun ati ọkọ rẹ ko gbe papọ mọ ki ọlọjọ to de
- Awọn eniyan to sọrọ nipa iku rẹ ni o ṣi kopa ninu fiimu ti wọn n ṣe lọwọ ni ọṣẹ yii, ni agbegbe Mowe, nipinlẹ Ogun
- Racheal Oniga wa lati ilu Eku ni ipinlẹ Delta, amọ agbegbe Ebutte Metta ni ipinlẹ Eko ni wọn bi sii.
- O bẹrẹ iṣe ẹ oṣere rẹ ni ọdun 1993, kete to fi igbeyawo rẹ silẹ ni nkan bi ọdun mọkandinlogun sẹyin.
- Ki o to bẹrẹ iṣẹ oṣere, o kọkọ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Ascoline Nigeria Limited.
- Fiimu akọkọ ti o kọkọ kopa ninu rẹ ni Onome ati fiimu Yoruba Owo Blow.
- Awọn fiimu miran to ti kopa ninu rẹ ni Sango, Super Story, "Died Wretched," "The Only Nigerian Girl," "Doctor Bello" ,"The Royal Hotel Hibiscus."The Wedding Party, The Royal Hibiscus Hotel, 30 Days in Atlanta, ati Out of Bounds,
Pupọ ninu awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ.
Lara awọn oṣere naa ni Jide Kosoko to sọ pe oun ṣi ranti gbogbo igba ti awọn mejeji jọ maa n kopa ninu ere bi ana.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
O ni Rachel Oniga kii ṣe akẹgbẹ oun nikan, ṣugbọn o tun jẹ bii ibatan si oun.
Ni ti Hilda Dokubo, o ni bii iya ni Rachel Oniga jẹ si oun, eyii to mu ki iku rẹ jẹ ọgbẹ ọkan fun oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Bakan naa ni Yomi Fabiyi n ṣedaro oloogbe naa nigab to sọ pe awọn memeji ṣi fọrọ jomitooro ọrọ ni ọjọp mẹfa sẹyin.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Yatọ si awọn oṣere tiata, pupọ awọn ololufẹ Rachel Oniga lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajúgbajà òṣèré, Racheal Oniga ti d'ágbére f'áyé
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Igbo ati ede Gẹẹsi, Rachael Oniga ti jẹ Ọlọrun nipe.
Eni ọdun mẹrinlelọgọta ni Oniga ko to jade laye.
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, Actor's Guild of Nigeria, Emeka Rollas ni lootọ ni oṣerebinrin naa ti jade laye.
Rollas sọ fun BBC pe akọwe oun pe ọmọ Racheal Oniga to fi idi rẹ mulẹ wi pe alẹ Ọgbọnjọ, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni iya oun jade laye.
Titi di asiko yii, ko i tii si aridaju ohun to ṣokunfa iku rẹ.
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- Àwọn ohun mẹ́rin tó yẹ kí ẹ ko mọ nípa Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- 'Lábẹ́ òfin àjọ ECOWAS, kó ṣééṣe kí Benin Republic jọ́wọ́ Sunday Igboho fún Nàìjíríà'
- Ikú Tope AjogbaJesu, ohun tí a mọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ nìyí