Sunday Igboho: Agbẹjórò ní kò sí ohun tó jọọ́ pé orílẹ́èdè Benin ń gbèrò láti dá Sunday Igboho padà sílé

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ kan niluu Cotonou lorilẹede Benin paṣẹ pe ki wọn mu Oloye Sunday Adeyemo(Igboho) kuro ni ahamọ ọlọpaa.
Amọ, ile ẹjọ sọ pe ki Igboho si wa ni atimọle ti kii ṣe ti awọn ọlọpaa.
Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho ṣalaye fawọn akọroyin idi ti Igboho yoo fi wa ni atimọle fun igba diẹ.
- ÌṢé lóòtọ̀ ni gbajúgbajà òṣèré, Racheal Oniga ti jáde láyé?
- Evangelist/Dókítà/Oníròyìn Kemi Olunloyo sọ nípa ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun, ESABO, Jide Kosoko àti Iyabo Ojo
- Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle
- A ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹsun ti US fi kan Abba Kyari, Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti pàṣẹ
- Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle
- Àfìgbà tóò dúró ká jọ gbé orin tuntun wa pẹ̀lú Alhaji Mustapha Abiola jáde - Ẹnìkejì Tope Ajogbajesu
Olusegun Falola to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho ni Benin Republic sọ pe ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation wa ni atiimọle lati daabo bo o ni.
Agbẹjọro Falola to jẹ Ọmọwe ninu ofin fikun ọrọ rẹ pe adehun ajọ ECOWAS gan an eyi ti Naijiria ati Benin naa buwọlu daabo bo Igboho.
Falola ni ijọba Naijiria gan an ko fẹsun ọdaran kan Ọgbẹni Adeyemo titi di akoko yii.
''Ofin orilẹede Benin ko faye gba ki eeyan wa ni atimọle ọlọpaa ju ọsẹ kan lọ.
Awọn alaṣẹ ijọba Benin Republic gbagbọ pe fifi Igboho silẹ lasiko ti awuyewuye si n lọ lọwọ lori ọrọ rẹ ni Naijiria ati Benin lewu fun abo rẹ.
Ijọba Benin rii bi ẹni pe Igboho nilo abo labẹ ofin lẹyin titi di igba ti awuyewuye to tẹ le bi wọn ṣe mu un niluu Cotonou yoo fi lọọlẹ.
Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, Igboho ko ṣẹ si ofin kankan lorilẹede Benin.
Koda ko tii lo pe ọjọ kan ni Cotonou ti wọn fi mu un ni papakọ ofurufu ni ọna rẹ si orilẹede Germany.
Igba to tii lo ni Benin Republic kere debi wi pe ko le raye lati gbero ati da wahala silẹ ni Benin.
Awọn agbofinro mu un nitori ọrọ oṣelu lati orilẹede Naijiria ni kii ṣe pe o ṣẹ si ofin nibi.
Igboho si wa lahamọ lati jẹ ki atẹkun fẹ si ọrọ naa ati lati jẹki alaafia jọba laarin Naijiria ati Benin.
Ẹnikẹni to ba sọ pe ki wọn fun Igboho lominira bayii fẹ gba ẹmi rẹ ni, nitori wọn le ṣeku pa a,'' Falola lo sọ bẹẹ
Lori akoko ti igbẹjọ yoo tun waye nile ẹjọ, agbẹjọro Falola sọ pe awọn adajọ lo le sọ igba ti ẹjọ naa yoo tun gberasọ.
O fikun ọrọ rẹ pe ko ṣeeṣe ki Benin jọwọ Igboho fun Naijiria lori ẹsun pe o n pe fun iyapa ẹya Yoruba lara Naijiria.
















