Mysterious palm tree with 42 heads: Ọ̀pẹ Umalẹ̀ tàbí olórí yéye tó ń ṣ'àmín s'ádurà àwọn èèyàn

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Bẹẹ ba n gbọ Ọpẹ Umalẹ, Ọpẹ olori yeye, ẹ ma sa lọ, ẹyinkunle yin nibi lo wa o.

Kayeefi BBC ti oṣu yii gbe wa lọ si inu igbo aramanda kan to wa ni ilu Ilogbo ni ipinlẹ Ekiti nibi ti igi ọpẹ to ni ori to le ni ogoji wa.

Awọn ara ilu naa sọ fun akọroyin Kayefi BBC Yoruba pe awọn gbagbọ pe igi abami yii ti wa ko tilẹ to di pe wọn tẹ ilu naa do ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin.

Igi ọpẹ olori mejilelogoji
Inu igbo ti igi ọ̀pẹ naa wa

O le lati gbagbọ amọ iṣẹ aramanda ọwọ Eledumare to fi ṣa sababi fun wa ni Ilogbo ni. Kabiyeis Owalogo ti ilu Ilogbo Ekiti sọ bẹẹ.

Nibayii igi naa ti di Ooṣa pataki ni ilu Ilogbo Ekiti gẹgẹ bi awn agba awo ṣe sọ pe awọn ti awọn tẹ ilu naa do gan baa nibẹ ni.

"Beeyan n jiya ọmọ, to ba de ibẹ, yoo ri ọmọ bi".

Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb