Ìjoba fìyà jẹ el-Zakzaky lọ́nà àìtọ́, ṣùgbọ́n a fa gbogbo rẹ̀ lé Ọlọrun lọ́wọ́ - Islamic Movemnent of Nigeria

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ awọn Musulimi, Islamic Movemnent of Nigeria ti sọ pe lootọ ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari fiya jẹ aṣaaju awọn, Sheikh Ibrahim El-zakzaky, ṣugbọn awọn fa gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ.Agbenusọ ẹgbẹ naa, Ibrahim Musa lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan.O ni inu awọn dun pe ile ẹjọ ti tu El-zakzaky silẹ ninu ọgba ẹwọn to wa bo tilẹ jẹ pe o ti lo nnkan bii ọdun mẹfa ni ahamọ ọhun, toun ti iyawo rẹ.O ṣalaye pe ẹgbẹ awọn gẹgẹ bi Shia ko tii ṣe ipade lati lori irufẹ igbesẹ ti awọn yoo gbe nitori bi awọn yoo ṣe tọju rẹ lo gogo lọkan awọn lọwọ yii.Ibrahim ni o ṣeeṣe ki awọn pe ijọba apapọ lẹjọ lati san owo gba mabinu lori iya to fi jẹ adari awọn, ṣugbọn awọn ṣi fẹ ṣetọju bayii na.
- Mo gbà pé mo jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn wíwọ́ké àti kíkó owó pamọ́ lọ́nà àìtọ́ - Hushpuppi
- A kò bèrè fún owó kankan lọ́wọ́ Hushpuppi - Abba Kyari dá èsì padà fún ileẹjọ́ US
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Oríire ńla ni ìdájọ́ El-Zakzaky jẹ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - IMN
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ẹgbẹ́ illuminati lè sọ èèyàn di olówó? Ohun méjìlá tí a mọ̀ rèé
- Ilé ẹjọ́ ti dá Ibrahim El-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
- Ẹbí gba ẹ̀mí ọmọdébìnrin kan nítorí ó wọ ṣokoto "jeans"
- Kí ni Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai ń ṣe ní Benin Republic, ìlú tí Sunday Igboho ti ń jẹ́jọ́?Gẹgẹ bii oun to sọ, o ni awọn agbofinro ti tẹ ẹtọ El-zakzaky loju mọlẹ ofin bi wọn ṣe tii mọle lẹyin ti awọn ẹlẹri bii marundinlogun ti ijọba apapọ ko lọ sile ẹjọ ko ri ẹsun Kankan ka sii lẹsẹ ṣaaju. Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2021 yii ni ile ẹjọ kan ni Kaduna tu adari ẹlẹsin Musulumi naa ati iyawo rẹ silẹ ninu ẹwọn lẹyin to ni awọn mejeji ko jẹbi ẹsun ti ijọba ipinlẹ ọhun fi kan wọn.Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2015 ni wọn fi panpẹ ọba mu El-Zakzaky lẹyin ti awọn ọmọlẹyin rẹ kolu awọn ikọ ọmọogun Naijiria niluu Zaria, iyen nipinlẹ Kaduna.Agbẹjọro El-Zakzaky, Sadau Garba ṣalaye pe ileẹjọ tu wọn silẹ lẹyin ti wọn da gbogbo ẹsun onigun mẹjọ ti ijọba ipinlẹ Kaduna pe mọ wọn nu.''Ileẹjọ ni awọn ẹsun naa ko fi ẹsẹ mulẹ''Sadau ni bawo ni ileẹjọ yoo ṣe fi ẹsun kan awọn eeyan lọdun 2015, ti wọn si ṣẹṣẹ gbe ofin kalẹ lori ẹsun naa ni ọdun 2017.Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ ijọba ipinlẹ Kaduna lo fẹsun kan El-zakzaky ati aya rẹ, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo wa nidi gbogbo igbesẹ naa.
Wo iye èèyàn tó dèrò ọ̀run lásìkò ìkọlù ẹgbẹ́ Shi'ite àti àwọn agbófinró

Oríṣun àwòrán, AFP
Lẹyin ọ rẹyin, Ile ẹjọ giga kan nipinlẹ Kaduna, ti da Olori ìjọ ẹsin Isilaamu Shia, Islamic Movement of Nigeria, Ibrahim El-zakzaky ati iyawo rẹ, Zeenat silẹ pe ki wọn maa lọ ni alaafia.
El-zakzaky ati iyawo rẹ ti n jẹjọ lori ẹsun to ni i ṣe pẹlu idaluru ati kikorajọpọ lọna ti o tapa si ofin.
Amọ, ile ẹjọ ti yi gbogbo awọn ẹsun naa ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan wọn danu bayii.
Ọdun 2015 ni ijọba mu El-zakzaky lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ijọ rẹ ati awọn ọmọ ogun Naijiria nilu Zaria.
Ọpọ igba lawọn ọmọlẹyin El-zakzaky ti ṣe iwọde eleyii ti wọn fi n beere fun itusilẹ olori wọn ati iyawọ rẹ.
Ọpọ awọn ifẹhonuhan yii lo mu ẹmi lọ nigba ti ọpọ eeyan si farapa yana yana.
Wọnyii ni awọn iṣẹlẹ buruku to ṣẹlẹ lasiko iwọde ẹgbẹ musulumi Shi'ite ni Naijiria.
Ọpọ ẹmi sun lọdun 2015 lẹyin ikọlu laarin ẹgbẹ Shi'ite ati ile iṣẹ ologun
Rogbodiyan bẹ silẹ nigba tawọn musulumi Shi'ite to n ṣe iwọde loju popo niluu Zaria nipinlẹ Kaduna kọlu awọn ọmogun to n kọwọ rin pẹlu ọga ọmogun oriilẹ, Tukur Buratai.
Ileeṣẹ ologun ni awọn musulumi Shi'itẹ di ọna mọ awọn ọga ologun to n kọja.
Ẹgbẹ Shi'ite fẹsun kan ileeṣẹ ologun oriilẹ Naijiria pe o yinbọn pa ọmọ ẹgbẹ awọn to le ni ọgọrun.
Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ni awọn ẹgbẹ Shi'ite lo kọlu awọn iṣọmọgbe Buratai ṣugbọn wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Akọroyin, ọlọpaa atawọn mọkanla mii ṣagbako iku lasiko iwọde awọn ẹgbẹ Shi'ite l'Abuja lọdun 2019
Iwọde awọn ẹgbẹ musulumi Shi'ite bẹyin yọ lẹyin ti eeyan mẹtala dero ọru nibi nigba tawọn agbofinro kọlu awọn ẹgbẹ naa niluu Abuja.
Akọroyin kan, ọlọpaa kan ati eeyan mọkanla lo ba iṣẹlẹ naa lagbegbe Wuse niluu Abuja.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe awọn fi ọwọ ofin mu aadọta eeyan lori iṣẹlẹ ọhun.
Awọn ọmọ ẹgbẹ Shi'ite ṣe iwọde naa fun itusilẹ olori wọn, El-zakzaky ati iyawo rẹ to wa latimọle.

Oríṣun àwòrán, Other
Ọmọ ẹgbẹ Shi'ite marun un fara gbọta nnibi iwọde wọn l'Abuja lọdun 2020
Awọn ọmọ ẹgbẹ musulumi Shi'ite marunn un fara gbọta nibi iwọde ti wọn ṣe niluu Abuja.
Ikọlu naa waye ni ikorita Berger niluu Abuja laarin awọn ẹgbẹ Shi'ite ati awọn agbofinro.
Atimọle ijọba ipinlẹ Kaduna ni wọn ju,El-zakzaky ati iyawo rẹ si niluu Kaduna.
















